Baba Ijesha: Yomi Fabiyi ní ọ̀rọ̀ tí ẹnìkan bá sọ láwùjọ, lá fi mọ̀ irú ẹbí tó ti jáde àti ẹni tó tọ

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi/Instagram
Gbajugbaja osere tiata Yoruba Yomi Fabiyi tun ti n sọ oko ọrọ sawọn eeyan kan loju opo Instagram rẹ.
A ko mọ ẹni to n ba wi tabi idi to fi n sọ ọrọ naa ṣugbọn aroko rẹ naa fara jọ aawọ to gba igboro lori ọrọ oṣere tiata nni, Baba Ijesha.
Lẹnu ọjọ mẹta yii, fa ki n fa ti n waye laarin Yomi Fabiyi ati awọn osere tiata miran lapa, kan to se pe eyi si ti mu ki awọn to jẹ agbagba ẹgbẹ awọn osere tiata dasi ọrọ naa.
Nibi ọrọ to kọ laipẹ yii to si fi soju opo rẹ ni Instagram, Yomi bẹrẹ ọrọ rẹ bi asamọ ati isiti, to sì fi ikilọ pari rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọjọ́ mẹ́rin ni mo fi bẹ Princess pé kí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha má di ẹjọ́ - Iya Rainbow
- Ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Interpol ṣèrànwọ́ fún ìjọba àpapọ̀ láti mú Nnamdi Kanu
- Orí àgbá ẹ̀tù láwọn èèyàn Ibarapa jókòó lé, wàhálà ń bọ̀ - OPC mẹ́ta tó gba ìdáǹdè
- Jide Kosoko, tí mo bá tú àṣírí rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ yóò dọwọ́ bojú - Nkechi Blessing yarí
- Mo dẹ́kun àdúrà gbígbà lẹ́yìn ikú Ajimobi - Florence aya olóògbé
- Oríire dé! Aláànú kan fún Kemisola ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ dé fásitì
- Omo Borty sọ̀rọ̀ sókè lórí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ àti Dino Melaye
- Òǹyẹ̀ kò lè yẹ ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko, mò ń bọ̀ níbẹ̀ - Sunday Igboho
- Obasanjo fèsì lórí báwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ń pe ààrẹ Buhari ní Jubril ti Sudan
Yomi ni a mọ ẹni to wo wọn dagba ati idile ti wọn ti jade wa nigba ti wọn ba n gbe apakan iroyin oju opo ayelujara lati ta fun araye.
O ni bi inu ba n bi eeyan kan nitori idi kan, tabi nkan ti ẹnikan se fun ninu ẹbi, to si n tabuku awọn agbaagba atawọn iran wọn to n bọ.
Yomi Fabiyi ni iru iwa bayii tumọ si pe iru ẹni bẹẹ ti n tabuku awọn obi rẹ nile, to si n bu wọn pẹlu.
O ni bakan naa si lo ri fun awọn eeyan to n ti iru ẹni bẹẹ lẹyin loju aye ati lori ayelujara.
"Ọmọ adulawọ ni wa, ti eeyan kan ba n fesi, to si n kọja aye rẹ nipa titabuku ipele ti Ọlọrun lo lati gbe onitọhun ga, ajẹ pe wọn ko mọ ohun to tọ niyẹn.
Yatọ si pe ka yẹra fun iru onitọun, ka si maa wo ni ọọkan, o tun se pataki pe ẹsan lati ọdọ Ọlọrun yoo waye."
Yomi Fabiyi fikun pe ko si ẹni ti wọn ko le tan jẹ lori ayelujara, ẹnikẹni si lo le sọrọ lori ohun kan tabi omiran lori ayelujara.
O wa kede pe ohun to daju ni pe ọjọ ọla loyun.

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi/Instagram
O ni bi ọrọ ba ti le diẹ, paapa eyi to jọ mọ iwa ọdaran, ko tọ ki awọn eeyan maa lo ọgbọn inu ti wọn tabi nkan miran to yatọ si ofin, lati fi yanju rẹ.
''Ọtọ ni aaye ile ẹjọ amọ loju opo ayelujara, nkan tawọn eeyan ba n sọ ni wọn maa n fẹ ki araalu tẹle.
Idi ni pe erongba ẹni to kọ ọrọ ni pe o fẹ kawọn eeyan tẹle nkan to ba fẹ ni.''
O tẹ siwaju pe "ki awọn eeyan lọ ni arojinlẹ daada, ki wọn si maa ranti pe aabo, alaafia ati ẹtọ ọmọniyan se pataki, ki a to kọ nkankan tabi bawọn se alabapin iroyin kankan loju opo ayelujara.''
Ko tan sibẹ, Fabiyi sọ pe "awọn to n fi aimọkan sọrọ loju opo ayelujara, ibẹ naa lariwo wọn maa n pin si."
''Fifi aimọkan han lori ayelujara paapa nigba ti ko ba ti lapa lori nkan ti ofin sọ, ko le kọja oju opo ayelujara''
"Awọn amofin ati adajọ ni imọ nipa ofin, ko si si nkan tẹle se si."
O fi kun ọrọ rẹ pe ti nkan tawọn eeyan ba n sọ lori ayelujara ba ba ofin mu, o se deede fawujọ ni yẹn.
Amọ bi o ba yapa si nkan tofin sọ, ko le yi nkan ti ofin sọ pada.
O wa rọ awọn to n se isiti yii fun pe ki wọn se ohun to tọ, ki wọn si ri pe awọn tẹle ohun to tọ.
Ọrọ ti Fabiyi sọ pọ ṣugbọn a ko n i le sọ gbogbo ẹ tan.
Eyi ta kan le fi tọka si ẹni to n ta ọfà ọrọ si ni pé ọrọ rẹ n waye laipẹ si igba tawọn oserebirin tiata meji kan, Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing fesi pada si ààrẹ ẹgbẹ oṣere TAMPAN, Jide Kosoko.
Ninu ọrọ awọn mejeeji, wọn ni awọn ko ni dakẹ lati maa sọ ohun to jẹ otitọ ati ododo paapa nipa ìṣẹlẹ tó kan Baba Ijesha, ti wọn fẹsun kan pe o ṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọde.




















