Ọlọ́pàá dóòlà èèyàn mẹ́ta, wọ́n rí ìbọn gbà lọ́wọ́ ajínigbé ní Abuja

Awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abuja, ti doola eeyan mẹta kuro ni ahamọ ajinigbe, to si tun ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Alẹ ọjọ Iṣẹgun ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Kubwa Relocation Estate, nibi ti awọn agbebọn ti ja awọn eeyan lole, ti wọn si tun yinbọn mọ awọn eeyan kan.

Kọmiṣọnna ọlọpaa, Sunday Babaji, sọ fun awọn akọroyin pe awọn ọlọpaa doola eeyan mẹta, ti wọn si tun gba ibọn AK-47 kan, ati ọta ibọn marundinlọgbọn, lọwọ wọn.

Agbẹnusọ ọlọpaa ilu Abuja, Josephine Adeh, sọ pe wọn ji awọn eeyan naa gbe lẹyin ti ibọn ba eeyan meji, ninu eyi ti ẹnikan ti kú.

Àwọn agbébọn jí àgùnbánirọ̀, àtàwọn míì gbé, wọ́n tún pa ẹnìkan

Egbìnrìn ọ̀tẹ̀, bí aṣe ń pa ìkan ní òmíràn ń rú.

Àwọn afurasí agbébọn tún ṣọṣẹ́ lánàá ní agbègbè Extention 2 Relocation, òpópónà Arab Road, Kubwa, Abuja níbi tí tí wọ́n ti gbẹ̀mí ènìyàn kan, tí wọ́n sì tún jí ènìyàn méje mìíràn gbé.

Nínú àwọn tí wọ́n jí gbé ọ̀hún ni àgùnbánirọ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adenike.

Ìròyìn ní kété tí àwọn agbébọn ọ̀hún yawọ agbègbè náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní dàbọn bolẹ̀ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ní jí àwọn tí ọwọ́ wọn bá ti bà gbé, tó sí jẹ́ wí pé wọ́n jí Adenike gbé nínú ilé wọn.

Àwọn ènìyàn méjì ni wọ́n ní ìbọn bà nínú ìkọlù náà àmọ́ ẹnìkan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lójú ẹsẹ̀ tí ìbọn náà bà á tí ẹnìkejì sì wà ní ilé ìwòsàn báyìí.

Óṣojúmikòró kan tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní òpópónà Amilomania ni àwọn agbébọn náà kọ́kọ́ wọ̀ ní agbègbè náà kí wọ́n tó bọ́ sí òpópónà Toyin fún ìkọlù ọ̀hún.

“Yàtọ̀ sí àgùnbánirọ̀ tí wọ́n jí gbé àwọn ènìyàn mẹ́sàn-án mìíràn ni à ń wá tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n a ti rí àwọn méjì padà nítorí náà la ṣe mọ̀ wí pé ènìyàn méje ni wọ́n gbé lọ.”

“Láti ìgbà tí ìkọlù náà ti wáyé kò sí éni tó le sùn mọ́ nínú gbogbo wa, ìbẹ̀rù bojo ni kálukú wà báyìí nítorí a ò mọ ohun mìíràn tó tún le ṣẹlẹ̀.”

Bákan náà ló ní àpáta tó wà ní agbègbè náà ni àwọn agbébọn ọ̀hún gbà wọlé kí ọwọ́ má ba à le tẹ̀ wọ́n.