PDP crisis: Yánpọnyánrin PDP ń fẹjú síi, Uche Secondus ní òun kò bẹ̀rù àṣẹ ilé ẹjọ́, kí ẹgbẹ́ má bàjẹ́ ni tòun

Oríṣun àwòrán, @Secondus
Yanponyanrin laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ti n waye baye fun osẹ diẹ eleyii ti awọn alagbara kan ninu ẹgbẹ naa n pe fun Uche Secondus, alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu naa.
Lẹyin ti ile ẹjọ giga kan nipinlẹ Rivers ti ni ko yẹba naa ko si ye e pe ara rẹ ni alaga apapọ ẹgbẹ Oṣelu PDP lorilẹede Naijiria.
Ọmọọba Uche Secondus ti ṣalaye pe ko si ohun kan to babara ninu rẹ ju wi pe ki oun pẹlu lọ si ile ẹjọ lati lọ da ile ẹjọ loun ipe rẹ.
- Ìdí rèé ti mo fi ní kí aráàlú máa di ìhámọ́ra ogun nítorí àwọn janduku- Gómìnà Katsina
- Èèyàn márùn ún kú, ọ̀pọ̀ míì farapa lásìkò rògbòdìyàn àwọn ọmọ onílẹ̀ l'EKo
- Wo ìgbà mẹ́ta tí Olusegun Obasanjo ti fi ìdọ̀bálẹ̀ nàá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ níwájú àwọn oríadé
- Ọlọ́run nìkan ló lè ní kí Tinubu má jẹ ààrẹ lọdún 2023, ìmọ̀ràn lọ̀rọ̀ Yahaya Bello- Joe Igbokwe
- Mi ò bínú sí gbogbo nǹkan ti Chioma sọ nípa mi- Apostle Suleiman
Onidajọ Okogbule Gbasam ti ileẹjọ giga ipinlẹ Rivers to wa ni Degema ni Portharcourt paṣẹ ni ọjọ Aje petiti di igba ti wọn yoo fi yanju ẹjọ naa o, Secondus ko gbọdọ oe ara rẹ tabi ṣe ojuṣe alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ninu ọrọ ti amugbalẹgbẹ fun Ọmọọba Secondus sọ, alaga ẹgbẹ oṣelu PDP naa ni ẹruko ba oun boti wulẹ ko mọ lori ipẹjọ naa oun si setan lati yọju si ile ẹjọ lori rẹ.
"Bi ẹnikẹni ba gbe Secondus ati ẹgbẹ oṣelu PDP lọ sile ẹjọ, o di dandan, yoo farahan ni lati wi tẹnu rẹ. Awọn ọmọ Naijiria lo ni ẹgbẹ oṣelu yiio si tobi ju ẹnikẹni tabi ẹgbẹ kankan lọ titi kan awọn afipa du ipo".
Yanponyanrin laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ti n waye baye fun osẹ diẹ eleyii ti awọn kan ninu ẹgbẹ naa ti gomina Nyesom Wike tipinlẹ Rivers ko sodi lati tun igbimọ isakoso ẹgbẹ naa ka.

Oríṣun àwòrán, PDP
Iléẹjọ́ ní kí alága gbogboogbò PDP, Uche Secondus lọ rọọ́kùn nílé
Rogbodiyan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti fori sọ ibi kan kan lójọ Aje, lẹyin ti ileẹjọ giga ipinlẹ Rivers ni ki ni alaga gbogbo ẹgbẹ naa, Uche Secondus lọ rọkun nile na.
Eeyan mẹrin, Ibeabuchi Ernest Alex, Dennis Nna Amadi, Emmanuel Stephen ati Umezirike Onucha lo ni ki ileẹjọ da Secondus duro gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ ọhun.
Adajọ ileẹjọ giga ẹkun Degema, O. Gbasam sọ ninu idajọ rẹ pe aṣẹ gun ẹbẹ awọn mẹrin yii.
- Ọlọ́run nìkan ló lè ní kí Tinubu má jẹ ààrẹ lọdún 2023, ìmọ̀ràn lọ̀rọ̀ Yahaya Bello- Joe Igbokwe
- Wo ìgbà mẹ́ta tí Olusegun Obasanjo ti fi ìdọ̀bálẹ̀ nàá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ níwájú àwọn oríadé
- Àwọn jàndùkú afẹ̀mí-ṣòfò ṣekúpa èèyàn 24 ní Kaduna àti Katsina lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Èyí ni ojú ọ̀nà àrèmabọ̀ fáwọn ẹrú ní Badagry
- Ọmọ ọdún márùn-ún tó jẹ́ ògbóntagí èdè Yorùbá, Adigun Olowe jẹ oyè nílùú Eko
- Oṣù mẹ́ta ni mo lò nílé ìwòsàn lẹ́yìn tí 'Mopol' fọ́ ìgo 'Coke' lórí mi ní LASU- Babatunde Gbadamosi
Nkan ko fara rọ ninu ẹgbẹ PDP lori awuyewuye ati yọ Secondus nipo ṣaaju ipade gbogbogbo ẹgbẹ naa to n bọ lọna.
Ẹwẹ, Secondus ti sọrọ lẹyin aṣẹ ile ẹjọ to ni ko gbọdọ pe ara rẹ ni alaga PDP mọ.
Oludamọran Secondus lori ọrọ iroyin, Ike Abonyi sọ pe Secondus ṣetan lati sọ ti ẹnu rẹ ni ileẹjọ.
O ni ẹgbẹ oṣelu PDP kii ṣe dukia ẹnikan, awọn ọmọ Naijiria lo ni i.















