Sunday Igboho: Wo àwọn èròjà àti orúkọ àwọn èèyàn tí DSS kó nílé Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ idi abajọ ti wọn fi yabo ile ajijagbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.
Ajọ DSS ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lalẹ Ọjọbọ pe awọn eeyan lo tawọn lolobo pe Igboho ko ibọn ati nkan ijagun pamọ nile rẹ lo jẹ ki awọn yabo ile rẹ.
Ninu atẹjade naa ti agbẹnusọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ, Ọmọwe Peter Afunanya fi sita, DSS ni awọn ọmọṣẹ mẹsan an ti wọn gbe ibọn AK-47 lọwọ to wa nile Igboho kọju ibọn sawọn DSS.
Amọ meji ninu awọn ọmọṣẹ Igboho naa tẹri gbaṣọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Sunday Igboho, Banji Akitoye, ẹ rìn jìnnà sójú pópó Eko fún ìwọ́de Yoruba Nation"
- Afenifere figbe bọnu pé ìkọlù sí òmìnira àti ẹ̀tọ́ láti sọ̀rọ̀ ti padà dé
- Ìbọn àti nǹkan ìjagun ni Igboho kó pamọ sílé ló jẹ kí á yabo ilé rẹ̀ - DSS
- Gani Adams tutọ́ sókè fójú gbà lórí ìkọlu sílé Sunday Igboho
- Níbo ní Sunday Igboho wà lẹ́yìn ìkọlù síle rẹ̀? Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà ń bèèrè
- Àwọn DSS àti ṣọ́jà ló kọlu ilé mi, mo fojú mi kòrókòró rí wọn - Sunday Igboho
- Àwọn ológun Nàìjíríà pẹ̀lú agbésùmọ̀mí ilẹ̀ òkèèrè ló kọlu ilé Igboho - Akintoye
- Àwọn ẹgbẹ́ ajìjàgbara Yoruba fọnmú lórí ìkọlù sílé Sunday Igboho
- Ẹ̀jẹ̀ kúnlẹ̀ nílé Sunday Igboho, ẹ̀mí méjì bọ́ lásìkò tí afurasí Sọ́jà kọlu ilé rẹ̀
- Sunday Igboho, ṣe sùúrù díẹ̀ lórí ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko - Olugbon ń lọgun
- Afurasí ‘Sọ́jà’ kọlu ilé Sunday Igboho lóru mọ́jú, òkú ṣùn, dúkìá bàjẹ́
Ọmọwe Afunanya ni ọkan lara awọn DSS lo kan ṣe leṣe ni ọwọ rẹ, o si ti lọ gba itọju nile iwosan.
Ajọ DSS ni lootọọ ni pe awọn mu awọn yoku ti wọn doju ija kọ awọn nile Igboho lọ.

Oríṣun àwòrán, DSS
Awọn nkan ti ajọ DSS ri nigba ti wọn wa gbogbo inu ile Igboho tan niyii:
- Ibọn AK-47 meje ati irufẹ ibọn mii mẹta.
- Ọgbọn iwe iroyin to n sọ lilo ibọn AK-47 lẹkunrẹrẹ.
- Ẹgbẹrun un marun un ọta ibọn.
- Ada marun un, ọbẹ meji.
- Pọọsi ti owo dọla marun un, iwe iwakọ ti Naijiria ati oke okun lorukọ Igboho wa ninu rẹ.
- Kaadi igbowo ati iwe igbelu orilẹede Germany naa wa ninu pọọsi ọhun.
- Aṣọ oogun mẹta ati ẹwu oogun kan.
- Ẹrọ kọmputa meji.
- Iwe igbelu awọn eeyan mii yatọ si Sunday Igboho.
Lẹyin awọn nkan ti ajọ DSS ko ninu ile Igboho, wọn tun mu eeyan mẹtala ninu ile rẹ lọ si Abuja.
Ọkunrin ni mejila ninu awọn eeyan yii nigba ti ọkan ninu wọn jẹ obinrin.
Orukọ mejila ninu awọn eeyan naa niyii nigba ti iwadii ṣi n lọ lọwọ lori eeyan kẹtala.
i.Abdulateef OFEYAGBE
ii.Amoda BABATUNDE aka Lady K (female)
iii.Tajudeen ERINOYEN
iv.Diakola ADEMOLA
v.Abideen SHITTU
vi.Jamiu NOAH
vii.Ayobami DONALD
viii.Adelabe USMAN
ix.Oluwafelumi KUNLE
x.Raji KAZEEM
xi.Taiwo OPEYEMI and
xii.Bamidele SUNDAY.
DSS nwa fi asiko yii sọ fawọn ọmọ Naijiria ati gbogbo agbaaye pe, Sunday Igboho atawọn ẹgbẹ rẹ ti wọn jọ n beere fun iyapa orilẹede Yoruba ti ko nkan ija ogun pamọ sile lati maa da ilu ru.

Oríṣun àwòrán, DSS
Awọn ibọn atawọn nkan ijagun ti a ri nile Igboho fihan gbangba nipa erongba Igboho lati kọju ija si ijọba orilẹede Naijiria.
DSS ti n fi asiko yii sọ fawọn gbogbo awọn ileeṣẹ to n ri si iwe igbelu ati kaadi idanimọ pe, Igboho le kan si wọn pe kaadi idanimọ ati iwe igbelu ohun sọnu pe oun fẹ ṣe omiran, ẹ maa da a lohun.
Ajọ DSS tun n sọ fawọn eeyan pe o ṣeeṣe ki marun un ninu ibọn AK-47 ti wọn ri nile Ighoho jẹ awọn ibọn ti awọn ọmọṣẹ rẹ fipa gba lọwọ awọn oṣiṣẹ aṣọbode ni Idi Iroko nipinlẹ Ogun.
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ tun fẹ ki awọn araalu mọ pe ija ibọn yinyin sira ẹni to bẹ silẹ nile Igboho fun wakati diẹ lo jẹ ki o ri ọna lati salọ.
Igboho le sa de bi ibi ti o ba wu u bayii, o le ti maa ṣe ikọlu si awọn agbofinro, ṣugbọn bo pẹ bo ya, ọwọ yoo pada tẹ ẹ.
Lakotan, ajọ DSS n rọ gbogbo awọn to n ṣatilẹyin fun Igboho lati gba ni imọran pe ki o jọwọ ara rẹ fawọn oṣiṣẹ eleto abo nitori ko si ẹni to ga ju ofin lọ.
Bakan naa, gbogbo awọn eeyan ti DSS mu nile rẹ ni yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ,'' Ọmọwe Afunanya lo ṣalaye bẹẹ.

















