Ọkùnrin kan "lu ìyàwó rẹ̀ pa" ní ìpínlẹ̀ Ogun nítorí ó lọ síbi ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ

ọkọ to n lu aya rẹ

Oríṣun àwòrán, others

Ọkùnrin kan "lu ìyàwó rẹ̀ pa" nítorí ó lọ síbi ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ

Awọn ẹbi Nike Opeifa ti fẹsun kan ọkọ rẹ Abayomi pe o lu obinrin naa pa lagbegbe Sango, ni ipinlẹ Ogun to wa ni iwọ oorun guusu Naijiria.

Iroyin ni wahala ṣẹyọ lọjọ Isinmi nigba ti Abayomi kọ jale pe Nike ko ni lọ sibi isọmọloruko ẹgbọn rẹ kan, eyii to yẹ ko waye ni agbegbe Ibafo, ni ipinlẹ kan naa.

Wọn ni Abayomi gba ki iyawo rẹ lọ ibi ayẹyẹ isọmọlorukọ naa ni igbẹyingbẹyin, ṣugbọn o kọ jale pe ko ni wọ inu ile oun nigba to pada de laarọ ọjọ keji.

Àkọlé fídíò, Ọkùnrin tó fẹ́ fipábámilòpọ̀ fín ǹkan sí mi lójú ló ṣe rọ́nà wọlé sí mi lára

Ọkan lara awọn mọlẹbi obinrin naa sọ fun awọn akọroyin pe ọkọ rẹ, Abayomi lu Nikẹ ni ilu bara loru mọju, eyii to fa ṣababi iku rẹ.

Mọlẹbi rẹ ọhun tun fi kun un pe Abayomi gbe oku iyawo rẹ naa lọ sile igbokusi ko ti fi iṣẹlẹ ọhun to ẹbi re leti.

O ni "Ijẹta ni ẹgbọn mi sọ fun mi pe oun fẹ lọ sibi ayẹyẹ isọmọlorukọ ẹgbọn rẹ agba ni Ibafo, ṣugbọn iya Abayomi ni ko má gba ki oloogbe naa lọ."

"Lẹyin to pada de ṣugbọn ti Abayomi kọ lati jẹ ko wọ inu ile ni iya rẹ da si ọrọ naa… aarọ ọjọ keji ni agbọ pe Nike ti jade laye.

Àkọlé fídíò, Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi

Ọkunrin naa tẹsiwaju pe "nigba ti a bi Abayomi lere bi Nike ṣe di alaisi, o ni ṣe lo gbe majele jẹ.

O ni "eyii jẹ iyalẹnu nla fun gbogbo ẹbi wa nitori ko gbe majele jẹ lati nnkan bi ọdun mẹta ti wọn ti n ni wahala ninu igbeyawo wọn."

"O gbe oku rẹ lọ ile igbokusi ko to fi to wa leti, bẹẹ lo tun lọ si agọ ọlọpaa pe iyawo oun ti gbẹmi ara rẹ, eyii ti ko ṣeeṣe."

Àkọlé fídíò, 'Bí aya bá kọ ọkọ rẹ̀ silẹ̀, kó wà láì lọ́kọ̀'

Nigba ti awọn akọroyin kan si ileeṣẹ ọlọpaa, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ni lootọ ni ọkunrin kan fi to ileeṣẹ naa leti pe iyawo oun gbe majele jẹ.

Ṣugbọn o fi kun un pe "awọn ẹbi obinrin naa ti sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ, ti wọn si fẹsun kan ọkunrin ọhun pe oun gangan lo ṣekupa iyawo rẹ.

Oyeyemi ni ọkunrin naa ti wa ni ahamọ bayii, iwadii si ti bẹrẹ lati mọ okodoro bi ọrọ naa ṣe jẹ.