Kìnìhún fa èèyàn kan ya ní Nairobi, àdúgbò dàrú

kinihun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kìnìhún fa èèyàn kan ya ní Nairobi, àdúgbò dàrú

Lati inu ọgba ẹranko ni guusu Nairobi to jẹ olu ilu orilẹ-ede Kenya ni Kinihun naa ti jade sita.

Bo ṣe jade naa ni ọkunrin kan to n lọ si igboro ni guusu Nairobi ṣe kongẹ rẹ to si fa a ya pẹrẹpẹrẹ.

Ko pẹ ti wọn doola ẹmi arakunrin yi ti wọn gbe e de ile iwosan tan lo jẹ Ọlọrun nipe.

Arakunrin naa ku lataari awọn ipalara to ri lẹyin to jabọ lẹnu kinhun na.

Ijọba Kenya ni iru iṣẹlẹ bayii ko wọpọ pe ki ẹranko sa jade lati inu ọgba ti wọn fi si wa maa ṣe ara ilu leṣe ni igboro.

Ijọba nipe o san kawọn eniyan gbe ile wọn dipo ki wọn maa sa kiri pẹlu ibẹrubojo lọ lasiko yii.

Àkọlé fídíò, Ó di dandan kí ará India yìí sọ ìdí tó fi ń sìn kìnìhún- Egbeyemi

Ṣugbọn awọn akọṣẹmọṣẹ ni ọpọ igba ti ẹranko ba sa kuro ni ibugbe rẹ bayii le jẹ nitori pe nkan kan bii ninu.

Tabi pe wọn paarọ tabi mu ayipada ba nkankan ni agbegbe ẹranko naa ni. bii ki wọn yaa sọtọ tabi ki wọn gbe awọn ẹranko mii kuro lẹgbẹẹ rẹ.

Wọn ti kilọ fawọn ara ilu lati ṣọra bi wọn ṣe n rin nigboro.

Ati pe to ba ṣẹeṣe ni ẹkun guusu yii ki awọn eniyan duro sile wọn titi ijọba a fi ri kinihun naa.

Àkọlé fídíò, Akure Kidnap: Àwọn abiyamọ fẹ̀hónúhàn lórí ọmọ tí wan jígbé nílé ìjọsìn Akurẹ