Isreal first flight to UAE: Ìjà d'ópin, fún ìgbà àkọ́kọ́, bàálù gbéra láti Israel lọ sí UAE

Oríṣun àwòrán, others
Eyi jẹ imupada bọ sipo ibasepọ orilẹ-ede mejeeji, lẹyin ti wọn kede pe awọn ti sinmi ogun.
Baalu Israel El Al ni yoo rin irinajo o ni wakati mẹta ọhun, lati gbe awọn aṣoju orilẹ-ede Israel ati US.

Wọn fi aaye gba baalu naa lati gba oju ofurufu orilẹ-ede Saudi Arabia kọja, eyi ti kii ribẹ tẹlẹ.
Wọn maa n ti i mọ àwọn baalu to ba n bọ lati Israel ni tẹlẹ.
- Iléẹjọ gíga jùlọ da ẹjọ́ SDP àti PDP nù, wọ́n ní Yahaya Bello ló wọlé ìbò gómìnà Kogi
- Yàtọ̀ sí Eko, wo ohun t'áwọn ìpínlẹ̀ meje míràn ń sọ nípa ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Wo ojú Akeem t'Ọlọ́pàá mú pé ó fipá bá ọ̀dọ́mọbìnrin kan sùn létí odò l'Oṣun
- Ìdí tí mo fi ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí 35 lọ́dọọdún rèé- Allwell Ademola
- Ìjọba Ghana ṣí iléeṣẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà padà. ó fún Nàìjíríà l'èsì àwọn ẹ̀sùn tó fi kàn-án
Orilẹ-ede UAE ni ìkẹta nilẹ Arab, to mọ si itẹwọ gba Israel gẹgẹ bi i orilẹ-ede, lati ọdun 1948 to ti wa.
Ọjọ Satide ni UAE pa ofin to ṣe lọdun 1972, lati ma ni ibasepọ pẹlu Israel, rẹ.
Ibẹrẹ oṣu yii si ni orilẹ-ede mejeeji ṣi oju opo ẹ̀rọ ibanisọrọ silẹ (láti ma a gba ipe laarin ara wọn) fun igba akọkọ.
Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ni wọn kede pe ija ti tán, lẹyin ti ilẹ America ba wọn laja.
Ṣaaju orilẹ-ede UAE, Egypt àti Jordan nikan lo da Israel mọ gẹgẹ bi orilẹ-ede, laarin awọn orilẹ-ede ilẹ Arab, ni Middle East.
Awọn onwoye l'agbaye sọ pe eyi yoo tubọ mu ki alaafia jọba ni Middle East.
- Ọba ni mí, mi ò le b'ọ̀rìṣà, Olorì tuntun tó ń bọ̀ já gbogbo ''scale''- Oluwo ti Iwo
- Wọ́n tún ti pa omidan ẹni ọdún 18 míràn l'Akinyele ní ìlú Ibadan
- Ta ni ìyàwó Chadwick Boseman, tó jẹ́ àwòkọ́ṣe rere f'áwọn ọ̀dọ́ Adúláwọ̀?
- Rabiu Yusuf, ìgbákejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà (AIG) lẹ́kùn Katsina jáde láyé
- Ọ̀fẹ́ ni China yóò kọ́ fásítì $50M ètò ìrìnnà sí Daura ìlú Ààrẹ Buhari- Amaechi
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Tolanibaj, Wathoni àti Brighto ni wọ́n lé kúrò ni BBNaija l'ọ́sẹ̀ yìí

















