Ọ̀kan lára àwọn awakọ̀ tó ń tẹ̀lé Makinde pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbá ọkọ̀

Oríṣun àwòrán, others
Ọkan lara awọn Awakọ to tẹle Gomina Ipinlẹ Oyo, Gomina Seyi Makinde, tí orukọ rẹ n jẹ Ramon Mustapha padanu emi rẹ tí awọn mẹta si farapa yanayana ninu ijamba oko to waye nigba ti wọn bọ lati Saki lana.
Iroyin to tẹ ileeṣẹ BBC News Yoruba lọwọ ni pe lójú ẹsẹ ni Awakọ ọhun jade laye lẹyin to fi ori sọlẹ nigba ti ọkọ naa takiti.
Eeyan mẹta to farapa nibi ijamba ọkọ naa ni wọn sure gbe lọ si ile wosan to wa ni itosi agbegbe ti ijamba ọhun tí waye fun itọju.
jamba ọkọ ọhun waye nigba ti Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde n bọ lati ilu Saki nibi to ti lọ ṣe ipade saaju eto ìdibo gomina lọdun 2023. Bakan naa ni iroyin naa ni wọn ti sin Ramon Mustapha ni ilana musulumi ni ile rẹ to wa ni Amuloko niluu Ibadan.








