Insecurity: Afenifere ní àtúntò nìkan ni ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Naijiria, kìí ṣe ìpinyà

Awọn gende agbebọn

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Awọn agbagba ilẹ Yoruba kan ti sọ pe, o di igba ti ijọba apapọ ba ṣe atunto si eto iṣejọba Naijiria, ki alaafia to le waye.

Akọwe apapọ fẹgbẹ Afenifere, Bashorun Seinde Arogbofa ati adari ẹgbẹ Afenifere Renewal Group, ARG, Wale Osun lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba.

Arogbofa ni o di igba ti Naijiria ba pada si bi wọn ṣe n ṣe ijọba laye atijọ, ti rukerudo to n lọ lọwọ, to le kasẹ nilẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni o yẹ ki agbegbe kọọkan ni Naijiria ni ọlọpaa tirẹ, eyii ti yoo maa daabo bo awọn eeyan agbegbe rẹ.

O ni bi ijọba apapọ ṣe wa gbogbo eto iṣejọba mọya yii, bii ọrọ aje, eto igbanisiṣẹ, eto abo, ati bẹẹ bẹe lọ, lo jẹ ki gbogbo rẹ wọ.

Ibon

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Arogbofa ni "Ṣe ẹni to wa ni Maiduguri lo fẹ mọ nnkan to n ṣẹlẹ nipa eto abo nibi ju emi ti mo wa nikalẹ ni ipinlẹ Ondo nibi yii lọ?"

"Ẹ wo awọn nnkan to n ṣẹlẹ bayii, bi wọn ṣe n pa awọn eeyan wa ni ipakupa, ti wọn si ṣi awọn bode wa silẹ, ti awọn eeyan kan n wọle lati oke ọya."

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn iroyin ipaniyan lojojumọ lo fa eredi ti awọn kan fi n sọ pe, awọn n fẹ ki Naijiria pinya, ki onikaluku si maa lọ nilọ tirẹ.

O ṣalaya pe, irufẹ ijọba ti wọn n ṣe nilẹ Amẹrika, eyi ti wọn n pe ni "Federalism" ni ẹgbẹ Afenifere n fẹ ki wọn gbe kalẹ ni Naijiria.

O ni atunto ti onikaluku ipinlẹ yoo maa bojuto nnkan ini ilẹ rẹ, ti wọn a si maa fi nnkan diẹ-diẹ sọwọ si ijọba apapọ loke.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Arogbofa sọ siwaju si pe, gẹgẹ bii ọkan lara awọn to kopa ninu ipade apero ọdun 2014, ko si ọkan ninu aba ti wọn da nibi ipade naa to n lọ bii ẹgbẹta, ti ijọba apapọ mu lo.

Agbekalẹ ọlọpaa agbegbe ni yoo yanju ọrọ aabo to mẹhẹ - ARG

Ẹwẹ, adari ẹgbẹ ARG, Wale Osun naa ṣọ pe atunto ati ọlọpaa agbegbe ni ọna kan gboogi lati yanju iṣoro Naijiria, paapaa, eto abo to mẹhẹ, ọrọ aje to dẹnukọlẹ ati airiṣẹ ṣe awọn ọdọ.

Ṣaaju ni ARG ti kọkọ ke pe Alaafin ilu Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta ati Ooni ti Ile Ife, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi, Ojaja keji, lati ke si awọn lọbalọba ẹgbẹ wọn, fun ipade apero lori ọna abayọ si iṣoro to n ba Naijiria finra.

O ni awọn ke pe awọn Ọba alaye mejeji naa, nitori wọn kii ṣe oloṣelu, wọn si tun jẹ alẹnulọrọ lawujọ.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Wale Osun ni, bo tilẹ jẹ pe awọn ko lagbara lati da asiko ti awọn ori ade naa yoo ṣepade apero naa, ṣugbọn awọn ti fi iwe ranṣẹ si wọn ki nnkan to bajẹ to kọja bẹẹ.

O pari ọrọ rẹ pe, oju ni alakan fi n fi n ṣọri, nitori naa ki awọn eeyan ilu mu eto abo ara wọn ni ọkunkundun.

Lẹyin naa lo wa rọ ijọba apapọ lati ṣeto atunto, ko si tun fọwọ si agbẹkalẹ ọlọpaa agbegbe, ki Naijiria le tẹsiwaju.

Amin iyasọtọ kan

Yorùbá, ẹ má ṣùn o lórí ààbò tó mẹ́hẹ torí àìláṣọ lọ́rùn pààká... - ARG lọgun

Ooni ati Alafin

Oríṣun àwòrán, Alaafin of Oyo Facebook

Yoruba ni ailasọ lrun paaka, apero gbogbo ọmọ eriwo lo jẹ nitori iku to ba n pa ojugba ẹni, owe nla lo n pa fun ni.

Lójúnà láti wá ojúùtú sí gbogbo ọ̀rọ̀ ètò ààbò tó mẹ́hẹ, láti orí ìjinigbé, ìdigunjalè, ìkọlù darandaran ni ilẹ̀ Yorùbá, ni ẹgbẹ́ Afenifere Renewal Group (ARG) se ké sí àwọn oríadé nilẹ Kaarọ-Oojire.

Wọ́n ké pé Aláàfin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi Kẹta, àti Ọ̀ọ̀ni ilé Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ọ̀jájá Keji atawọn oriade mii láti pe ìpàdé àpérò àwọn adari àti aṣojú ilẹ̀ Yorùbá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nínú àtẹ̀jáde ti ẹgbẹ́ náà fi síta ni ọjọ́ Ajé, tí àkọ̀wé ìpolongo ẹgbẹ́ náà Kunle Famoriyo sì fọwọ́sí sàlàyé ogun mẹ́ta tó ṣíji bo orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Atẹjade naa ni awọn ogun ọhun ni ètò àbò tó mẹ́hẹ, ọ̀wọ́n gógó ọja àti àìríṣẹ́ṣe àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re Renewal Group rọ Aláàfin, Òòni láti pe ìpàdá apérò asájú Yorùbá.

Oríṣun àwòrán, AFenifere

Ó ní èyí sì ń mú ìfàsẹ́yìn bá ìṣerere ọmọ Yorùbá, èyí sì ló fa ìpè fún ọ̀nà abáyọ àti láti gbárùkù àwọn adarí nínú olóṣèlú.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde naa ṣe sọ " bí àwọn gómìnà Nàìjíría mííràn ṣe ṣe nǹkan tó lààmì laaka tó, síbẹ̀, òfin ká àwọn mííràn lápá kò láti ṣe ǹkan tó yẹ nidi ipese eto aabo to peye.

Amọ ẹgbẹ ARG ni síbẹ̀, ó di dandan kí àwọn ènìyàn gbé ìgbésẹ̀ lati wa ojutu si bi gbogbo nǹkan ṣe rí yìí.

"Láti rí ọ̀nà àbáyọ, ó ti di dandan kí àwọn oríadé pé ìpàdé láti pé àwọn ènìyàn jọ fún igbésẹ̀ akin"

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Kọ́ ẹ̀kọ́ si nípa ààlọ́ nílẹ̀ Yorùbá

"A ko le má tan ara wa pé ǹkan si dára nilẹ̀ Yorùbá tàbí pé gbogbo ǹkan tí ó n ṣẹlẹ̀ ni ìhà Nàìjíríà tó kù àti àwọn orílẹ̀dè tó yí wa ka yìí, kò kan wá.

Lọ́wọ́lọ́wọ́ ìwà ọ̀daran ti n peléke síi pẹ̀lú bi ọ̀pọ̀ ṣe ń sálọ kúrò lórílẹ̀ -èdè yìí àti bí òṣì àti iṣẹ́ ṣe ń pọ̀ si.

"Ẹgbẹ́ náà ni àwọn ní ìgbàgbọ́ pé aṣeyọrí Nàìjíríà níṣe pẹ̀lú ìgbésẹ̀ akin tí àwọn adári bá gbé ní ìhà gúúsù-ìwọ-òòrùn.

Wọ́n sì rọ wọ́n pé kí wọ́n wá ààye láti gbé ìgbésẹ̀ yìí fún ànfàni ará ìlú.