Suspected Ritualist: Ki láwọn gende méjì n ṣé ní ibojì òkú pẹlú orí gbígbẹ ní Kaduna

Oríṣun àwòrán, Daily Trust
Ọwọ palaba awọn alaburu meji kan ti segi ni Kaduna lẹyin ti awọn ọlọpaa ka wọn mọ plu ori oku .
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa ASP Muhammad Jalige lo fi ọrọ yi to awọn akọroyin leti ninu atẹjade kan gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Daily Trust ti ṣe sọ.
Jalige sọ pe lọjọ Kẹtalelogun ni awn gba ipe ẹgba wa kan lati ọdọ ọga agọ ọlọpaa to wa ni Kakuri.
- Ajọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Benue wú òkú èèyàn mẹ́wàá jáde ní ibojì àwọn ajínigbé
- Ọ̀rọ̀ yìí gbẹnután!,Ìyá dú ọmọ rẹ̀,o yí láta,ó wá jòkó jẹ ẹ́
- Ọlọ́jọ́ padà dé! Arákùnrin tó 'jíǹde' ní mọ́ṣúárì tí kú
- "A ti ń sin òkú méjì sínú ibójì kan náà nítorí ọ̀wọ́ngógó ibojì ìsìnkú"
- Àwọn afurasí tí wọ́n ká orí èèyàn mọ́ lọ́wọ́ ní ìlú Akure fojú balé ẹjọ́
DPO agọ ọlọpaa naa sọ pe niṣe lawọn kan fi to awọn leti ni nkan bi ago mọkanla alẹ pe pe awọn olubi kan wa nibi iboji oku Musulumi to wa ni Kudenden.
Nigba ta wọn ọlọpaa yoo fi de ibẹ, wọn ka awọn ọkunrin meji kan mọ pẹlu ọkọ ati ori oku.
Awọn mejeeji jijọ n gbe ni adirẹsi Zaki Close, Kabala West, Kaduna.
Jalige sọ pe awọn ṣi n tẹsiwaju pẹlu iwadii lati mọ pato nkan ti wọn n ṣe nibẹ pẹlu ori oku.
O wa rọ araalu lati tete fio to awọn ọlọpaa leti bi wọn ba kẹfin ẹnikankan to n hu iwa aida












