Wo ohun tí gómìnà Sanwo-Olu sọ nípa ọkùnrin tí ọlọ́pàá yìnbọn lágbègbè Ajah

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti ba ẹbi atawọn ọrẹ Gafaru Buraimoh to di oloogbe lẹyin ti ọlọpaa kan ṣina ibọn fun lagbagbe Ajah kẹdun.
Ọrọ ikẹdun naa lo waye ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Sanwo-Olu, Gbega Akosile fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọru.
Akọsile ni iku arakunrin naa ba gomina Sanwo-Olu lọkan jẹ, o si ti ṣeleri pe ijọba yoo fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iwadii iṣẹle naa ki awọn mọlẹbi oloogbe le ri idajọ ododo gba.
O ni “Ko se ẹni to yẹ ko ku irufẹ iku ti ọkunrin naa ku.”
“Ọkan lara awọn ọmọ ipinlẹ wa ni Buraimoh, o si ni ireti ọjọ ọla to dara, iku rẹ jẹ ohun ibanujẹ fun emi funra mi ati ipinlẹ wa lapapọ, nitori arun to de ba oju naa lo de ba imu.”
“Mo mọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fi ṣikun ofin mu afurasi to gbẹmi oloogbe naa, wọn si ti gba ibọn lọwọ rẹ, bẹẹ naa ni wọn ti bẹrẹ iwadii.”
“Mo wa fi akoko yii rọ awọn araalu ki wọn lọ fi ọkan balẹ ki wọn ma si fi ofin si ọwọ ara wọn.”
“A si fẹ ki gbogbo ara ilu mọ pe awa gẹgẹ bii ijọba yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ ki idajọ ododo le leke.”
Leyin naa lo ni ọọfisi gomina n reti abọ iwadii awọn ọlọpaa lori iṣẹlẹ ọhun.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ọwọ tẹ ìsípẹ́tọ̀ ọlọ́pàá tó yìnbọn pa ọ̀dọ́kùnrin kan ní Ajah

Oríṣun àwòrán, npf
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko sọ pe ọlọpaa kan to yinbọn pa ọdọkunrin kan ni agbegbe Ajah, ti wa ni atimọle.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fi sita, ni nkan bi aago mọkanla aabọ alẹ ọjọ Iṣẹgun ni ọlọpaa yinbọn pa Gafaru Buraimoh, to n gbe ni Happy Land Estate, Ajah.
Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sẹ sọ, wọn ni oloogbe Buraimoh lọ ra epo bẹntiro nile epo, asiko to n pada sile ni isipẹtọ ọlọpaa naa yibọn mọ.
Iroyin miran sọ pe nibi ti Buraimoh ti n gba owo ni ṣọọbu oni POS kan ni ọta ibọn ti isipẹtọ yin ti wa a ba.
Iroyin naa sọ pe isipẹtọ naa, ti wọn ko darukọ, wa lara awọn ọlọpaa to n le awọn to n ta epo bẹtiro lọna aitọ, Black Market.
Iṣẹlẹ naa mu ki awọn ọdọ agbegbe naa ṣe iwọde ni owurọ Ọjọru, ọjọ keje, oṣu Kejila, ọdun 2022.
Nibi iwọde naa la gbọ pe wọn ti di oju ọna marosẹ Ajah.
Iwe iroyin The Nation jabọ pe awọn ọlọpaa tun yin afẹfẹ tajutaju mọ awọn oluwọde, eyi to mu ki iwọde naa di wahala.
Niṣe ni awọn olugbe agbegbe naa kan fi ikede sita pe ki awọn eeyan to ba fẹ lọ si agbegbe Ajah, wa ọna miran gba.
Kini ileeṣẹ ọlọpaa sọ?
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin sọ pe ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ni Ajah, ni ọlọpaa naa ti wa.
O ni loju ẹsẹ ti ọlọpaa naa yinbọn mọ Buraimoh, ni awọn akẹẹgbẹ rẹ ti gba ibọn lọwọ rẹ, ti wọn si mu u.
“Ileeṣẹ ọlọpaa, nipasẹ DPO ileeṣẹ ọlọpaa Ajah ati alamojuto ẹkun Elemoro, ti wa ẹbi ọmọkunrin naa rí, ti wọn si ba wọn kẹdun.
“A ba wọn kẹdun iku ọmọ wọn, to jẹ eyi ti ko yẹ ko waye, a si fi da wọn loju pe iwadii ti bẹrẹ lori nkan to fa bi ọlọpaa sẹ yinbọn, ti idajọ ododo yoo si waye.”
Igba akọkọ kọ niyii ti ọlọpaa n yinbọn pa araalu ni ipinlẹ Eko, ati Naijria lapapọ.
Eyi si wa lara nkan to fa iwọde alagbara EndSars jakejado Naijiria lọdun 2020.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












