Diego Maradona: Báyìí ni àgbàọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù Diego Maradona ṣe wọ káà ilẹ̀ lọ lólú ìlú Argentina

Awọn oludaro n wo posi Maradona

Oríṣun àwòrán, Casa Rosada

Ba a ku laa dere eeyan o sunwọn laaye. Agbaọjẹ agbabọọlu Argentina yẹlẹ ri, Diego Maradona ti wọ kaa ilẹ lọlẹyin to papoda lẹni ọgọta ọdun.

Olu ilu orilẹede Argentina, Buenos Aires ni wọn sin Maradona si nibi ti ọpọ ti pejọ lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun elege ara to filẹ ṣaṣọ bora.

Awọn ẹbi ti ko ju mẹrinlelogun lọ pẹlu awọn ọrẹ rẹ lo wa nibi ayẹyẹ isinku Maradona l'Ọjọbọ.

Amọ, ọgọọrọ eeyan lo lanfaani lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un, ọpọ lo n sunkun, nigba ti awọn mii n ṣe sadakanta lẹgbẹ posi Maradona.

Iku Maradona ti mu ki gbogbo eeyan lagbaaye papaa julọ awọn ololufẹ ere bọọlu ṣe idaro ẹni 're to lọ papaa julọ nilẹ abinibi rẹ, Argentina.

Koda asia orilẹede Argentina ati jẹsi rẹ pẹlu nọmba ''10'' ti o maa n wọ wa lori posi Maradona fun awọn eeyan lati ri lolu ileeṣẹ ijọba ilẹ naa.

People gather to mourn the death of soccer legend Diego Maradona, outside the Diego Armando Maradona stadium, in Buenos Aires

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Maradona was regarded as a national hero in Argentina

Awọn agbofinro tiẹ ni ikọlu pẹlu awọn oludaro to n gbiyanju lati suu mọ olu ileeṣẹ ijọba nibi ti wọn gbe posi Maradona si.

Iroyin kan tiẹ tun sọ pe awọn ọlọpaa yin tajutaju lati dari awọn ero nibi eto isinku naa.

Ọkọ igboku si lo gbe posi Maradona lo si ilẹ isinku si Bella Vista ni bi ti o ti sun.

Ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn Diego Maradona ìlúmọọká agbábọ́ọ̀lù rèé kó tó dágbére f'áyé

Ohun mẹta ti ẹda kan ko mọ laye ti a wa yii ni pe ko si ẹni to mọ iru iku ti yoo pa a.

Ekeji ni pe ko si ẹni to mọ igba ati akoko ti ọlọjọ yoo de ati pe ko si ẹda ẹni to mọ ibi ti o maa ku sii.

Awọn ọmọ orilẹede Argentina ati gbogbo agbaye si n ṣe idaro gbajugbaja agbabọọlu elege ara, Diego Maradona ti filẹ ṣaṣọ bora lẹni ọgọta ọdun l'Ọjọru.

Amọ kinni ọrọ ti ogbontarigi agbabọọlu naa sọ kẹyin ki o to jẹ Eleduwa ni pe.

Diego Maradona koju Nigeria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ lati orilẹede Argentina, Maradona sọ fun ọmọkunrin to wa pẹlu rẹ ni ede ilu rẹ pe ''Me siento mal,'' eyi to tumọ si ''o n rẹ mi.''

Ara Maradona ko le daadaa nigba to lọ jẹ ounjẹ aarọ Ọjọru, o ṣaroye pe otutu n mu oun.

Diego Maradona koju Nigeria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin naa lo sọ fun ẹbi rẹ kan pe o n rẹ oun ki o to pada sori ibusun rẹ ki ẹlẹmi to gba a.

Ayẹwo oku fihan pe arun ikọlu ọkan to ṣekupa Maradona lẹyin ọsẹ meji to ṣe iṣẹ abẹ ọpọlọ lati ko ẹjọ to da sii lọpọlọ kuro.

Ẹwẹ, aarẹ orilẹede Argentina, Alberto Fernandez ti kede ọjọ mẹta lati kẹdun Maradona.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Diego Maradona ìlúmọọká agbábọ́ọ̀lù dágbére f'áyé

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe gbajugbaja agbabọọlu ni ọmọ Argentina Diego Maradona ti dagbere faye.

Ikede yi ta ri ka loju opo awọn ileesẹ iroyin sọ pe o faye silẹ laipẹ ọjọ ti o ṣe isẹ abẹ ọpọlọ.

Diego Maradona

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹni ọgọta aọdun ni Maradona ko to fi aye silẹ.

Maradona je okan lara agbabọọlu to lamilaka julọ lagbaye.

O tun jẹ agbabọọlu ọmọ Argentina tó gbà ife ẹyẹ agbaye gẹgẹ bi Balogun ikọ ọmọ agbabọọlu Argentina.

Ọpọ ni yoo maa ṣe iranti Maradona fun goolu rẹ to fọwọ jẹ ninu idije agbaye eyi ti Argentina fi gbewuro soju ilẹ Gẹẹsi ni Mexico 86.

Diego Maradona

Oríṣun àwòrán, AFP

Tolori tẹlẹmu ni ko ni gbagbe ilumọọka agbabọọlu elege ara yi to ṣe pe o ko ipa ribi ribi ninu ere bọọlu lagbaye.

Nigba aye rẹ, o gba bọọlu fún ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona àti Napoli ó si gba ife ẹyẹ pelu lẹẹmeji ni Serie A.