Sunday Igboho: Ilana Omo Oodua ní jálajàla tí òkú Adogan rí gan ti DSS lójú, ni wọn ṣe gbé òkú rẹ̀ lọ

Oríṣun àwòrán, Yoruba Nation/Facebook
Awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ nilẹ Yoruba atawọn eekan ajijagbara to n pe fun idasilẹ Yoruba Nation ti n se idaro akọni to lọ laarin wọn.
Ọkunrin naa ti inagijẹ rẹ n jẹ Adogan ni awọn osisẹ agbofinro DSS pa loru Ọjọbọ ti wọn se ikọlu sile gbajumọ ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Sunday Igboho.
Adogan la gbọ pe o jẹ ara awọn ọmọlẹyin Sunday Igboho, ti wọn dijọ n jija gudu fun idasilẹ orilẹede Yoruba Nation.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho kọ̀wé sí ìjọba àpapọ̀, o ní dandan kí wọn sàn owó gbà má bínú ₦500m
- Ta a ló yìnbọn pa Jumoke, ọmọ ọdún 14 nítòsí ibi ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota?
- Sunday Igboho ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí DSS pa
- DSS kò mú mi lọ́dọ̀ Guru Maharaji, èmi rèé n‘Ibadan, ẹ sinmi àhesọ ọ̀rọ̀ - Sunday Igboho
- Bí ìjọba Buhari bá yege láti pa mí ni, yóò ní ‘Unknown Gunmen’ ló wá pa mí - Sunday Igboho
- Kí ló dé tí DSS kó bàńtẹ́ òògùn, ba ilé Sunday Igboho jẹ́ lái fara pa?
- Ilé mi kọ́ ni àwọn DSS ti kó àwon ìbọ́n tí wọ́n pàtẹ- Sunday Igboho
- Àwọn ọmọ Yoruba lókè òkun ṣèwọ́de nílùú London torí Sunday Igboho
- "DSS, níbo ni ₦2m àti owó Euro, Dollar àti Pound Sterling tẹ kó nílé mi wà? "
- Sunday Igboho, ìsáǹsá rẹ̀ kò lé sá mọ́ wa lọ́wọ́, mímú lá mú ọ - DSS fọwọ́ gbáyà
Ọkunrin yii si ni awọn osisẹ DSS lo wa lara awọn eeyan meji ti ẹmi wọn ti ọwọ awọn bọ nile Sunday Igboho nitori pe wọn n di awọn lọwọ lati wọnu ile naa.
Nigba ti wọn n daro oloogbe naa, Ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, ti oun naa n jijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation kede pe ọta ibọn mejidinlaadọta ni DSS yin mọ Adogan, titi to fi jade laye.

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki/Facebook
Atẹjade ti Ifa Dare fisita ni orukọ ẹgbẹ Ilana Omo Oodua loju opo Facebook Olayomi Koiki, tii se agbẹnusọ fun Sunday Igboho ni "Eyi ni oju akọni ati jagunjagun tootọ.
Orukọ rẹ ni Adogan (PBUH), o gba ọta ibọn mejidinlaadọta sara, to si duro bii akọni Ẹsọ Ikoyi ti ko bẹru ohunkohun.
Nigba ti ọta ibọn DSS ko ran Adogan, ni wọn ba fi ọmọ odo fọ lori, wọn du bi ẹran titi to fi ku."
Ẹgbẹ Ilana Omo Yoruba ni Adogan, Majasola Igboho Oosa, ki alaafia ati ibukun Eledua wa pẹlu rẹ, o ti jade kuro lati pada wa ja ni ọjọ miran.

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki Facebook
Ẹgbẹ naa fikun pe awọn osisẹ DSS se oku Adogan jalajala debi pe oju gan n ti wọn lati fi oku rẹ silẹ, ti wọn si gbe lọ pẹlu wọn.
Ẹgbẹ naa ni se ni ẹjẹ Adogan n ro tẹle awọn DSS lẹyin lati inu yara igbalejo Sunday Igboho titi de olu ileesẹ wọn to wa nilu Abuja.
Ẹgbẹ naa wa n fi ọwọ gbaya pe ko si a n boju wẹyin mọ ninu ọrọ idasilẹ orilẹede Yoruba, ti awọn yoo si se iwọde Yoruba nilu Eko lonii ọjọ Satide.
Saaju ni Sunday Igboho ti kọkọ daro ọmọlẹyin rẹ naa, to si ni ki awọn eeyan maa gbadura fun aya atawọn ọmọ to fi silẹ.


















