Land Grabbers: Èèyàn márùn ún kú l'Eko, méjì kú l'Ogun lásìkò rògbòdìyàn àwọn ọmọ onílẹ̀

Lagos

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O kere tan, eeyan marun un ti dagbere faye, ti ọpọ awọn mii si farapa lasiko ti awọn janduku kọlu agbegbe Igbokuta ati Gberigbe to wa ni Ikorodu, nipinlẹ Eko.

Iroyin ni awọn janduku ọhun, ti ọpọ mọ si ọmọ onilẹ kọlu agbegbe naa ni nnkan bii ago kan ọsan ti wọn si kọlu awọn eeyan to ni ilẹ lagbegbe ọhun.

Wọn ni ọgbẹni kan ti ọpọ mọ si "Sir K" lo ko awọn janduku ọhun sọdi lati kọlu awọn kan ti wọn n wo gẹgẹ bii alatako awọn.

Lara awọn awọn ti ẹmi wọn sọnu nibi iṣẹlẹ ọhun ni Lateef Ade, Mutiu Balogun, Hameed Idris atawọn meji mii.

Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ, ṣugbọn ti ko fẹ fi orukọ rẹ lede ṣalaye pe wahala naa bẹrẹ lẹyin ti awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ti ẹka "Special Fraud Unit" fi ṣikun ofin mu ayederu ọlọpaa kan ti Sir K fi si agbegbe naa.

O ni lẹyin ti ọlọpaa mu ayederu amí ti Sir K fi sibẹ tan ni awọn ọmọlẹyin Sir K ọhun ṣe ikọlu si adugbo awọn nibi ti ẹmi eeyan marun ti sọnu.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Gbogbo akitiyan lati gbọ lati ẹnu alukoro agbenusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Adekunle Ajisebutu lori iṣẹlẹ ọhun lo ja pabo.

Ẹwẹ, ni ipinlẹ Ogun bakan naa, ẹmi eeyan meji bọ lasiko ti awọn afurasi ọmọ onilẹ kọlu agbegbe Obada-Oko.

Iroyin ni awọn janduku naa kọlu agbegbe ọhun ni nnkan bii aago mejila ọsan pẹlu oniruru ohun ija oloro lọwọ to fi mọ afọku igo.

Awọn eeyan agbegbe naa ṣalaye pe awọn janduku naa ṣa ọgbẹni kan, Sikiru Kayode ni ada ti ẹmi si fẹe bọ lẹnu rẹ.

Arakunrin kan ti ọrọ naa ṣoju rẹ, Taoheed Agbaje ṣalaye pe awọn janduku to kọlu agbegbe ọhun to ọgọrun un.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ti sọ pe awọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, iwadii si ti bẹrẹ.

Àkọlé fídíò, Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí