Lionel Messi: Ronaldinho ní Messi kọ́ ni agbábọ́ọ̀lù tó dára jùlọ lágbàáyé

Ronaldinho ati Messi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Ronaldinho

Ọrọ yii dabi ẹni pe ko ni tan nilẹ bọrọ. Ọpọ lo ti n sọ pe aramọnda agbabọọlu Barcelona ati Argentina, Lionel Messi ni agbabọọlu to dara julọ ninu itan.

Bakan naa, ọpọ ni wọn ko gba pe Messi ni agbabọọlu to dantọ julọ lagbaaye.

Agbabọọlu Brazil tẹlẹ ri orilẹede Brazil to jẹ akẹgbẹ Messi ni ikọ Barcelona, Ronaldinho wa lara awọn to gbagbọ pe Messi kọ ni agbabọọlu to dantọ julọ ninu ere bọọlu.

Laipẹ yii ni Messi gbami ẹyẹ Ballon D'or nilẹ Faranse fun igba kẹfa, amọ Ronaldinho t'oun naa gbami ẹyẹ Ballon d'or lọdun 2005 sọ pe oun ko le pe Messi ni agbabọọlu to dara julọ lagbaaye ninu itan.

Ronaldinho ni idunnu lo jẹ fun oun pe Messi gbami ẹyẹ Ballon fun igba kẹfa loṣu yii amọ agbabọọlu bi Pele, Maradona, ati Ronaldo ko le jẹ ki sọ wi pe Messi lo dara julọ ninu itan.

"Ohun ti mo le sọ ni pe Messi lo dantọ julọ laarin gbogbo awọn agbabọọlu to wa lasiki tirẹ,'' Ronaldinho lo woye bayii.

Cristiano Ronaldo lo ṣi keji lẹyin ti oun naa ti gba ami ẹyẹ Ballon d'or fun igba marun un.