Alleged missing N106bn: SERAP gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ lórí owó tí wọ́n ló d'àwátì láwọn ilé iṣẹ́ ìjọba

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bashir Ahmad
Ajọ SERAP to n ri itọpinpin awọn akanṣe iṣẹ ni Naijiria ti gbe Aarẹ Muhammadu Buhari lọ si ile ẹjọ lori biliọnu mẹrindinlaadọfa(N106bn) to di awati lawọn ileeṣẹ ijọba mọkandinblaadọjọ(149).
Ajọ SERAP pe Buhari lẹjọ lori ikuna rẹ lati ṣe iwadii ẹsun owo to di awati ọhun lawọn ile iṣẹ ijọba.
Igbesẹ yii tẹle ikede ọfiisi ayẹwe owo wo agba ni Naijiria lọdun 2018 pe N105,662,350,077 ti di awati tabi ki wọn ti ṣe e kumọ kumọ lawọn ileeṣẹ ijọba 149.
- Ìdí rèé tí PDP kò ṣe tíì wọlé ìbò gómìnà l'Eko láti 1999 di àkókò yìí- Bode George
- Ẹ dẹ́kun lílo Kurani àti Bibeli nìkan láti fi búra fún àwọn olóṣèlú wa, ẹ jẹ́ ká fí ńkan ìṣẹ̀mbáyé kún un- Oba Ogboni Iwase
- Kò tíì tó àsìkò pé kí Nàìjíríà pín ṣùgbọ́n...- Olowu ilẹ̀ Kuta
- Ẹ̀yin akọ̀ròyìn, ẹ má kọ ìròyìn tó lè dá wàhálá sílẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani Modakeke- Ọlọ́pàá
SERAP tun pe agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami, SAN ati minisita eto inawo, Zainab Ahmed naa lẹjọ lori ẹsun kan naa.
Ninu ẹjọ ti SERAP pe pẹlu nọmba yii, FHC/ABJ/CS/903/2021, lọsẹ to lọ ni ile ẹjọ giga ijọba apapọ l'Abuja, ajọ naa fẹ ki ijọba paṣẹ fun Buhari lati ṣe iwadii owo to sọnu yii.
Ajọ SERAP fẹ ki ileẹjọ ri pe awọn to ba jẹbi ẹsun yii foju wina ofin ki wọn si da owo ijọba pada.
Ajọ naa ṣalaye ti ijọba ba ri owo yii gba pada, yoo dẹkun yiya owo kaakiri ti ijọba apapọ n ṣe bayii.
SERAP sọ pe gbese orilẹede jẹ yoo tun dinku ti ijọba ba le ri owo to di awati yii gba pada.
Ajọ SERAP ni owo ti wọn lo sọnu yii ti ṣe akoba fawọn ẹka ijọba, ko si le jẹ ki wọn ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ gi ileeṣẹ ijọba.
- Èèdì! Èdè-ài-yedè bẹ́ sílẹ̀ lórí owó pínpín, awọn ajínigbé yìnbọn pa ara wọn, èèyàn mẹ́sàn-án kú
- Àwọn Emèrè ṣe àjọ̀dún nílùú Osogbo, bó ṣe lọ nìyí
- Búlọ́kù fẹ́ dá ìjà sílẹ̀ láàrín ìjọba àtàwọn olówò búlọ́kù ìpínlẹ̀ Ondo
- Láàrín ọdún méjì ₦3 bílíọ̀nù làwọn ajínigbé ti gbà nílẹ̀ Yorùbá, èèyàn 200 ni wọ́n sì ti pa- Gani Adams
SERAP tun sọ fun ileẹjọ pe ko paṣẹ fun aarẹ Buhari lati maa gbe eto iṣinu gbogbo ileeṣẹ ijọba jade lọdọọdun.
Ajọ naa ni eleyii yoo fawọn araalu lanfaani lati mọ bi ẹka ijọba kọọkan ṣe n nawo.
Ile ẹjọ ko tii kede ọjọ ti igbẹjọ yoo bẹrẹ.














