Fulani-Herders Crisis: Ọlọ́pàá ní Amotekun, OPC àti Fijilanté ló rí àwọn afurasí náà mú

Awọn afurasi ọdaran darandaran

Oríṣun àwòrán, Amotekun

Ikọ alaabo nilẹ Yoruba, Amọtẹkun ti fi oju awọn afurasi ọdaran mẹfa, ti ọwọ wọn tẹ ni ipinlẹ Ọyọ han si gbangba.

Ninu atẹjade ti Adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Oyo, ọgagun Olayinka Olayanju fi lede ni, ijọba ibilẹ Kajọla nipinlẹ Oyo lọwọ ti tẹ awọn afurasi ọdaran naa, ti wọn jẹ agbebọn darandaran.

Olayanju ni ajọṣepọ awọn ikọ eleto aabo labẹle bi awọn vigilante ati awọn ọmọ ẹgbẹ OPC lo ṣiṣẹ pọ, ti ọwọ fi tẹ awọn agbebọn lasiko ti wọn n ṣe iwọde ka.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni owurọ kutu Ọjọ kọkandinlọgbọn, Oṣu Kẹrin, ni ọwọ tẹ awọn agbebọn naa ni ijọba ibilẹ Kajọla ni ibi ti wọn ti gbe igi di opopona ti awọn eniyan n gba kọja.

Awọn afurasi ọdaran darandaran

Oríṣun àwòrán, Amotekun

Ikọ Amọtẹkun ni bi o tilẹ jepe wọn gbiyanju lati sa mọ awọn lọwọ, awọn ri wọn gbamu lẹyin ti wọn le wọn wọ inu igbo lọ.

Orukọ awọn afurasi agbebọn to jẹ Fulani naa ni Awali Atine, Ibrahim Abu, Shuaib Balau, Ibrahim Musa, Abdullah Masika ati Umar Aliu Masika.

Awọn afurasi agbebọn naa ni wọn n ṣọṣẹ ni agbegbe Okeho-Ilua ati Okeho-Iṣẹyin, nipinlẹ Oyo.

Ikọ Amọtẹkun ni awọn afurasi agbebọn yii ni ma n ṣiṣẹ gẹgẹ bi Fulani darandaran ni ọsan, ti wọn a si dena da awọn eniyan ni oru.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Lasiko ti wọn ri wọn gbamu, maalu to le ni ọgọsan ni wọn gba ni ọwọ wọn pẹlu ohun ija oloro ni oriṣiriṣi ati iye owo to to #268, 470.00.

Ikọ Amọtẹku naa fikun pe awọn tun ri awọn afurasi agbebọn marun un miran ni apa ila oorun Saki, ti awọn si ti fa wọn le ikọ ọlọpaa lọwọ.

Bakan naa ni ikọ Amọtẹkun naa wa rọ awọn araalu lati ran awọn lọwọ nipa fifi iroyin ti yoo ran iwadii lọwọ fi to awọn leti.