Festus Keyamo: Amòfin ní Mínísítà kò ṣẹ̀ sí òfin bó ṣe fi nọ́mbà Eedris Abdulkareem sórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, @fkeyamo
Agbẹjọro kan, Suleiman Abaya ti sọ fún BBC pe ko lodi si òfin kì èèyàn fi ẹrọ ibaraẹnisọrọ ẹlòmíràn sita lórí ayelujara.
Abaya lo sọ ọrọ náà lásìkò tó n dá sí ede aiyede to n wáyé láàrin mínísítà abẹle fún ọrọ osiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Festus Keyamo ati gbajugbaja Olorin takasufe, Eedris Abdulkareem.
O ni "Ori kẹrin ofin orilẹ-ede Naijiria tọdun 1999 fún gbogbo ọmọ Naijiria laaye lati sọrọ laye ara wọn, ṣugbọn nipa ti ohun tó wáyé láàrin Eedris ati Keyamo, n ṣe ni Keyamo kan fi nọmba náà lede nikan ni."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Agbébọn yabo ilé Sunday Igboho ní òru mọ́jú
- Iyabo Ojo àti Foluke Daramola tako ara wọn lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Ìrù ejò lẹ̀ ń fà pẹ̀lú ìkọlù lemọ́lemọ́ sílé Sunday Igboho - Àgbààgbà Yorùbá
- Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ ní Iyana Iba l‘Eko lọ́jọ́ Aje, ọlọ́pàá ní kíì ṣé ìjà ẹlẹ̀yàmẹ̀ya
- Ọmọ Nàíjíríà kan kú lásìkò tó bẹ́ sí River Thames ní London torí ó fẹ́ dóòlá ẹ̀mí obìnrin kan
- Buhari ló ń ki àwọn agbésùnmọ̀mí láyà láti ṣe ìkọlù - Ajàfẹ́tọ̀ọ́ẹni
- Ikú Jelili kó lọ lásán, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Jonathan ọlọ́pàá tó ṣekúpa ní Quilox
- Ọjọ́ ìsinmi òni ro! Agbébọn ṣé ikọlù sílé ìjọ́sìn ní Kaduna, wọ́n jí ọ̀pọ̀ olùjọ́sìn gbé lọ
- Ẹgbẹ́ Oduduwa Republic Agitators ní ìwọ́de alágbára ń bọ̀ l‘Osun
"Ohun tó lòdì sí òfin ni ki èèyàn kéde itakurọsọ laarin ara rẹ àti ẹlòmíràn, eyi to le ṣakoba fún ẹnìkejì."
Amofin náà salaye pe, ni kete ti eeyan ba ti le se iforukọsilẹ nọmba ẹrọ alágbèéká rẹ, o ti yọnda nọmba náà sì gbagede fún arọwọto ẹnikẹ́ni ni Naijiria ati l'oke okun.
O fi kun pe ti eeyan ba ti le se eyii, èèyàn tí fi eto rẹ lè ileeṣẹ ìjọba tó n ri sí ibaraẹnisọrọ, NCC lọwọ, nítorí náà kìí se aṣiri mọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, Keyamo yóò ṣẹ sí òfin tó bá jẹ pe oun ni agbẹjọro fun Eedris Abdulkareem, to sì fi ọrọ ajọsọ wọn lede fún gbogbo araye gbọ.
Bó tilẹ jẹ pé amofin náà ni òun kó lero pe Keyamo le hú irufẹ iwa tó hù bo ṣe fi nọmba Eedris lede lórí ayélujára, ṣugbọn o ni niwọn igba to jẹ pe amofin ni òun fúnra rẹ, o mọ ohun tó ṣe nítorí kò ṣẹ sí òfin, ṣugbọn o ti dojú ti ara rẹ àti ijoba to n sin.
Lẹyin naa lo ni Eedris lẹtọ labẹ òfin lati sọ awọn ọrọ tó sọ nípa kudiẹ kudiẹ to n wáyé ni Nàìjíríà ninu awo orin Jagajaga Reloaded to gbe jáde.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni Eedris Abdulkareem gbe orin tuntun kan jade, eyii to pe "Nigeria Jagajaga Reloaded".
Ninu awo orin naa lo ti dárúkọ Festus Keyamo, to si sọ pé Keyamo ti jẹ dodo pẹlu awọn tó jẹ gaba le Naijiria lórí, kò sì lè sọ ododo mọ.
Ọrọ naa bi Keyamo ninu to bẹẹ to fi tu àṣírí ọrọ laarin oun ati Eedris, eyiti to wáyé láàrin wọn ni nnkan bíi ọdún mẹta sẹyin.
Keyamo wa fẹsun kan Eedris pe eredi to fi n sọko ọrọ sí ìjọba tó wà lóde ni pé ko rí jẹ labẹ ìjọba ọhun.
Pupọ awọn ọmọ Naijiria lo ti n fi ẹro wọn sita lórí awo orin tuntun ti Eedris ṣe, èsì tí Keyamo fún ati pàápàá bo ṣe fi nọmba rẹ lede fún gbogbo araye, to fi mọ ọrọ ajọsọ wọn.

Kí ló fa ìjà láàárín Eedris Abdulkareem àti Festus Keyamo?

Oju opo ibanidọrẹpọ lori ayelujara lo n gbona lọwọ lọwọ bayii nitori aawọ kan to n waye laarin akọrin Eedris Abdulkareem ati Festus Keyamo, minisita fọrọ igbanisisẹ.
Ọpọ eeyan si lo wa n para poro pe ki lo le fa ija laarin awọn gbajumọ mejeeji yii, to fi di ohun tawọn eeyan n gba bii ẹni gba igba ọti loju opo ayelujara.
Nigba to n salaye ohun to mu ki ọrẹ rẹ ja laarin oun ati Eedris, Keyamo lo bọ soju opo Twitter rẹ, to si tọpasẹ orisun ija ọhun si ọdun 2018.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Aráàlú gbá Rotimi Makinde lọ́rọ̀ torí ọ̀rọ̀ tó kọ nípa ẹ̀ṣùn tí wọn fi kan Baba Ijesa
- Adunni Olorisa, obìnrin òyìnbó tó di ìyàwó òrìṣà nílẹ̀ Yorùbá títí di ọjọ́ ogbó
- Kamaru Usman fi ẹ̀ṣẹ́ da orí Jorge Masvidal rú láti gba ife ẹ̀yẹ
- Ọwọ ọlọ́pàá tẹ afurasí méjì pẹlú orí òkú ní ibójì
- Ẹjọ́ ń bẹ lọ́run fún gbogbo ẹ̀yin tí kò wàásù fáwọn tó ń tẹ lé yín lórí Instagram àti Facebook- Mike Bamiloye
- Ikọlù agbébọn tó jó ilé Gómìnà ìpínlẹ̀ lọ́wọ́ òṣèlú nínú-Ìjọba Imo
- Pásítọ̀ pín ounjẹ iṣínu àwẹ̀ Ramadan fún àwọn Músùlùmí
- Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ EKSU ti ní kí wọ́n gbé ilé ẹ̀kọ́ náà tì pa!
Amọ ko si ẹni to mọ nipa ikunsinu aarin awọn mejeeji titi ti Eedris fi gbe awo orin tuntun sita laipẹ yii.
Orin ti Eedris Abdulkareem sẹsẹ gbe jade laipẹ yii naa lo ti n fa oniruuru awuyewuye, to si n fa aawọ laarin rẹ ati Festus Keyamo.
Nigba to n fesi si si awo orin tuntunt naa, Keyamo ni awo orin ti Eedris Abdulkareem kọ ló pe àkọ́lé rẹ̀ ní Jagajaga reloaded, eyi to ni o jẹ ara ọ̀nà láti ba ni lórúkọ jẹ́.
Bawo ni ija Eedris ati Keyamo se bẹrẹ lọdun 2018?
Festus Keyamo ni oun ni oludari feto ibaraẹnisọrọ fun ipolongo ibo Muhammadu Buhari lọdun 2018.
O ni Eedris fí àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ sí òun lọdun 2018 pé òun fẹ́ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ètò ìpolóngo ààrẹ Buhari, ati pe, òun tì kọ orin fun ipolongo naa, o si ṣe pàtàkì láti rí òun.
Sùgbọ́n, lẹ́yìn o rẹ̀yìn, Keyamo ni Eedris sọ pé òun nílò láti yá owó fún sísan owó tó tó mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún náírà.
O ni Eedris ni owo naa lo wa lati san owo tí òun ń jẹ ilé ìtura kan àti láti san owó ilé ìwòsàn ìyá rẹ̀ tó ṣàìsàn, tí owó náà sì ti lé ni mílíọ̀nù mẹ́tà nàìra.

Oríṣun àwòrán, Festus Keyamo SAN/Twitter
Ẹ̀wẹ̀, Keyamo ni lẹ́yìn àsìkò yìí ni olóṣèlú kan pè òun pé ọ̀tọ̀ ni ìtàn tí Eedris Abdulkareem sọ fún òun, o ni ọmọ rẹ ló sọ pe o n ṣe àìsàn, lo wi fun oun.
Keyamo ni Eedris tún bẹ̀ òun láti fi òun mọ mínísítà feto ìdájọ àti agbẹ́jọrò àgbà ní Nàìjíríà, Abubakar Malami.
Bakan naa lo tun n bẹbẹ lati mọ mínísítà ètò ìrìnà ,Rotimi Amaechi àti àkọwé àgbà fún ìjọba Nàìjíríà, Boss Mustapha, to si ni oun fẹ polongo orúkọ wọn.
Keyamo ni Eedris tún ṣèlérí pé, gbogbo àra ni òun fi wà lẹ́yìn ipolongo ìjọba, sùgbọ́n Keyamo ni nígbà tó yá, ó yé òun pé owó lásàn ni Eedris nílò, ó sì lé ba òun lójú jẹ́ tó bá yá, nítorí náà, òun kò bá ṣe pọ mọ.

Oríṣun àwòrán, Festus Keyamo/Twitter
Keyamo ni lẹ́yìn àsìkò yìí, tí Eedris ti wá ri pé òun kò rí ẹnikẹ́ni sun mọ tabi ri ibikibi wọ̀ nínú ìjọba Buhari láti rí owó, ló ba lọ sí igun tí Atiku pé òun wà lẹ́yìn rẹ̀.
O ni idi ree ti Eedris fi bẹ̀rẹ̀ sí ni pe Buhari ni gbájúẹ, sùgbọ́n tawọn mójú kúrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, tawọn si ri iwa rẹ gẹ́gẹ́ bi ẹni tó n gba ẹnu ẹgbẹ́ alátakò sọ̀rọ̀.
Keyamo ni "Lọpọ igba lo maa n darukọ mi amọ igbesẹ ọtun to tun gbe lasiko yii ni awo orin to se sita, eyi to pe ni Jagajaga Reloaded.
Orin yii si ni Eedris n lo lati safihan ijakulẹ rẹ pe ko ri aarin ololufẹ Buhari wọ. "
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ọpọ ọrọ ibajẹ ti Eedris sọ nipa Buhari
Sáájú ni Eedris Abdulkareem ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí "Mr Lecturer" ti pé ààrẹ Muhammadu Buhari ni "Gbájúẹ tó láṣeyọrí"
Lójú òpó instagram rẹ̀ ló gbé tó sì kọ̀ báyìí pé "most successful fraudster in the history of Nigeria".
Ní ọdún 2018 ni Eedris ti kọ́kọ́ ni "Buhari jẹ́ gbájúgbaja nínú ìwà gbájúẹ̀ ní gbogbo àwọn ipò tí ó ti dì mú ni Nàìjiríà."

Oríṣun àwòrán, Eedris
Bó ṣe sọ lójú òpó twitter rẹ̀, Eedris ni " Buhari kọ́kọ́ fi ìwà jìbìtì wọ iṣẹ́ ológun, ó gba ìgbéga tí kò tọ́ sí i lásìkò tó wà nínú iṣẹ́ ológun."
"O bá ètò ìjọba awa arawa jẹ́, tó sì sọ Nàìjíríà dí òtòsì àti aláìlólùrànlọ́wọ́"




















