Kìí ṣéé àwàdà, Ẹ wó arákùnrin Kenya tó 'jíǹde' ní mọ́ṣúárì tó padà wá kú

Oríṣun àwòrán, CitizenTV
Lẹyin ọsẹ kan ti iroyin gbode kan pe Peter Kigen jinde ni mọṣuari, arakunrin kan ni Kenya ti pada wa ku.
Gẹgẹ bi ohun ta ri ka lawọn iwe iroyin ilẹ naa, wọn ni lọsẹ to kọja lawọn to n tọju oku ṣaadede rii to taji lasiko ti wọn n palẹmọ oku rẹ.
Wọn ni niṣe lo bẹrẹ si ni pariwo ki o to wa pada tun daku nigba naa.
- Àrà kengé! Ọmọ China to ẹgbá sí ìdí ọmọ'ṣẹ́ rẹ tó pẹ́ ẹ́ dé ibi'ṣẹ́
- 'Mo mọ̀ọ́mọ̀ sin ọmọ-ọmọ mi, ìkókó jòjòló láàyè ni, nítorí wọ́n fipá bá ọmọbìnrin mi lòpọ̀ ló fi lóyún rẹ̀'!
- Ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀: Orí Twitter ló ti bẹ̀rẹ̀, ikú ló já sí
- 'Òkú bí àádọ́ta ni iná jó gúrú-gúrú ní mọ́ṣúárì l'Anambra'
- Kàyéèfì! Òkú 'jinde' ní mọ́ṣúárì!
- Ẹ̀rọ CCTV tú àsírí ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún tó fi ipá bá ọmọ ọdún mọ́kànlá lòpọ̀
Arun to lagbara gan an n daamu Peter Kigen, ẹni ọdun mejilelọgbọn ti o si n gba itọju ni ile iwosan ki wọn to ni ko maa lọ sile.
Lọsẹ to kọja, o sọ fun ileeṣẹ iwe iroyin Daily Nation pe inu oun dun lati tun maa jẹ ero aye pada.
O sọ fun ileeṣẹ iwe iroyin naa pe ''Iṣẹ Ọlọrun ni''
Iroyin 'ajinde' rẹ yi mu kawọn eeyan maa ṣe eemọ loju opo ayelujara ni Kenya.

Oríṣun àwòrán, Kapkatet Hospital
Koda awọn aṣoju ile aṣofin Kericho County jiroro lori ọrọ yi.
Wọn tori rẹ ṣagbekalẹ igbimọ iwadii lati le tọ pinpin iṣẹlẹ yi.
Abajade kan sọ pe awọn oṣiṣẹ ilera ko ṣaṣemaṣe kankan ninu ọrọ yi.
- Ṣé ẹ rántí àkọ́lé àwọn ìwé àkàgbádùn yìí?
- Àwọn Olúkọ ìpínlẹ̀ Oyo fakọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà púpọ̀
- Ọkùnrin kan "lu ìyàwó rẹ̀ pa" nítorí ó lọ síbi ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ
- Tí a bá yọwọ́ àwọn ọba alayé kúrò, kò ní sí Nàìjíríà mọ́- Alaafin Oyo
- Makinde, Dele Momodu ń ṣèdárò Àgbà Oyè Ilẹ̀ Ibadan, Harry Akande tó jáde láyé
Lọjọbọ lagbẹnusọ mọlẹbi rẹ kan sọ fun ileeṣẹ iwe iroyin Standard newspaper pe: ''Nigba ti a gbe Kigen de ile iwosan Kericho County Hospital lati Kapkatet, wọn sọ fun wa pe o ti dakẹ''
Ọgbẹni Hezbon Tonui ni awọn gbe e lọ sibẹ lati gba itọju to peye si i ni ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.

















