Akinyele killings: Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ Toheed Ganiyu tí wọ́n ló pa Mary Daramola ẹni ọdún 18 l'Akinyele ní ìlú Ibadan

Oríṣun àwòrán, others
Arabinrin miran ti wọn pe orukọ rẹ ni Mary Daramọla ni awọn oniṣẹ ibi kan tun ti pa lagbegbe Akinyẹle nilu Ibadan, lẹyin ti wọn fi ipa ba a lopọ tan.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, ileto Alabata nitosi Mọniya ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
Ọrọ igbenipa lẹyin ifipabanilopọ ti di tọrọfọnkale lagbegbe Akinyẹle ni ilu Ibadan lati osu diẹ sẹyin.
Ọpọ lo si ti woye pe asiko ati fẹdọ lori oronro ti de lẹyin ti ọwọ tẹ Sunday Shodipẹ gẹgẹ bii afurasi ọdaran to wa nidi iṣẹlẹ naa.
Ọmọ ọdun mejidinlogun ni Mary Daramọla ti wọn ṣẹṣẹ tun ṣe lọṣẹ yii.
Awọn eeyan kan n sọ pe arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹToheed Ganiyu lo wa nidi iṣẹlẹ naa, wọn ni ọwọ ba a nigba to n gbiyanju ati ju oku omidan naa danu sinu igbo kan ni ileto ọhun.
Ninu atẹjade to fi ṣọwọ si ileeṣẹ BBC News Yoruba, alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, SP Gbenga Fadeyi ṣalaye pe ni agogo mẹjọ aṣalẹ ọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, Toheeb Ganiyu tan Mary Daramọla wọ iyara rẹ nibi ti o ti rọ ọ ni ọti yo ki o to fi tipa ba a lopọ.
Oku Mary ni awọn eeyan ri lẹyin eyi pẹlu atọ ọmọ ọkunrin ni oju ara ati ẹnu rẹ.
Fadeyi fi kun un pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ afurasi naa, iwadii si ti n lọ lọwọ lẹka iwadii ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Iyaganku nilu Ibadan.
Ninu ọrọ tirẹ, Baalẹ Alabata, Oloye Ọlakanmi Ọlaniyan ti rọ awọn ọdọ lagbegbe naa lati bu omi suuru mu ki wọn si ni igbagbọ ninu ọlọpaa ati iwadii wọn.
Oloye Ọlaniyan kọminu lori gbọnmọgbọnmọ iwa ipaniyan ati ifipabanilopọ lagbegbe naa eleyi to fi rọ ijọba atawọn agbofinro lati tete wa ojutu sii.
- Wo ọ̀nà márùn ún tí o lè gbà dáàbò bò ara rẹ lọ́wọ́ ìjàmbá láì gbé ìbọn!
- "Mi ò ní wọ Uber mọ́ tí wọ́n bá leè fi owó lée nítorí àfikún owó orí tí Sanwo Olu ṣe"
- Ilé ẹjọ́ ju olè orí omi mẹ́ta sí ẹ̀wọ̀n, ó tún ní kí wọ́n san 60 miliọ̀nù
- Àlàyé rèé lórí bo ṣe le è dá Emèrè mọ̀ tàbí dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ wọn
- Ìdè jáá! Ọmọkùnrin tí bàbá rẹ̀ tì mọ́lé bíi ẹlẹ́wọ̀n f'ọ́dún méje ní Kano gba ìtúsílẹ̀!
- Àwọn nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ṣíṣe ìṣirò àsìkò tí o bá n yé ẹyin
















