Igboho House Attack: Gani Adams tutọ́ sókè fójú gbà lórí ìkọlu sílé Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Gani Adams
Ààrẹ ọ̀nà kakanfo gbogbo ilẹ̀ Yorùba Iba Gani Ige Adams ti bẹ̀nu àtẹ́ lu ìkọlu tó wáye nílé olóye Sunday Adeyemo ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Sunday Igboho lówúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́bọ.
Iba ni ìgbẹ́sẹ̀ yìí jẹ́ ọ̀nà láti pa Igboho lẹnumọ́ lorí òmìnira ọmọ Yorùbá tó n bèrè fún.
Ààrẹ Adams rọ ìjọba àpapọ̀ láti ṣe ìwádìí nǹkan tó fa ìṣẹ̀lẹ̀ náà kí wọ́n mú gbogbo àwọn ọ̀daràn tó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà.
- Ìbọn àti nǹkan ìjagun ni Igboho kó pamọ sílé ló jẹ kí á yabo ilé rẹ̀ - DSS
- Jẹ́jẹ́ ni Iyabo Ojo jókòó, èmi ni mo pè é sí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha - Lola Alao
- TAMPAN bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn igun tó ń bínú, ọ̀rọ̀ yóò yanjú láìpẹ́ - Femi Adebayo
- Ta ló fẹ́ jí Auxilliary gbé ní Ibadan?
- Ẹni tó bá tàbùkù àgbà níta, ti ń bú òbí rẹ̀ nílé tẹ́lẹ̀ - Yomi Fabiyi
Nínú àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ rẹ̀ Kehinde Aderemi fi síta lọ́jọ́bọ ló ti sàlàyè pé ènìyàn mẹ́jọ ni ó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ tí ọ̀pọ́ àwọn dúkíà sì sòfò.
Ààrẹ ni ìkọlu sí ilé Sunday Igboho yìí tú àṣírí ìjọba àpapọ lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ , tọ sì tẹ̀pẹlẹ̀mọ pé àwọn tó ṣe iṣẹ́ ibí náà ń gbìyànjú láti ṣẹ̀rùba Igboho ni lóríọ̀rọ̀ Yoruba nation, èyí tó jẹ́ nǹkan tí àwọn ọmọ Yorùba nílé àti lẹ́yìn odi ń fẹ́.
" Wọ́n ń lépa Igboho nítóri ìpinurẹ̀ láti jìjàgbara yorùbá àwọn tó sì wà lẹ́yìn ìkọlu náà kí wọ́n lọ mọ pé ìkọlu sí Igboho, jẹ́ ìkọlu si gbogbo ọmọ káàrọ́-òò-jííre. Ó bani lọ́kan jẹ́ pé ìjọba tó n bẹ lóde kìí fẹ́ gbọ́ nǹkan ti ará ilú ń fẹ́ sétí.
" Bí àpẹrẹ kò sí ìgbà kankan ti ilẹ̀ Gẹẹsi pa àwọn ènìyàn Scothland lẹnumọ lásiko tí wọ́n fẹ́ yà kúrò. Nǹkan mẹ́jì ni a ń bèrè lọ́wọ́ ìjọba, yàlá kí wọ́n ṣe ọ̀kan níbẹ̀, níṣe ni wọ́n ń fi agídí mú àwọn ara ilú."
" Fídíò tó jáde láti ilé Igboho jẹ́ tí ikú àtí ìparun, ènìyàn mẹ́jọ ló bá lọ tí ọ̀pọ̀ dúikíà sì sòfò, kódà tó bá se ti ìròyìn tó tẹ̀ mí lọ́wọ́, wọ́n ni pé àwọn ọmọogun Nàìjíríà ló ṣe iṣẹ́ náà'"
"Ká wa sọ pé Igboho kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ṣe ẹ mọ pé ó le dá ogun sílẹ̀. Sé ẹ ránti bí ọ̀rọ̀ Boko Haram se bẹ̀rẹ̀ tí ìhọba pa Muhammed Yusuff olórí wọn lọ́dún 2019.
Ikú Yusuff ni Nàìjíríà kò tí bọ́ nínú ìṣòrò rẹ̀ di òní yìí.
Ní tèmí mí o kẹ̀yìn sí gbogbo nǹkan tó bá níṣẹ́ pẹ̀lú òfin tàbí faramọ́ kí ẹnikẹni ṣe lòdì sí òfin, sùgbọ́n ó yẹ kí ìjọba ani àfaradà, èyí ló le mú ki pijóba àwarawa dùn.












