Iskilu Wakili Vs OPC: Àwọn OPC mẹ́ta tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ìdáǹdè l‘àhámọ́ sọ ohun tójú wọn rí

Oríṣun àwòrán, Facebook/OPC Diary
Awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹta ni agbegbe Ibarapa ti awọn ọlọpaa mu si ahamọ lasiko ti wọn mu afurasi ọdaran darandaran ni Igangan, Iskilu Wakilu, ti sọrọ nipa ohun ti oju wọn ri.
Orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ OPC naa, ti wọn jẹ igun Gani Adams ni Hazzan Raman, Dauda Kazeem ati Awodele Awodigba, ti gbogbo wọn jẹ ọmọ bibi agbegbe Ibarapa.
Awọn akọni mẹtẹẹta naa, ninu fidio kan to jade sori ayelujara salaye pe o ti to ọdun meji ti Wakilu ti bẹrẹ iwa ijinigbe gba owo, ifipabanilopọ ati ipaniyan lagbegbe Ibarapa.
- Nkán ìbànújẹ ni bí ọlọ́pàá ṣé ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC mọ́lé nítorí Wakili- Adari OPC
- Wakili àtàwọn méjì míì dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn, ìjínigbé àti olè kàn wọ́n
- Ọwọ́ ṣìnkún Àmọ̀tẹ́kùn tẹ afurasí agbẹ́bọn darandaran mọ́kànlá l‘Oyo
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Iskilu Wakili, afurasí Balógun Fulani tí OPC mú ní Ayetẹ ìpínlẹ̀ Ọyọ
- Àwọn lọ́balọ́ba nílẹ̀ Yoruba dalẹ̀ wa lórí àwọn ọmọ OPC mẹ́ta tí wọ́n tímólé láìṣẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Iskilu Wakili - Ẹgbẹ́ OPC
- Àṣẹ àwọn gómìnà là ń retí, àwa ti ṣetán láti dáàbò bo ilè Yorùbá- Gani Adams
- Ògo ilẹ̀ Yorùbá ní Sunday Igboho jẹ́, ẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ìràwọ rẹ̀ wọlẹ̀ - OPC
- Wakili jiyàn ọ̀rọ̀, ó ní òun kò mọ ohunkohun nípa ìṣekúpani tó ń wáyé n'Ibarapa méjèèje
Wọn ni afurasi ọdaran yii ni awọn ọmọ ogun to n sisẹ fun ninu isẹ ibi rẹ yii, ti awọn agbofinro si mọ gbogbo wọn bi isana ẹlẹẹta.
Wọn ni bi awọn ba se n mu awọn ọmọ Wakilu afurasi onisẹ ibi yii, ni awọn ọlọpaa ma n fi wọn silẹ, eyi to mu ki isẹ ibi rẹ maa lekenka siwaju si.
Awọn mẹtẹẹta salaye pe lẹyin ti Sunday Igboho fun awọn ọdaran Fulani ni gbedeke lati ko aasa wọn kuro ni agbegbe Ibarapa, ọpọ wọn lo salọ sinu igbo.
Wọn ni inu igbo yii ni wọn wa, lai le si igboro mọ tabi wọ inu ile wọn pẹlu.
Ọmọ Wakili sọ fun wa pe awọn yoo pa iran Yoruba run ni Ibarapa:
Ninu ifọrọwerọ naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ OPC yii ti salaye pe ọmọ Wakili to wa ni ahamọ pẹlu awọn sọ pe awọn Fulani ti setan lati pa iran Yoruba run ni agbegbe Ibarapa.
Wọn ni se ni ẹnu ya awọn ni ọjọ to sọrọ naa, to si fikun pe Fulani kii dari jin eeyan, o si di dandan ki awọn gbẹsan iwa tawọn Yoruba hu si Fulani.
"Ọmọ Wakili sọ fun wa pe ni ọjọ tawọn ba kọlu Yoruba ni agbegbe Ibarapa, ọrọ naa yoo kọ sisọ.
Inu atimọle si la wa nigba ta gbọ isẹlẹ ipaniyan ọlọgọọrọ to waye nilu Igangan laipẹ yii, ẹnu si ya wa lootọ.
Koda, o sọ fun wa pe awọn Miyetti Allah ti tọwọ bọ ọrọ wa, ti a si gbọdọ fi oju bale ẹjọ dandan."
Wọn fikun pe ori ẹtu ibọn ni awọn eeyan agbegbe Ibarapa joko le, o si yẹ kawọn ọba wa dide si ọrọ yii nitori ogun si n bọ.
"Awọn Fulani ti ni awọn n bọ wa jẹ ilu wa run, a si fẹ kawọn ọba wa jade sita lati ke yanya pe a ko fẹ Fulani mọ ni agbegbe Ibarapa.
To ba jẹ pe bi Sunday Igboho ti kegbe sita, naa ni awọn ọba sugba rẹ, lai jẹ ko sinmi, ti wọn si n gbogun ti awọn Fulani yii, ọrọ ko ba ti yanju.
A si fẹ ki awọn ọba wa sọ fun awọn Fulani to sa lọ silu Igbo Ora pe ki wọn kuro nibẹ, ki alaafia le jọba ni awọn agbegbe yoku to wa ni Ibarapa."
Awọn Yoruba ara wa lo n se agbodegba fun Wakili:
Awọn akọni ọmọ Oodua yii tun sisọ loju rẹ pe awọn ọmọ Yoruba ti wọn n ko ẹran fun Iskilu Wakilu atawọn darandaran Fulani yoku lati tọju fun wọn lo wa lẹyin awọn afurasi ọdaran naa.
Wọn ni awọn ọmọ Yoruba yii lo maa n pe Wakilu lati se ofofo fun lasiko ti awọn eeyan kan ba fẹ lọ kọ lu ninu igbo to wa, ti yoo si mura silẹ de wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Jide Kosoko, tí mo bá tú àṣírí rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ yóò dọwọ́ bojú - Nkechi Blessing yarí
- Mo dẹ́kun àdúrà gbígbà lẹ́yìn ikú Ajimobi - Florence aya olóògbé
- Oríire dé! Aláànú kan fún Kemisola ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ dé fásitì
- Omo Borty sọ̀rọ̀ sókè lórí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ àti Dino Melaye
- Òǹyẹ̀ kò lè yẹ ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko, mò ń bọ̀ níbẹ̀ - Sunday Igboho
- Obasanjo fèsì lórí báwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ń pe ààrẹ Buhari ní Jubril ti Sudan
Bakan naa ni wọn fi kun pe awọn agbodegba ọmọ Yoruba naa lo maa n lọ ra eroja ounjẹ, awọn ohun eelo miran pẹlu ohun ija fun Wakilu lasiko to wa ninu igbo to salọ lẹyin abẹwo Sunday Igboho.
"Awọn Yoruba ara wa to jẹ Alapata, lo sofofo fun Wakili pe a n bọ lọjọ ti a lọ mu. Wọn ti gbaradi de wa, ti wọn si n yinbọn mọ wa, lọjọ ti a lọ mu.
Amọ Oodua tẹle wa lọjọ naa ni ọwọ wọn ko se ka wa, koda, awọn baba nla wa ko sun lọjọ naa, wọn gbe wa nija ni, bibẹẹkọ, ọrọ naa ko ba yiwọ."
Wakili ni ko si Baba nla baba ẹni to le le oun kuro ni agbegbe Ibarapa:
Nigba ti wọn n salaye ọpọ igbesẹ to ti kọkọ waye saaju lati mu afurasi ọdaran naa, awọn akọni ajijagbara naa ni ofo ni gbogbo igbesẹ lati mu n ja si.
Wọn salaye pe awọn apapọ araalu ti kọkọ fun Wakili ni iwe pe ko fi agbegbe naa silẹ, ta mọ si Quit Notice amọ wọn lo fi aake kọri ni.
Wọn ni Wakili sọ fawọn araalu pe ko si baba nla baba ẹni to le le oun kuro ni ibi ti oun wa.
"Saaju ni igbesẹ awọn ọlọpaa lati mu Wakili n ja si pabo nitori bi wọn ba se fẹ mu, ti wọn de ẹnu ọna ile rẹ, ni wọn yoo ni asẹ wa lati oke pe ki awọn fi silẹ.
Nigba to ya nijọba ipinlẹ Oyo fi ikọ Amotekun sọwọ lati mu, ti wọn si kun inu ọkọ nla Hilux bii mẹẹdogun amọ o ku diẹ ki wọn wọnu igbo to wa, ni wọn duro.
Wọn ni awọn tun ti gba "order" pe awọn ko gbọdọ wọnu igbo lọ mu, eyi si lo kọ wa lominu lati lọ mu funra wa.
Awọn ọdaran Fulani darapọ mọ ọlọdẹ fijilante lati sisẹ ibi:
Awọn ọmọ ọgbẹ OPC mẹtẹẹta yii tun salaye pe ẹran ti wọnu egungun, egungun si ti wọnu ẹran, ni ọrọ awọn ọdaran Fulani to wa ni agbegbe Ibarapa.
Wọn ni ọpọ awọn afurasi ọdaran naa ni wọn dara pọ mọ awọn ọdẹ ibilẹ fijilante lati maa sisẹ ibi wọn.
"Wọn n lo isẹ Fijilante naa lati maa ra awọn ohun ija oloro to lagbara, ti wọn si n sọ fun awọn agbofinro to ba bi wọn lọna pe fijilante ni awọn.
Koda, wọn ni Kaadi idanimọ fijilante lagbegbe Ibarapa lọwọ, ti wọn si n fi se isẹ ibi."
Awọn ọmọ Wakili lo jo ile ati dukia wọn, ti wọn si parọ mọ wa ni ọdọ ọlọpaa pe awa la sisẹ ibi naa:
Awọn OPC naa fikun pe nigba ti awọn mu Wakili de ọdọ ọlọpaa, ni ọmọ rẹ ti awọn ọlọpaa ti n wa lati ọjọ pipẹ wa ba awọn nibẹ.
Wọn ni awọn ọmọ Wakili yii wa fi ẹsun sun awọn ọlọpaa pe awọn ni awọn jo ile ati dukia Wakili, nigba to si jẹ pe funra wọn ni wọn ti dana sun awọn eroja naa.
Atimọle lati wa ridi okodoro ọrọ nigba ti ọmọ Wakili naa sọ fawọn pe awọn huwa naa lati ro ẹjọ mọ awọn lẹsẹ ni nitori awọn kuku mọ pe awọn ko le pada sinu ile awọn to wa laarin ilu mọ.
Wayi o, awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹtẹẹta naa ti wa leri leka pe awọn ko ni dẹkun gbigbe iran awọn nija bi o tilẹ jẹ pe oju awọn ri ni ahamọ, tawọn si padanu ọpọ nnkan rere lasiko ti awọn wa ni atimọle.
Bakan naa ni wọn sọ iya nla to jẹ awọn mọlẹbi wọn lasiko ti wọn fi wa ni ahamọ ọlọpaa.






















