Bàbá ìyàwó ní ìfẹ́ wà láàrin ọmọ́ òun àti ọkọ rẹ̀, inú àwọn sì dùn sí ìgbeyàwó náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan, Fatima Abubakar ti padanu ẹmi rẹ lẹyin to re sinu kanga omi nigba ti igbeyawo rẹ ku ọla.
Iṣẹlẹ naa la gbọ wi pe o waye ni ilu Gajaja, ijọba ibilẹ Danbatta, nipinlẹ Kano.
Baba Fatima, Ọgbẹni Abubakar sọ fun BBC pe, iṣẹlẹ buruku naa waye lasiko ti ọmọbinrin naa ati awọn ọrẹ rẹ nlọ fun ayẹyẹ alẹ omidan nile anti rẹ kan l'ọjọru.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- 'Penis Fish", ẹ̀ja tuntun tó rí bí ǹkan ọmọkùnrin lùwẹ̀ jáde lórí òkun
- Kò sí ọkùnrin tí yóò fún obìnrin tó halẹ̀ bíi tèmi lówó - Lizzy Anjorin
- Gómìnà Kwara kéde àgùnbánirọ̀ àtàwọn míì gẹ́gẹ́ bí kọmíṣọ́nnà tuntun
- Táyà ọkọ̀ agbépo tó fọ́ fa ìjàmbá ọ̀kọ̀ l'Ékò, èèyàn kan farapa
- Boris Johnson àti ẹgbẹ́ rẹ̀ wọlé ìbò, Trump àtàwọn ààrẹ míì kíi kú oríire
"Niṣe lo duro l'ẹgbẹ kanga naa, ko to o di wi pe o fi ẹsẹ kọ, to si ṣubu sinu kanga.
Ọjọ keji, to jẹ Ọjọbọ lo yẹ ki ayẹyẹ igbeyawo laarin oun ati ọkọ afẹsọna rẹ o waye.
Baba Fatima ṣalaye pe, inu ọmọ oun dun si igbeyawo naa, ati pe ifẹ wa laarin oun ati ọkọ afẹsọna rẹ.
O sọ pe amọ o ṣeni laanu pe inu ibanujẹ ni awọn alejo to yẹ ko wa ba oun yọ ayọ igbeyawo ọmọ oun wa bayii.
Inu ibanujẹ ni ọkọ afẹsọna naa wa, ti ko si le ba ẹnikẹni sọrọ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ.












