Taiwo Hassan: Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sá fún mi nígbà tí mo dùbúlẹ̀ àìsàn

Oríṣun àwòrán, Instagram/AlhajiTaiwo
Gbajugbaja oṣere sinima agbelewo, Taiwo Hassan ti ọpọ eeyan mọ si Ogogo to ṣọrọ lori aarẹ to ṣe fun odindin ọdun mẹjọ lati ọdun 2004 titi di 2012.
Nigba ti o n ṣe aisan naa, oriṣiriṣi iroyin ofege lo gbalukan nipa nnkan to n ṣe oṣere naa.
Nigba ti awọn kan n sọ pe o ni arun HIV ni awon kan ni egbo igi oloro lo tu sii ninu.
Ṣugbọn agba ọjẹ oṣere naa ti ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ sii nigba naa fun araye.
Ogogo ni ninu awẹ Ramadan ọdun 2004 ni oun mọ pe oun ni arun ọgbẹẹnu ti wọn pe ni Ulcer.
O ni oun lo to oṣu meje ti oun n ki irun lori ijokoo nitori pe oun ko to ẹru Ọlọrun to n dide duro lati gbe irun duro.
Ogogo ni oun lati pa ẹrọ ibanisọrọ ti oun n lo nigba ti iroyin n kaakiri pe oun gbe egboogi oloro ni abi pe oun ko arun HIV ni.
Tonti pe ẹlẹsin Muslumi, Kristẹni ati iṣẹṣe n gbadura fun un, awọn orẹ ati iyawo rẹ pada fi i silẹ lọ nigba ti iṣoro naa pọ.
Ogogo ni oun pada fẹ obinrin to duro ti oun nigba iṣoro naa, obinrin naa si ti bimọ meji fun oun bayii.
Ṣe obinrin kuku kọkọ bimọ fun ni ko sọ pe ko duro ti ni nigba ti iṣoro ba de.
Taiwo Hassan gba awọn to ba n la iṣoro kan kọja lasiko yii lati tubọ sunmọ Ọlọrun ki wọn kun fun adura.
O ni ko si iṣoro to ni ibẹrẹ ti ko ni lopin ti eeyan ba ni suuru to dẹ n gabdura.















