Osun APC crisis: Gomina Oyetola ti pè fún alàáfíà láàrin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC tí Gboyega Famodun gbé lọ sílé ẹjọ́

Osun

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina Oyetola to n tuko ipinlẹ Osun ti parọwa si ẹka awọn ọmọ ẹgbẹ APC nibẹ.

Gomina Oyetola ni pe ki alaga to n pe ẹjọ naa jawọ nibẹ bayii.

Lọjọ Isegun lo ni ki koowa jẹ ki alaafia jọba ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Osun ninu atéjade kan to fi sita.

Àkọlé fídíò, Badagry: Ojú ọ̀nà àrèmabọ̀ fáwọn ẹrú tó ń lọ sókè òkun

Saaju ni alaga ẹgbẹ naa Omooba Famodun Gboyega ti pe ẹjọ lodi si awọn oloye ẹgbẹ kan ti wọn yabo ile ẹgbẹ pẹlu awọn ọmọ eriwo kan lọsẹ neji sẹyin.

Ismail Omipidan to jẹ akọwe eto iroyin gomina Oyetola lo buwọlu atẹjade naa.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Iroyin ni gomina ko si nile nigba ti iṣẹlẹ naa

Oyetola ni ki wọn wagbo dẹkun fun igbẹjọ naa leyin to bu ẹnu atẹ lu ikọlu awọn janduku nile iya egbẹ.

APC

Oríṣun àwòrán, @APC

Akọ̀wé APC, èèyàn mẹ́fà míràn fojú ba ilé ẹjọ́ fún fífọ́ òkúta mọ́ ọmọ ẹgbẹ́ lórí l' Ọ̀ṣun

Akọ̀wé APC, èèyàn mẹ́fà míràn fojú ba ilé ẹjọ́ fún fífọ́ òkúta mọ́ ọmọ ẹgbẹ́ lórí l' Ọ̀ṣun

Akọwe igbimọ isakoso ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọsun, Rasaq Salinṣile ti dero ile ẹjọ pẹl'awọn eeyan mẹfa miran ti wọn jẹ ọmọlẹyin gomina ipinlẹ naa nigba kan ri to tun minisita f'ọrọ abẹle bayii, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹsola.

Àkọlé fídíò, Eegunjobi Omotanbaje Ajobiewe- Èébú ní wọ́n kọ́kọ́ ń bù mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣà pípé ní

Ẹsun wọn ni pe wọn lọ da ile ẹgbẹ ru ti wọn si ti ipa bẹẹ lu arakunrin kan, Ajetunmobi Muideen ti wọn si tun fọ aga mọọ lori ti wọn si tun okuta mọ ẹlomiran toruko rẹ n jẹ Babatunde Hamzat lori.

Rasaq Salinsile, Adelowo Adebiyi ni o n lewaju igun kan lẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Osun ti wọn n pe ni The Osun Progressives, TOP.

Oun ati awọn meji kan ti ti jẹ kọmisonna ri labẹ ijọba gomina Arẹgbẹṣọla, Kazeem Salami ati Biyi Odunlade, Gbenga Akano oẹlu Alaba Popoola ati AzeezAdekunle ni awọn ti ileeṣẹ ọlọpaa ko lọ sile ẹjọ.

Ile ẹjọ Majisreeti kan nilu Osogbo ni wọn ko wọn lọ lati jẹjọ ẹsun ti wọn fi kan wọn naa.

Yanponyanrin ti n bẹ sulẹ lati bi ọdun mẹta sẹyin laarin ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Osun nitori aawọ laarin Gomina Gboyega Oyetọla ati Rauf Arẹgbẹṣọla to fi ipo naa silẹ.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Awọn onwoye kan ṣalaye pe bi gomina Oyetola ṣe n yi pupọ awọn eto ti ijọba Arẹgbẹṣọla gbe kalẹ danu kun ara ohun to n fa gbun-gbun-gnun laarin awọn mejeeji.

Amọsa awọn afurasi mẹtẹta baa ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ati pe finifini lọwọ awọn mọ.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Ileẹjọ gba beeli wọn pẹlu milionu marun un naira, oniduro kan to gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba ni ipinlẹ naa ki o to sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinlelogun osu kẹsan.

Wahala to fa ipẹjọ yii bẹ silẹ nibi ijoko igbimọ igbẹjọ kotẹmilọrun ti wọn gbe kalẹ lẹyin idibo wọọdu to waye lọjọ kẹrinla ọdun 2021.

Nibẹ ni awọn to n gbe lẹyin Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla atawọn to gbẹ lẹyin Gomina Gboyega Oyetọla ti gbe ina woju ara wọn.