Yoruba Nation Rally: Ṣé lóòtọ́ ni Sunday Igboho darapọ̀ mọ́ ìwódé Yoruba Nation ?

Awọn Oluwọde

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni asaaju ajijagbara Yoruba Nation, Oloye Sunday Igboho ti gunlẹ si adugbo Ojota nilu Eko nibi ti iwọde naa ti n waye.

Agbẹnusọ fun Igboho, Olayomi Koiki lo kede bẹ loju opo Facebook rẹ.

Koiki ni awọn alatilẹyin Sunday Igboho ti de sinu Eko lati wa darapọ mọ iwode Yoruba Nation to n lọ lọwọ ni ilu Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn ko ba ti ija wa, awọn fẹ wa ṣe iwọde ni irọwọrọsẹ ni lati pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba.

Awọn Oluwọde

Iwọde si ti doju ọgbagade nilu Eko bayii nibi ti awọn agbofinro duro wamu wamu lati da awọn oluwọde naa lẹkun.

Bi wọn se n yin afẹfẹ tajutaju si wọn, naa ni wọn n fọn omi gbigbona si wọn lara, ti iro ibọn si tun n dun bakan naa.

Bakan naa ni wọn fi kun wi pe Sunday Igboho kii ṣe ọdaran nitori naa ki awọn eniyan ma a reti wọn ni ilu Eko.

Amọ ṣa, titi di asiko ti akọroyin BBC Yoruba kuro nibi ti iwọde naa ti waye ni ọsan oni, ko ko firi tabi fi oju ri Sunday Igboho.