Baba Ijesha: Iyabo Ojo àti àwọn obìnrin kan ń ṣèwọ́de tako ìtúsílẹ̀ afurasí náà

Gbajumọ osere tiata lobinrin, Iyabo Ojo, ẹni to n gbara ta lori ọrọ Baba Ijesha ati ọmọde ti wọn lo fi tipa ba lopọ, ti mu ileri rẹ sẹ.
Iyabo, to n leri leka ninu fidio kan to se loju opo Instagram rẹ lalẹ Ọjọru, lo ni ohun yoo ba ọrọ ẹsun ti wọn fi kan Baba Ijesha de opin, ti idajọ ododo yoo si wa.
Iyabo, ẹni to ni kede pe awọn eeyan kan n saayan lati yọ baba Ijesha latimọle ọlọpaa lọjọ Ẹti, wa fọwọ gbaya pe oun ko ni gba ki wọn tu afurasi naa silẹ.
- Iyabo Ojo gbé fídíò jáde nípa bí ọwọ́ ṣe tẹ Baba Ijesha
- Ẹ̀yin tí Baba Ijesha bá ọmọ tàbí àbúrò yín lòpọ̀ láìtọ́, ẹ fi ẹjọ́ ṣùn mí - Princess Comedian
- Iyabo Ojo àti Foluke Daramola tako ara wọn lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Ẹgbẹ́ òṣèré tíátà TAMPAN sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀ṣùn bíbá ọmọdé lòpọ̀ tí wọn fi kan Baba Ijesha
- Gbogbo abiyamọ aye ẹ gba wá, wọ́n ti fẹ́ tú Baba Ijesha silẹ - Iyabo Ojo figbe ta
- Òṣèré tíátà gbọnmú lórí ẹnu àbùkù tó ń kun àwọn òṣèré Yorùbá torí Baba Ijesha
- Ipa tí Fathia Balogun kó nínú bí mo ṣe dèèyàn lágbo òṣèré fíìmù Yorùba rèé - Baba Ijesha
Lọna ati mu ileri rẹ sẹ, Iyabo ti wa gba agọ ọlọpaa Panti lọ nilu Eko lati lọ fi ẹhonu rẹ han pe wọn ko gbọdọ tu Baba Ijesha silẹ ni ahamọ.
Iyabo, ẹni to kọwọ rin pẹlu awọn obinrin kan ti ọpọ wọn jẹ osere tiata bakan naa, ni wọ́n n ke fata fata niwaju agọ ọlọpaa naa pe wọn ko gbọdọ tu Baba Ijesha silẹ.
"Ọrọ eyi kii se ọrọ eeyan kan mọ, o ti di ọrọ gbogbo abiyamọ. Ko si ibi ti a n lọ, ibi ti a maa wa ni eleyi.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Gbogbo wa la bimọ, bawo ni agbalagba ọkunrin yoo se maa ba ọmọkekere lopọ, a ni gba. Ta lo fẹ́ fi silẹ, nibo lo fẹ wọ, gbogbo wa la bimọ."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Iyabo Ojo gbé fídíò jáde nípa bí ọwọ́ ṣe tẹ Baba Ijesha
- Mò ń ké tantan, tí Buhari kò bá fí ipò sílẹ̀, ìbò 2023 kò ní wáyé - Father Mbaka
- Yekeen Ajileye, ọ̀gá mi nínú iṣẹ́ tíátà ṣẹ̀ mí, ó ṣẹ ẹlẹ́dàá mi - Abija
- Ẹ̀yin tí Baba Ijesha bá ọmọ tàbí àbúrò yín lòpọ̀ láìtọ́, ẹ fi ẹjọ́ ṣùn mí - Princess Comedian
- Ẹpọ̀n àgbò kàn ń mì lásán ni lórí ètò ààbò Nàíjíríà tó mẹ́hẹ, kò ní já - Obasanjo
- Gbogbo abiyamọ aye ẹ gba wá, wọ́n ti fẹ́ tú Baba Ijesha silẹ - Iyabo Ojo figbe ta
Titi di akoko ta n ko iroyin yii jọ, Iyabo ati awọn akẹẹgbẹ rẹ naa si wa niwaju agọ ọlọpaa Panti nilu Eko nibi ti wọn ti n fi ẹhonu han.

Òṣèré tíátà gbọnmú lórí ẹnu àbùkù tó ń kun àwọn òṣèré Yorùbá torí Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, legemiami/Instagram
Yoruba ni ti ọrọ ba se n pẹ nilẹ, naa ni yoo maa gbọn si.
Bẹẹ ni ọrọ ẹsun ifipa ba ọmọde lopọ ti wọn fi kan gbajumọ osere tiata kan, James Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Ijesha ri.
Idi ni pe oniruuru ọrọ lo ti n jẹyọ lẹyin ti iroyin naa jade sita, tawọn akẹẹgbẹ rẹ ninu isẹ tiata atawọn araalu si ti n sọ oniruuru ero wọn nipa isẹlẹ naa.
Lara wọn ni gbajumọ osere tiata lọkunrin kan, ti gbogbo eeyan mọ si Legemiami, to sọrọ nipa ẹsun ti wọn fi kan Baba Ijesha.
- Tí òṣèré tíátà yóò fi kú, eré ni wọn yóò ló ń ṣe - Ibrahim Chatta
- Òṣèré méjì yìí ń fi ẹ̀wọ̀n runmú tóríi fíìmù "Ife" táwọn obìnrin ń bá ara wọn lòpọ̀
- Ẹ gbà mí o, wọ́n ti ń fi kóló mi kó àwọn èèyàn lómi ọbẹ̀ jẹ- Tawa Ajisefinni
- Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá tó bí ìbejì
- Wo àwọn sinimá mẹ́wàá tó gbé sinimá Yorùbá sáyé
- Ṣé o mọ iye òṣèré fíìmù Yorùba àti olórin tó bá ọdún 2020 lọ?
- Kíni ẹ mọ̀ nípa àwọn gbajúgbaja Yollywood?
Lege, ẹni to fi ọrọ naa sita loju opo Instagram rẹ lasiko ti iroyin jade nipa rẹ ni ko dara bi awọn eeyan kan se n da baba Ijesha lẹbi lori ẹsun naa saaju idajọ ileẹjọ.
Lege ni lootọ ni wọn fi ẹsun kan gbajumọ osere naa pe o fipa ba ọmọde lopọ, amọ wọn ko se afihan fidio bi Baba Ijesha ti n hu iwa ibajẹ naa.

Oríṣun àwòrán, legemiami/Instagram
"Se ile kanna abi adugbo kanna ni wọn jọ n gbe ni, lo se rọrun fun lati ba ọmọ naa lopọ lati ọmọ ọdun meje, ko ye mi.
Awọn akẹẹgbẹ mi kan ti n jade, ti wọn si n sọrọ nipa isẹlẹ naa eyi to n fun awọn eeyan kan lọrọ sọ, ti wọn si n sọrọ buruku nipa agbo isẹ tiata Nollywood, ẹka ti Yoruba.
To ba jẹ pe bẹẹ ni, ika to ba sẹ ni ọba n ge, bi o tilẹ jẹ pe oun ko se atilẹyin fun ohun ti baba Ijesha se."
Legemaimi wa n beere pe ki ni awọn osere fiimu Yoruba se fun awọn eeyan to n bu awọn osere tiata lede Yoruba, se awọn lo sẹ wọn ni?
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
O ni ko si idaniloju pe Baba Ijesha hu iwa naa, yoo si dara ki wọn ni suuru ki ileẹjọ dajọ naa, ki wọn to maa tanuku awọn osere.
Osere tiata naa wa jẹjẹ pe awokọse rere ni oun maa jẹ fawọn ololufẹ oun, oun ko si le fara mọ iwa ifipa banilopọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ó tún n rúgbó bọ̀! Ṣé lóòótọ́ ni Olori Damilọla ti sá kúrò ní ààfin Ọyọ?
- Bàálù ọmọ ogun òfúrufú ṣèèèsì pa sọ́jà 20 ní Borno, ọmọ Naijiria fárígá
- Yorùbá, ẹ má ṣùn o lórí ààbò tó mẹ́hẹ torí àìláṣọ lọ́rùn pààká... - ARG lọgun
- Ọjọ́ Ajé gba ọ̀pọ̀ ẹ̀jẹ̀ ọmọ Nàíjíríà láti ọwọ́ àwọn agbébọn
- Agbébọn yabo ilé Sunday Igboho ní òru mọ́jú
- Iyabo Ojo àti Foluke Daramola tako ara wọn lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
Amọ awọn ọrọ to Legemiami sọ yii ti bọ si apo ibinu awọn eeyan kan, ti wọn si ti bọ sori ayelujara lati maa naka aleebu si osere tiata naa.
Ọpọ awọn obinrin si lo n naka aleebu si pe ọwọ oun gan ko mọ nipa iru ẹsun ti wọn fi kan Baba Ijesha, nitori naa lo se n gbe lẹyin rẹ.
Awọn miran kan tiẹ tun fi ẹsun gbajuẹ kan, eyi tawọn ileesẹ iroyin ayelujara kan n gbe soju opo wọn.
Koda, oju opo ayelujara ti kun nipa orisirisi iroyin nipa awọn osere tiata kan lede Yoruba, ti wọn n naka aleebu si pe wọn n hu iru iwa ti baba Ijesha hu, eyi ti awa ko ni darukọ wọn.
Awọn ẹsun naa pọ to bẹẹ gẹẹ ti osere tiata yii fi tun bọ sori ayelujara lati maa bẹ awọn obinrin pe ki wọn tu eekanna lẹyin ọrun oun.
Legemiami ni kawọn obinrin to n pa irọ mọ oun nitori ero ohun nipa ọrọ baba Ijesha jọọ dari jin oun, oun ko ni se bẹẹ mọ.
O ni "Nibi ta ba de yii, o daa bayii, mo bẹ ẹyin obinrin patapata pe ki ẹ dari jin mi, n ko ni se bẹẹ mọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 4
N ko fara mọ nnkan ti ko dara, mo kan ni ọrọ naa ko ri bẹẹ ni amọ ẹ dari jin mi.
Nnkan ti n ko se ni wọn ti fi n kan mi bayii, ẹ dakun ẹ dari jin mi. Ẹ ko ni ri ibi, ẹ ko ni sofo tabi sunkun ọmọ"
Ọrọ wa di ibẹru obinrin ni ipilẹsẹ ọgbọn fun Legemiami, to si n rawọ rasẹ si gbogbo obinrin pe ki wọn fori jin oun.
- Ìrù ejò lẹ̀ ń fà pẹ̀lú ìkọlù lemọ́lemọ́ sílé Sunday Igboho - Àgbààgbà Yorùbá
- Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ ní Iyana Iba l‘Eko lọ́jọ́ Aje, ọlọ́pàá ní kíì ṣé ìjà ẹlẹ̀yàmẹ̀ya
- Keyamo dójú ti ara rẹ̀ àti ìjọba tó ń sìn bó ṣe kéde ìtàkurọ̀sọ rẹ̀ pẹ̀lú Eedris fáyé - Amofin
- Ọmọ Nàíjíríà kan kú lásìkò tó bẹ́ sí River Thames ní London torí ó fẹ́ dóòlá ẹ̀mí obìnrin kan
- Buhari ló ń ki àwọn agbésùnmọ̀mí láyà láti ṣe ìkọlù - Ajàfẹ́tọ̀ọ́ẹni

















