Gun control in Nigeria: Wo ọ̀nà márùn ún tí o lè gbà dábòbò ara rẹ lọ́wọ́ ìjàmbá!

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Onimọ nipa eto aabo lorilẹ-ede Naijiria, Slyvester Emiantor ti sọ awọn ọna miran ti awọn ọmọ Naijiria le gba lati daabo bọ ara wọn lọwọ ijamba lasiko ti eto aabo mẹhẹ ni Naijiria yii.
Eyi ko ṣẹyin awuyewuye to n waye lori boya ki awọn ọmọ Naijiria ma a gbe ibọn ilẹwọ bii AK47 lati koju eto aabo to mẹhẹ.
Amọ, Amofin agba ni Naijiria ti ni ko ba ofin mu lati jẹ ki awọn ọmọ Naijiria ti kii ṣe ẹṣọ alaabo lati gbe ibọn.
- Victor Agunbiade ni ojú àlá ni Ọlọrun ti yan iṣẹ́ ọmọ ogun ojú omi fún òun ní America
- Aya adarí ìjọba ológun Naijiria tẹ́lẹ̀rí, Victoria Aguiyi-Ironsi ti jáde láyé
- Ọlọ́run nìkan ló lè ní kí Tinubu má jẹ ààrẹ lọdún 2023, ìmọ̀ràn lọ̀rọ̀ Yahaya Bello- Joe Igbokwe
- Akọ̀wé APC, èèyàn mẹ́fà míràn fojú ba ilé ẹjọ́ fún fífọ́ òkúta mọ́ ọmọ ẹgbẹ́ lórí l' Ọ̀ṣun
- Èèyàn márùn ún kú, ọ̀pọ̀ míì farapa lásìkò rògbòdìyàn àwọn ọmọ onílẹ̀ l'EKo
- Ilé ẹjọ́ ju ọmọ ìjọ tó fi ìpá bá ọmọ pásítọ̀ rẹ̀ sùn ní ìpínlẹ̀ Ondo sí ẹ̀wọ̀n gbére
Ọ̀nà márùn ún lati gbà dáàbòbò ara ẹni lọ́wọ́ ìjàmbá!
- Ohun akọkọ ti o ni lati ṣe lati igba de igba ni ki o ma a ṣe ere idaraya ki ara rẹ ko le mokun, nitori ti ẹ ba koju ole tabi ijamba, ẹni ti ara rẹ ba mokun lo le e sare daadaa tabi farapamọ daadaa.
- Ohun ikeji ni lati ma ṣe gba ibẹru laaye nitori ti o ko ba bẹru wa a le rọnu lati wa ọna abayọ kuro ninu ijamba naa, amọ ibẹru yoo jẹ ki o gbagbe gbogbo ẹkọ ti o ti kọ lati da abo bo ara rẹ.
- Ohun kẹta ni lati kọkọ farapamọ ti o ba bọ sinu ẹwu. fun apẹẹrẹ, ti o ba gbọ iro ibọn, oun akọkọ ni lati mọ ohun to n ṣẹlẹ, nibo ni ijamba ti wa, kini mọ le ṣe lati daabo bo ara mi, ki o to gbe igbeṣẹ kankan.
- Ohun ẹkẹrin ni lati ni ẹkọ ati imọ nipa ọna ati daabobo ara ẹni gba ọwọ awọn onimọ nipa eto aabo. Ijọba gbọdọ mu lọkunkundun lati kọ awọn araalu lọna ati daabo bo ara wọn.
- Imo ẹko ni[pa eto aabo yoo jẹ araalu mọ iru asọ to yẹ ki wọn ma a w ati ọna ti wọn le gba lati lọ asọ ti wọn ba wọ, ẹya ara wọn, lilo tie ọrun, orukun ati ọwọ eniyan to fi mọ igbadi lati fi da abo bo ara wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa ni onimọ nipa eto aabo, Slyvester Emiantor fikun pe ijọba ni ipa lati ko nipa aabo araalu.
Emiantor gba ijọba ni imọran lati maṣe fun awọn araalu ni anfaani lati gbe ibọn dani fun aabo ara wọn, amọ ki awọn ologun ṣe idanilẹkọ fun awọn araalu nipa bi wọn ṣe le daabo bo ara wọn.
- Ìdí rèé ti mo fi ní kí aráàlú máa di ìhámọ́ra ogun nítorí àwọn janduku- Gómìnà Katsina
- Akọ̀wé APC, èèyàn mẹ́fà míràn fojú ba ilé ẹjọ́ fún fífọ́ òkúta mọ́ ọmọ ẹgbẹ́ lórí l' Ọ̀ṣun
- Orí ayélujára ni mo ti gbọ́ pé ìgbéyàwó mi àkọ́kọ́ ti foríṣọ́npọ́n - Funke Akindele Bello
- "A ti ń sin òkú méjì sínú ibójì kan náà nítorí ọ̀wọ́ngógó ibojì ìsìnkú"
- Ogun Àgbẹ́kọ̀yà, ìjà òmìnira fáwọn àgbẹ̀ ni tàbí ìfẹ́míṣòfò?
- Ṣé ìrànwọ̀ ni Kamala, ìgbákejì tí Biden yàn yóò jẹ́ fún un tàbí ìpalára?
Ẹgbẹgbẹ̀rún ọmọ Nàìjíríà ní yóò má a kú lójoojúmọ́ tí wọn bá gbà wọ́n láàyè láti gbébọn dání- Amofin
Onimọ nipa ofin orilẹ-ede Niajiria, Agbẹjọro Monday Ubani ti ni ko si ofin to ṣe agbatẹru pe ki ọmọ Naijiria kọọkan ma a gbe ibọn dani rin ni titi.
Ubani sọ fun BBC Yoruba bẹẹ lẹyin ti Gomina ipinlẹ Bẹnuẹ, Samuel Ortom rọ ijọba lati fun awọn ọmọ Naijiria laaye lati gbe ibọn bii AK47 lati daabo bo ara wọn.
Agbẹjoro naa ni ẹnikẹni to ba gbe ibọn bẹẹ dani yoo foju ba agọ ọlọpaa labẹ ofin Naijiria.

Oríṣun àwòrán, others
Awọn wo ló lè gbe ibọn ni Naijiria labẹ ofin?
Ubani ni awọn araalu ti ofin fun ni anfaani lati gba ibọn ni awọn to n fi ṣe ọdẹ,
Koda, o ni irufẹ ibọn ti wọn le lo, amọ kii ṣe bii AK47.
Eyi si gbọdọ wa pẹlu iwe aṣẹ ati ominira lati le lo ibọn.
Awọn oṣiṣẹ eleto aabo ni ibọn wa fun ni Naijiria bii Ọlọpaa, ọmọ ogun, awọn ẹṣọ alaabo ẹnu bode àti bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa lo ni wi pe ti wọn ba fun awọn ọmọ Naijiria ni anfaani lati gbe ibọn pẹlu ọrọ aje to dẹnukọlẹ ati bi aisi owo to gba igboro kan, ọgọọrọ awọn eniyan ni yoo ma pa ara wọn ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Others
Igbesẹ wo lo nṣaaju ki eeyan to le ni iwe aṣẹ lati gbe ibọn?
Amofin naa ni: ‘Ki ijọba to le e gbe iru igbesẹ bẹẹ, wọn gbọdọ wo ihuwasi awọn eniyan ati bi ilu ṣe rọrun si, ki wọn to le gbe iru igbesẹ bẹẹ''
Agbẹjọrọ Monday Ubani wa rọ ijọba orilẹ-ede Naijiria lati ma a ṣe idanilẹkọ loore-koore fun awọn oṣiṣẹ eleto aabo lati koju eto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria.
Bakan naa lo fikun un pe ki ijọba lọ awọn eleto aabo labẹle to wa ni ijọba ibilẹ kọọkan lọna ati koju eto aabo to dẹnukọlẹ naa.
O ti le ni ọdun mẹwaa bayii ti eto aabo ni Naijiria ti dẹnukọlẹ kaakiri gbogbo ẹkun to wa ni Naijiria.
Ṣaaju ni Gomina Benue ti sọrọ pe...
Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ Naijiria má a gbebọn bíi AK47 láti fi dáàbò bo ará wọ́n- Gómìnà Benue
Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom ti rọ ijọba apapọ lati fun awọn ọmọ Naijiria to kunjunwọn ni anfaani lati ma a gbe ibọn ilewo bii AK47.
Gomina Ortom ni fifun awọn ọmọ Naijiria ni anfaani naa yoo dẹkun eto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria.
O ti le ni ọdun mẹwaa bayii ti eto aabo ni Naijiria ti dẹnukọlẹ kaakiri gbogbo ẹkun to wa ni Naijiria.
- "A ti ń sin òkú méjì sínú ibójì kan náà nítorí ọ̀wọ́ngógó ibojì ìsìnkú"
- Ẹ̀gbọ́n àti àbúrò wà ní ilé ẹ̀jọ́ lórí ikú Tolulope Arotile
- 'Àwa ọmọ Nàìjíríà tó farapa fẹ́ wálé láti Lebanon, ìjọba kó wa pamọ́'
- Ọlọ́run nìkan ló mọ bí ìrìnàjò ìfẹ́ ẹ̀dá á ṣe rí láyé, ọ̀dọ́ Aláàfin ní orí gbémí yà sí, ó sì tẹ́milọ́rùn- Olorì Aanu
Gomina Ortum naa fi eleyii lede ni ibi to ti n sọrọ ni ipade awọn gomina lorilẹ-ede Naijiria ti wọn ṣe lori ẹrọ ayelujara.
O ni gbogbo ẹka ijọba gbọdọ fi imọsọkan lati gbogun ti eto aabo to dẹnukọlẹ ni Niajiria, ati wi pe eto aabo to dẹnukọlẹ n ba wa finra gidigidi.
Bakan naa lo gba ijọba ni iyanju lati ri wi pe wọn pese owo ati eto eko fun awọn eleto aabo lati ra ohun ija ti wọn nilo lati koju eto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria.
- 'Àwa ọmọ Nàìjíríà tó farapa fẹ́ wálé láti Lebanon, ìjọba kó wa pamọ́'
- Ọlọ́run nìkan ló mọ bí ìrìnàjò ìfẹ́ ẹ̀dá á ṣe rí láyé, ọ̀dọ́ Aláàfin ní orí gbémí yà sí, ó sì tẹ́milọ́rùn- Olorì Aanu
- Èèyàn 334 ló gbàwòsàn lọ́wọ́ Covid-19 l'Ọjọru, 453 míì tún lùgbàdì rẹ̀- NCDC
- Wọ́n dájọ́ ikú nípa sísọ̀kò pa ẹni ọdún 61 ní Kano
Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom ni ijọba gbọdọ wa wọrọkọ fi sada ni ẹka eto aabo nitori aisi aabo to peye naa ti fa ifasẹyin fun idagbasoke orilẹ-ede Niajiria.
Ortom ni eto ẹkọ gbọdọ peleke si, ki awọn eniyan, paapaa ọdọ ba le kẹkọ nipa ọna bi o ṣe yẹ ki eniyan ma a wuwa ni awujọ.

















