Aisha Buhari tutọ sókè fojú gbà à, ó ní kí Garba Sheu kọ́we fipolẹ́

Aworan Aisha Buhari ati Garba Sheu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aisha Buhari tutọ sókè fojú gbà à, ó ní kí Garba Sheu kọ́we fipolẹ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Orukọ iyawo aarẹ orile-ede Naijiria, Aisha Buhari lawọn eeyan n lọgun tantan loju opo Twitter lataari ọrọ to sọ pe ki agbẹnusọ aarẹ Buhari Garba Sheu kọwe fipo silẹ.

Ninu ọrọ ti Aisha Buhari sọ ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ, o ni Garba Sheu ti gba abọde ti o si tọ ki o kọwe fiposilẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Aisha Buhari sọ pe nkan ti wọn ni ki ẹlẹmọṣọ Garba Sheu sọ kọ ni o gbaju mọ ti o si yapa adehun to ṣe lati ba aarẹ Naijiria ṣiṣẹ tọkantọkan.

Yatọ si ẹsun yi, Aisha Buhari tun fi awọn ẹsun miran kan Garba Sheu ṣugbọn koko nkan to jẹ yọ ni pe Garba Sheu nikan kọ ni Aisha n sọko ọrọ ba.

Ninu atẹjade naa o sọ pe:

  • Garba Sheu n lẹdi apo pọ pẹlu awọn kan lati maa toju bọ ohun to n ṣẹlẹ ninu mọlẹbi aarẹ Naijiria
  • Garba Sheu kan naa n lodi si idasilẹ ọọfisi iyawo aarẹ (Office of the First Lady) ti o si sọ pe ijọba Buhari ni o lodi si idasilẹ ọọfisi yi
Àkọlé fídíò, Akure Kidnap: Àwọn abiyamọ fẹ̀hónúhàn lórí ọmọ tí wan jígbé nílé ìjọsìn Akurẹ
  • O ni Garba Sheu wa lara awọn to gbimọran ọtẹ lati tan ara ilu pe awọn ti oun mọ ita nigba ti oun dari irinajo pada si Naijiria
  • Bẹẹ ni Aisha Buhari sọ pe Garba Sheu kanra mọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ amohunmaworan Naijiria ti wọn n ṣiṣẹ pẹlu ọọfisi iyawo aarẹ ti o si mura pe dandan ni ki wọn gbaṣẹ lọwọ wọn.
  • Bakan naa ni Aisha sọ pe Garba Sheu n mu idojuti ba mọlẹbi aarẹ ati ileeṣẹ aarẹ Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ileeṣẹ iroyin BBC Hausa gbiyanju lati ba Garba Sheu sọrọ lori nkan ti iyawo aarẹ sọ ṣugbọn ko gbe ipe rẹ.

Ni kete ti a ba ti ri esi tirẹ gba lori ọrọ yi la o fi to yin leti.

Lẹnu lọọlọ yi, ǹkan ko ṣẹnu re laarin iyawo Aarẹ Naijiria atiwọn kan to n naka si pe wọn ko jẹ ki aarẹ ṣe ijọba fun ra rẹ.