Àṣìṣe Sunday Igboho ni àwọn gómìnà n wò, wọn kò wo èrè ọjọ́ iwájú - Ọba Ogboni Iwasẹ

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

“Ẹyin tẹẹ sọ pe ko si oogun mọ, ti ogboni ba sọ pe nkan maa a ṣẹlẹ ko le to ọjọ meje”

Ọba Ogboni Igba Iwasẹ, Adeyinka Sangolade Arifanlajogun ba BBC sọrọ lori awuyewuye to rọ mọ iwọde Yoruba Nation ati Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams.

O ni ibaṣepọ to dara lo wa laarin oun ati Gani Adams, nitori pe ọmọ Yoruba ni. Ṣugbọn, oun ko faramọ riri awọn ọba alade fin.

Ọba Ogboni naa ṣalaye pe ti wọn ba n fi ẹsin abalaye buru fun awọn oloṣelu, ilu yoo tuba, yoo tuṣẹ.

Ó di ìgbà tí àwọn olóṣèlú bá n fi nkan àbáláyé búra kí Naijiria tó le rójú - Ọba Ogboni Iwasẹ

O ni ti wọn ba le mu ẹsin abalaye mọ Bibeli ati Kuraani lasiko ibura fun awọn adari Naijiria, wọn o ma a ṣe daadaa.

Lori ọrọ ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Igboho, Ọba Arifanlajogun sọ pe oun ti rọ ijọba pe ki wọn o ṣi oju aanu wo o.

O sọ pe o ṣeni laanu pe dipo ki ijọba wo anfaani ti igbesẹ Igboho yoo jẹ ni ọjọ iwaju, awọn aṣiṣe rẹ ni wọn n wo.

Lori ọrọ ti Ọba Ogboni Abalaye ti awọn ọlọpaa mu nipinlẹ Eko lasiko iwọde Yoruba Nation, Ọba Adeyinka sọ pe ilẹ Yoruba ni o n ja fun, amọ aṣiṣe ni bo sẹ yi ọrọ pada pe oun ko ṣe iwọde.

O ni agbara iṣẹmbaye ṣi wa nilẹ Yoruba, tako bi awọn eeyan kan ṣe n sọ lasiko yii.

O ni ti Ogboni ba sọ pe nkan yoo ṣẹlẹ si ẹnikan, ko le pe ọjọ meje ti yoo fi ṣẹlẹ.

O ni ọlaju lo mu ki awọn eeyan o ma a foju kere ẹgbẹ naa.