Alaafin: Àwọn ẹlẹ́yinjú àánú ń kówó jọ fún olorì Alaafin Oyo, Damilola láti fi gba ilé

Oríṣun àwòrán, officialqueen_dami
O dabi ẹni pe asiko yii ko dara lori bi Olori Damilola se kuro ni aafin Oyo, ti ara ko si rọ okun fun.
Gẹgẹ bi iroyin to n ja lori ayelujara, a gbọ pe Olori Damilola ti lọ ba ọrẹ rẹ kan pe ko saanu oun nitori apo oun gbẹ.
Lọwọlọwọ bayii, a gbọ pe ilu Eko ni Olori Damilola sa wa, ti wọn si ti n se eto ikowojọ fun lati ri pe o ri nnkan dimu.
Koda, se ni wọn fi ọrọ ti Olori Damilola sọ nipa ipo inira to n la kọja naa soju opo ayelujara nibi ti iya rẹ gan ti n sọkun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bayii ni ọwọ́ mi ṣe tẹ Baba Ijesha pẹ̀lú ọmọ mi - Princess Comedian
- Ọ̀rọ̀ Baba Ijesha dá ìjà sílẹ̀ láàrin Iyabo Ojo àti Yomi Fabiyi
- Remi Tinubu rí ìbínú ọmọ Nàíjíríà lórí bó ṣe tọwọ́ òṣèlú bọ ètò ààbò
- Ìwàásù Baba Adeboye ló sọ mí di Kristẹni - Funke Etti
- Wo oore tí Ramadan n ṣe fún àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn tó n gbà á
- Kò sí orílẹ̀èdè tí kìí la àkókò ìnira kọjá - Bola Tinubu
- Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ fún ẹyà Igbo ní ilẹ̀ Biafra àti òmìnira tó ń fẹ́ - Ẹgbẹ́ 52 lókè ọya rọ United Nations
Bakan naa ni wọn tun fi atẹjisẹ ti Damilola fi ransẹ si ọrẹ rẹ naa sori ayelujara nibi to ti n sọ fun onitọun pe oun sẹsẹ gunlẹ silu Eko ni.
Damilola ni ko si ibi kankan ti oun fẹ sun ni alẹ ọjọ naa, ti oun si nilo lati fi ori ha ibi kan di ọjọ keji.

Oríṣun àwòrán, Gistlovers
O ni Kabiyesi sọ fun oun pe ki oun kuro ni aafin nitori oun ko fẹ ri oun, to si ni ki wọn ti ilegbe mi.
Aanu Olori naa si lo se awọn eeyan to ka iroyin naa, ti wọn si n da owo jọ fun Olori Damilola, ki aye le tubọ rọrun fun nilu Eko.
Ni idaji oni ti wọn gbe iroyin naa sita, owo ti wọn n da jọ fun Olori Damilola ti le ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin naira (₦857,000)
Bẹẹ ba gbagbe, saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Olori Damilola ti kuro ni aafin Oyo nitori ọrẹ rẹ kan to gba sile nigba ti onitọun ni isoro.

Oríṣun àwòrán, Gistlover
Amọ lẹyin o rẹyin, ọrẹ yii ti di aayo Alaafin, ti Olori Damilola si faake kọri pe obinrin naa, to pe orukọ rẹ ni Abebi, ko le ba oun se orogun.
Idi si niyi to se ni wọn le oun jade ni aafin Oyo ni aajin oru, to si sa lọ silu Eko lati lọ bẹrẹ igbe aye tuntun.

Àkàrà tú sépo! Wo bí ọ̀rẹ́ Olorì Damilola ṣe gba Alaafin mọ lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, officialqueen_dami/nstagram
Saaju la ti fi to yin leti pe iroyin to gba ori ayelujara kan ti salaye bi Olori Damilola se ko jade ni aafin Oyo.
Gẹgẹ bi ọrẹ Olori Damilola kan ti salaye lori ayelujara, olo ẹlẹjẹ tutu kan tii se ọrẹ fun Olori naa, ni baba ṣẹṣẹ ri lati fi se ayaba.
Ẹyin naa ni boo lo ṣe jẹ? Ẹ jẹ ki a bu yin gbọ bo ṣe jẹ gẹgẹ bi itakurọsọ to waye laarin olori Damilọla ati ọrẹ rẹ, eyi to n bẹ lori gbajugba oju opo ayelujara Instagram kan.
- Kà nípa ohun tí Alaafin Oyo sọ nípa "ìkòkò ọbẹ̀" àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́jọ́ Kérésìmesì
- Kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàfin Oyo táwọn èèyàn fi ń ki Alaafin ní mẹ́sàn án mẹ́wàá?
- Ẹ̀yin oríadé, tẹ bá fẹ́ mọ ìtàn Yorùbá, ẹ lọ kọ́ lọ́dọ̀ Alaafin - Oluwo
- Bí Gómìnà Makinde bá ṣẹ̀ mí, lẹ́tà lásán ló jẹ mí- Aláàfin Ọ̀yọ́
- Àṣírí ńlá tó ń bẹ láàrín Alaafin àtàwọn onílù rẹ̀ rèé
- Àwọn onílù mí ló ń tú àṣírí ìkà èèyàn tó bá wọ ààfin mi - Aláàfin
Ọrọ naa la gbọ pe o bẹrẹ nigba ti ọmọbinrin kan ti wọn ni olori Damilọla pe orukọ rẹ ni Abẹbi lati ilu Ibadan, kan si olori Damilọla pe iṣẹ n ṣẹ oun, oun si nilo iranlọwọ ayaba naa, ki jijẹ ati mimu lee di irọrun.

Oríṣun àwòrán, officialqueen_dami/nstagram
Ohun ti a gbọ ni pe olori Damilọla gba, o si pe Abẹbi yii lati wa maa baa da si owo aṣọ adirẹ to n ṣe.
Lẹyin eyi ni a gbọ pe ọwọ kan ọwọ, ẹsẹ kan ẹsẹ laarin Kabiyesi alaafin ati Abebi Ibadan, lo ba fi eyi ti Alaafin Ọyọ ati Abebi Ibadan jumọ di wọlewọde, titi ti o fi di aayo baba.
Igba ti wọn ni Kabiyesi n gbero ati kuku wa gbe Abẹbi ọrẹ olori Damilọla niṣulọka, ni olori Damilọla ba fariga pe Kabiyesi ko lee maa gun ori oun, ko tun maa gun ori ọrẹ oun.
Eyi, gẹgẹ bi oju opo ikansira ẹni Instagram ti Olori Damilọla ba sọrọ ṣe sọ, lo faa ti Kabiyesi Alaafin fi ni ki Olori Damilọla maa lọ kuro laafin.
Lasiko ti iroyin yii fi n jade, aafin ọyọ ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ fún ẹyà Igbo ní ilẹ̀ Biafra àti òmìnira tó ń fẹ́ - Ẹgbẹ́ 52 lókè ọya rọ United Nations
- Kò sí orílẹ̀èdè tí kìí la àkókò ìnira kọjá - Bola Tinubu
- Wo oore tí Ramadan n ṣe fún àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn tó n gbà á
- Ìwàásù Baba Adeboye ló sọ mí di Kristẹni - Funke Etti
- Ta ló ń fi orúkọ Oluwo lu àwọn obìnrin ní jìbìtì lórí ayélujára?
- Òṣèré tíátà gbọnmú lórí ẹnu àbùkù tó ń kun àwọn òṣèré Yorùbá torí Baba Ijesha
- El-Rufai yarí kanlẹ̀, ó ní ìjọba òun kò ní san owó fún àwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé
Ni odun meji sẹyin ni Olori Damilọla di ayaba laafin Oyo.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ti le iya olori Damilọla at'awọn mọlẹbi rẹ kuro laafin Ọyọ.
Koda gẹgẹ bi ọrọ inu atẹranṣẹ ti Olori Damilọla fi ranṣẹ to fi ke gbajare sita, o ni ọkan lara awọn iransẹ kabiyesi ni wọn ran pe ko da ẹru oun sita.

Ó tún n rúgbó bọ̀! Ṣé lóòótọ́ ni Olori Damilọla ti sá kúrò ní ààfin Ọyọ?

Oríṣun àwòrán, officialqueendamifanpage/Instagram
Iroyin to n lọ nigboro bayii, ta ni ka gbe si yin leti ni pe Olori Damilola, tii se ọkan lara awọn 'Ẹlẹ Daddy', Oxygen ti Alaafin ìlú Ọyọ, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta fi n mi, tun ti kuro ni aafin.
Bẹẹ ni oniruuru awọn ileesẹ iroyin ori ayelujara lo ti n gbe iroyin sita lati alẹ ọjọ Aiku pe olori Damilọla naa ti fi aafin silẹ.
Igba akọkọ si kọ re e ti iroyin yoo sọ pe Damilọla ti kuro ni aafin.
- Eyí ni àwọn arẹwà 'ẹ̀lẹ̀ Daddy', àfẹ́fẹ́ tí Aláàfin fi ń mí
- Ṣé lóòtọ́ ni olorì méjì míì tún ti kúrò láàfin Oyo?
- Wò ó bí Alaafin àti aya àkọ́fẹ́ rẹ̀, Olorì Abibat ṣe pàdé ní èwe
- Kíni 'Ẹ̀lẹ̀ daddy' Olorì Abbey Adeyemi ṣe tí ojú òpó ayélujára Instagram rẹ̀ fi ń yeruku lálá?
- Wo àwọn olorì àgbà mẹ́rin tí Aláàfin ń wárí fún
- ''Aláàfin kìí ṣe ọkùnrin tí wàá jẹ lásán, tó sì wá sálọ - Aráàlú fèsì fún Olorì Anu
- Ṣé lóòtọ́ ni Alaafin Ọyọ ti fẹ́ olorì tuntun láti ẹ̀yà Igbo? Ẹ wo ǹkan tí a mọ̀ nípa rẹ̀
- Ọlọ́run nìkan ló mọ bí ìrìnàjò ìfẹ́ ẹ̀dá á ṣe rí láyé, ọ̀dọ́ Aláàfin ní orí gbémí yà sí, ó sì tẹ́milọ́rùn- Olorì Aanu
- Wo ọ̀nà tí àwọn ‘ẹ̀lẹ̀ Daddy’ gbà dé ààfin Ọyọ
- Mo ti kúrò ní ààfin Oyo, kí ìròyìn tó ò jáde pé èmi àti Wasiu Ayinde n fẹ́ ara wa - Olori Badirat
Ẹ o ranti pe lasiko ti iroyin jade ni ọdun 2020 pe Olori Aanu kuro ni aafin, naa la gbọ pe Damilọla naa tẹlẹ. sugbọn wọn ni o sa pada si aafin.
Iroyin ti ẹ sọ lasiko naa pe aarin oru ni awọn mejeeji fi aafin silẹ.
Sugbọn ni asiko yii, a ko ti i mọ nkan to ṣe e ṣe ko le Olori Damilọla kuro ni aafin, tabi asiko to kuro, tabi ibi to lọ.
Iroyin pe Olori Damilọla ti ko jade kuro ni aafin si lo jade sori ayelujara lẹyin ọjọ diẹ ti Ọba Adeyemi kọ ilé awosifila fun meji lara awọn olori rẹ.
Awọn olori to gba ẹbun ile naa ni Ayaba Memunat ati Folashade, to pe ni Aafin Suuru, ‚Palace of Patience'.
Ṣe o wa a ṣe e ṣe ko jẹ igbesẹ ti Alaafin gbé lo mu Damilola kuro ni aafin?A ko le sọ amọ nigba to ba ya, gbogbo rẹ yoo fi oju han sita fun araye.
Sugbọn iwadii wa fihan pe, ko si aworan Ọba Adeyemi kankan mọ ni oju opo ibanidọrẹ Instagram Olori Damilola, kikida aworan oun ati ọmọ rẹ nikan si lo wa nibẹ.
Ta ba si wo ohun to ti sẹlẹ lati ẹyin wa, lasiko ti awọn olori to saaju ko kuro ni aafin, se ni wọn n yọ fọto ti wọn ya pẹlu Alaafin kuro loju opo ayelujara wọn.
Bakan naa la tun ri pe Olori Damilola ko wọ ilẹkẹ si ọrun ati ọwọ gẹgẹ bo se maa n wọ ọ tẹlẹ bii ayaba.
Olori Damilọla ni ayaba to kere ju ni aafin ìlú Ọyọ, ki iroyin tun to gbe ni oṣu diẹ sẹyin pe, Iku Baba Yeye, Alasẹ ikeji Orisa tun ti fẹ òló ẹlẹ́jẹ tutu mii lati ilẹ Igbo.
Chioma ni wọn pe orukọ ayaba tuntun naa.
Iwadii wa si fihan pe, gbogbo àwọn olori Alaafin to n lo ayelujara Instagram, ni Chioma n ba dọọrẹ papọ, to si ma n kọ ọrọ si abẹ àwọn aworan tabi fidio ti wọn ba fi sibẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ọdun to kọja ni meji lara awọn olori ni aafin Oyo, Ayaba Badirat Ajoke ati Aanu, kuro ni aafin laarin oṣu diẹ si ara wọn.
Iroyin sọ nigba naa pe, Badirat ni ajọsepọ pẹlu gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde K1, ni wọn fi le e kuro ni aafin, ti Olori Badra si sẹ lori ẹsun naa.
Ni ti Aanu, a ko mọ pato nnkan to le kuro ni aafin Iku Baba Yeye.
Bẹẹ ba gbagbe, nigba ti awọn olori mejeeji kọkọ ko kuro ni aafin Oyo, ere ni, awada ni, irọ ni, kii se ootọ, ni awọn eeyan n sọ.
Bẹẹ si ni atẹjade kankan ko si jade sita lati aafin Oyo nipa isẹlẹ naa fun awọn akọroyin, kii ootọ ọrọ to pada fidi mulẹ pe awọn Olori naa ti rin jinna si aafin Oyo lootọ.
Olori Aanu lo si fi ẹsun kan Alaafin loju opo Instagram rẹ pe oriade naa n lepa ẹ̀mí oun nitori pe oun sá kuro ni aafin, eyi to fidi ọrọ mulẹ pe o ti kọ Alaafin silẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọjọ́ Ajé gba ọ̀pọ̀ ẹ̀jẹ̀ ọmọ Nàíjíríà láti ọwọ́ àwọn agbébọn
- Agbébọn yabo ilé Sunday Igboho ní òru mọ́jú
- Iyabo Ojo àti Foluke Daramola tako ara wọn lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Ìrù ejò lẹ̀ ń fà pẹ̀lú ìkọlù lemọ́lemọ́ sílé Sunday Igboho - Àgbààgbà Yorùbá
- Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ ní Iyana Iba l‘Eko lọ́jọ́ Aje, ọlọ́pàá ní kíì ṣé ìjà ẹlẹ̀yàmẹ̀ya
- Keyamo dójú ti ara rẹ̀ àti ìjọba tó ń sìn bó ṣe kéde ìtàkurọ̀sọ rẹ̀ pẹ̀lú Eedris fáyé - Amofin
- Ọmọ Nàíjíríà kan kú lásìkò tó bẹ́ sí River Thames ní London torí ó fẹ́ dóòlá ẹ̀mí obìnrin kan
- Buhari ló ń ki àwọn agbésùnmọ̀mí láyà láti ṣe ìkọlù - Ajàfẹ́tọ̀ọ́ẹni
Igba yii si lo to ye gbogbo eeyan pe lootọ ni Olori Aanu naa ti ko kuro ni Aafin Oyo.
Nibayii, okoowo aṣọ ni olori Badirat ati Aanu n ṣe nilu Eko bayii, to si ti fidi mulẹ pe wọn ti di ayaba ana ni aafin Oyo.
Yoruba ni ti ko ba si ina, eefin ko le ru sita, bi ootọ wa ni ayaba Damilola naa ti kuro ni aafin abi irọ ni, laipẹ, laijinna, ẹri yoo jade.
























