Sowore: Mínísítà fétò ìdájọ́ gba ìwé ẹjọ́ Sowore kúrò lọ́wọ́ àjọ DSS

Sowore ni ile ẹjọ

Lẹyin gbogbo awuyewuye to waye lori bi ileeṣẹ DSS ṣe ya bo ile ẹjọ lati mu Soworẹ laipẹ yii, agbẹjọro agba lorilẹede Naijiria, Abubakar Malami, SAN ti gba ẹjọ naa lọwọ ajọ ọhun.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Umar Gwandu fi sita lọjọ Ẹti, akọwe agba nileeṣẹ eto idajọ nijọba apapọ, Ọgbẹni Dayọ Apata, SAN kọwọ si ọga agba ileeṣẹ DSS pe ko tete "ko awọn iwe ẹjọ naa ṣọwọ si ọfiisi agbẹjọro agba ni kiakia."

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Yorùbá foríkorí gbé ìwé tó lè sọ ẹ̀yà ara yín lédè Yorùbá.

O ni minisita feto idajọ ti paṣẹ pe ki ileeṣẹ eto idajọ o gba akoso ẹjọ naa ni ibamu pẹlu abala aadọjọ ati ikẹrinlelaadọsan iwe ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999.

Atẹjade naa tun ṣalaye wi pe ki igbẹjọ lee ya ni igbesẹ ati gba a kuro lọwọ ajọ DSS ṣe waye.

Àkọlé fídíò, Naira Marley: Adọ́jọ́ ṣún ìgbẹ́jọ́ síwájú di oṣù kejì ọdún 20202

Bi ẹ ko ba gbagbe, ni Ọjọru ni minisita feto idajọ, Abubakar Malami ṣalaye fawọn oniroyin pe ijọba apapọ yoo ṣewadi bi awọn oṣiṣẹ DSS ṣe ya wọ kootu kan ni ilu Abuja lati fi tipatipa mu Soworẹ pada si ahamọ.