Ex-governors’ pension: ilé aṣòfin Èkó láwọn kò ní ṣé bí tàwọn aṣòfin Zamfara

ile iwe

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Oriṣii ọna ti ijọba fi n lo owo ori awọn eniyan

Kuforiji: Kò sí ohun tó burú nínú kí Gómìnà máa gbowó gọbọi lẹ́yìn ìfẹ̀yìntì

Olori ile aṣofin ipinlẹ Eko nigbakan ri, Adeyemi Kuforiji ti gbaruku ti awọn aṣofin lori ofin owo ati dukia ifẹyinti fawọn to ti jẹ Gomina ati igbakeji ri nipinlẹ naa.

Kuforiji sọ ọrọ yi di mimọ lasiko to n kopa lori eto kan lori ẹrọ amohunmaworan Naijiria TVC ni ipinlẹ Eko.

O ṣalaye pe ti awọn to wa lori ipo ba ṣe nkan bo ti ṣe yẹ, ara ilu ko ni maa lọgun nipa owo ifẹyinti gọbọi tawọn Gomina n gba.

Kuforiji ni: ''Ti gbogbo eeyan ba ṣiṣẹ bi Jakande ti ṣe ṣiṣẹ, bi Tinubu ṣe ṣiṣẹ nipinlẹ Eko,ko si ẹni ti yoo ma pariwo lori owo ifẹyinti tawọn Gomina n gba''

Kuforiji ni ti a ba wo wahala tawọn to di ipo mu yii ṣe lati fi sin ilu, o yẹ ki ara ilu fi imoore han pẹlu owo ifẹyinti to jọju.

Lẹnu ọjọ mẹta yi, ariwo ti gbode kan pe ki awọn aṣofin ipinlẹ to ku naa tẹle igbesẹ ile aṣofin Zamfara to wọgile owo ifẹyinti gọbọi fawọn to ba ti jẹ Gomina ri.

Ipinlẹ naa ni yatọ si eleyi ti ofin la kalẹ fawọn to ba wa nipo, awọn ko ni le fi ofin kalẹ ni ijọba ipinlẹ lati tun ya owo ati dukia sọtọ fawọn Gomina ati igbakeji wọn ti wọn ti kuro nipo.

Aworan olori ile asofin ana nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, Facebook/Hon Adeyemi Ikuforiji

Àkọlé àwòrán, Ilé aṣòfin Èkó láwọn kò ní ṣé bí tàwọn aṣòfin Zamfara

Owo ọna meji la tako

Adeyemi Kuforiji: Nígbà tá gbé òfin owó ìfẹ̀yìntì kalẹ, iṣẹ nlá là ṣé

Ariwo fífopin sowo ifẹyinti awọn oloṣelu lataari igbesẹ ile aṣofin Zamfara to wọgile owo ifẹyinti gọbọi ló gbode kan.

Ajọ SERAP to jẹ ajọ aladani to n ja fun iṣedeede lawujọ ni Naijiria lo n lewaju ninu ipe ki wọn wọgile owo tabua fawọn Gomina to ti kuro nipo.

Adetokunbo Mumeen to jẹ adari ajọ naa kopa ninu eto ori ẹrọ amohunmaworan ti a n sọ yi to si ni owo gbigba lọna meji lawọn tako.

Aworan ile aṣofin ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, ilé aṣòfin Èkó láwọn kò ní ṣé bí tàwọn aṣòfin Zamfara

Bi a ko ba gbagbe, ile ẹjọ giga kan nilu Eko gbe idajọ kalẹ pe ki agbẹjọro agba Naijiria gba gbogbo owo ifẹyinti ọna meji tawọn Gomina to di ipo miran mi mu nijọba gba lọwọ wọn.

Ipinlẹ Eko wa lara awọn ipinlẹ to fariga pe awọn ko ni yi ofin yi pada nitori ko tako ilana ofin owo ifẹyinti fawọn to di ipo Gomina mu tẹlẹ ri.

Àkọlé fídíò, Bi ìyàwọ mi ṣe n jábọ́ sí kọ́tà ló jẹ́ kí n kọ́ka fura pé kò ríran mọ́- ọkọ Dorcas

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ọjọ Aiku, alaga igbimọ lori ọrọ ibanisọrọ ile aṣofin Eko, Tunde Braimoh ni ''lopin igba ti ofin tawọn ile ba gbe kalẹ ko ba tako ofin Naijria, wọn lẹtọ lati ṣe ofin ti yoo ṣaanfaani fara ilu''

Atupalẹ owo ifẹyinti ati Dukia fawọn Gomina nipinlẹ Eko

Ofin ti ipinlẹ Eko ti wọn fi lọlẹ lọdun 2007 laa kalẹ pe, awọn Gomina tabi igbakeji wọn ti wọn ko ba yọ nipo laanfani lati gba deede owo oṣu wọn gẹgẹ bi owo ifẹhinti eyi to jẹ opọlọpọ miliọnu naira lọdun.

Wọn a tun fun wọn ni ile meji, ọkan ni ilu Eko ati omiran nilu Abuja, bi Gomina naa ba ṣe saa kan, ile kan ṣoṣo ni wọn yoo fun wọn.

aworan ọkọ ayọkẹlẹ

Oríṣun àwòrán, Google

Yatọ si awọn ohun ti a ka kalẹ yii, wọn tun n gba ọkọ ayọkẹlẹ mẹfa pẹlu awọn ajẹmọnu miran pẹlu oṣiṣẹ ti yoo ma ba wọn ṣiṣẹ.

Ilera ọfẹ, owo ina ati omi ati awọ ajemọnu bii titun ọkọ ṣe, gbigba alejo ati bẹẹ bẹẹ lọ lo wa nibẹ.

Aworan ile

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Ilera ọfẹ, owo ina ati omi ati awọ ajemọnu bii titun ọkọ ṣe, gbigba alejo ati bẹẹ bẹẹ lọ lo wa nibẹ.

Gomina mẹrin lo ti jẹ ni ipinlẹ Eko lati igba ti ijọba awarawa ti bẹrẹ. Lateef Jakande, Bola Tinubu, Babatunde Raji Fashola ati Akinwumi Ambode.

Tinubu ati Fashola ṣe saa meji pe perepere, ṣugbọn saa kan ni Jakande ati Ambode ṣe.

Bẹẹ gbogbo ara ilu lo mọ pataki owo ori sisan lati fi gbọ bukata ijọba.

Àkọlé fídíò, Èyí ni ìtàn bí ẹni tí mó gbọ́njú mọ̀ bíi bàbà ṣe fipá bá mi lájọṣepọ̀