CBN kéde gbèdéke 100,000 owo tí o le gbà ní ATM, POS àti bánkì lọ́sẹ̀

Owo Naira tuntun

Oríṣun àwòrán, Presidency

Banki agba Naijiria ti mu adinku ba iye ti awọn araalu le gba jade ninu asunwọn wọn nile ifowopamọ, lori ATM ati POS.

Oludari ẹka to n mojuto bi awọn banki ṣe n sẹ iṣẹ wọn, Haruna Mustafa, lo fi ikede naa sita.

Ọjọ Iṣẹgun ni CBN fi ikede tuntun sita eyi to fihan pe awọn ọmọ Naijiria ko ni le gba ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira kuro ninu asunwọn wọn ni banki, laarin ọsẹ kan.

Awọn ileeṣẹ ko ni le gba ju ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta.

Yatọ si eyi, owo ti wọn le gba jade ninu asunwọn naa ko ni i ju ẹgbẹrun lọna ogun Naira lati ori ẹrọ POS lojumọ.

Ọjọ kẹsan-an, oṣu Kinni, ọdun 2023, ni ofin tuntun naa yoo bẹrẹ isẹ.

Ikede yii waye lasiko ti CBN n gbaradi lati ko owo Naira tuntun jade fun nina, bẹrẹ lati ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kejila, dun 2022.

Ẹnikẹni ti yoo ba gba ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira laarin ọsẹ kan, gbọdọ ṣetan lati san ida marun-un owo to ba gba. Awọn ileeṣẹ yoo san ida mẹwaa.

Yatọ si eyi, sọwedowo (cheque) to ba le ni ẹgbẹrun lọna aadọta Naira, ko nii jẹ sisan pẹlu owo. Onitọhun ni lati gba a sinu asunwọn rẹ ni.

Fun gbigba owo jade lati inu ẹrọ ATM, gbedeke ẹgbẹrun lọna ogun Naira lojumọ ni CBN fi sita, ko si gbọdọ ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira laarin ọsẹ kan.

Bakan naa ni CBN tun sọ ninu ikede rẹ pe igba Naira (200 Naira) ati awọn owo to wa labẹ rẹ, nikan ni wọn o ma a ko sinu ẹrọ ATM.

Ṣugbọn ṣa, banki agba naa sọ pe ẹnikẹni tabi ileeṣẹ to ba ni eredi to jẹ ootọ, lati gba ju miliọnu marun-un Naira tabi miliọnu mẹwa Naira, yoo la iwadii alagbara kọja.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023, ni CBN gbe owo Naira (200, 500, 1000) jade.