9th Assembly: Èrò ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ẹní tí àṣẹ ilé aṣòfin àgbà Nàìjíríà yóò já mọ́ lọ́wọ́

Ipo igba kini ninu oṣelu awa ara wa ṣe pataki ṣugbọn a ko le fi ọwọ rọ awọn igba to ku naa ṣẹyin.
Idi ree ti awọn eeyan Naijiria ṣe n foju sọna lati mọ ẹni ti yoo di ipo aarẹ ile aṣofin agba mu labẹ saa kẹsan ile aṣofin Naijiria.
Lọjọ kọkanla oṣu Kaarun ni awọn ọmọ ile aṣofin agba yoo dibo yan ẹni ti yoo jẹ olori wọn.
Tani yoo jẹ aarẹ laarin awọn to n du ipo yi ni ibeere nla ti awọn eeyan n reti idahun si.
Awọn to n du ipo naa
Odu lawọn mejeeji ti wọn du ipo aarẹ lẹyin ti Bukola Saraki pari saa rẹ.
Ifidirẹmi ninu idibo gbogbogbo to kọja lo sokunfa bi Bukola Saraki ko ṣe pada wa si ile aṣofin agba bo tilẹ jẹ pe yoo fẹ ṣoro diẹ fun un lati di ipo naa mu.
Awọn meji to lewaju lati di ipo yii mu ni Sẹnẹtọ Ahmad Ibrahim Lawan to n ṣoju ẹkun ariwa ipinlẹ Yobe.

Oríṣun àwòrán, The Nigerian Senate
Akẹgbẹ rẹ ni Sẹnẹtọ Mohammed Ali Ndume lati ipinlẹ Borno to n soju ẹkun guusu Borno. Lati ọdun 2011 lo ti wa ni ile gẹgẹ bi Sẹnẹtọ labẹ asia ẹgbẹ PDP.
Ṣugbọn nigba ti awọn kan kora jọ lati gba ijọba lọwọ ẹgbẹ PDP, o darapọ mọ wọn ti o si jẹ olori ọmọ ile to pọ ju lọ labẹ asia APC.
Kini awọn mejeeji n gbero lati ṣe ti wọn ba de ori aleefa?
Sẹnẹtọ Ndume ni adisọkan oun ni bi ile aṣofin yoo ṣe ni ominira tirẹ ti ko si ni si wi pe eeyan kan yoo ma dunkoko mọ awọn aṣofin nidi iṣẹ wọn.
O ni oun yoo rii pe atunto ba ipo aarẹ ile asofin agba ti oun yoo si ṣapa lati koju iwa jẹgudujẹra.
Ko fẹrẹẹ si iyatọ pupọ ninu nnkan ti Sẹnẹtọ Lawan naa fẹ ṣe ti o ba di aarẹ ile asofin agba.

Oríṣun àwòrán, The Nigerian Senate
Ohun naa ko fẹ ki awuyewuye pupọ wa laarin ẹka aṣofin ati ti alaṣẹ ijọba.
Lawan kii ṣe aimọ lagbo oṣelu ti ọpọ awọn Sẹnẹtọ si ti lawọn yoo gbaruku ti lati di aarẹ ile asofin.
Bawo ni idibo naa yoo ti ṣe lọ?
Ati aarẹ ile asofin ati igbakeji rẹ ni wọn yoo yan lọjọ iṣẹgun.
Gbogbo awọn asofin mọ́kàndínláàdọ́fà ni yoo dibo yan ẹni tọkan wọn fẹ.
Labẹ ofin idibo ile,idibo bonkẹlẹ alafihan(open secret ballot) ni iwe ofin la kalẹ.
Ko ti daju boya wọn yoo fi ibo tẹnikọọkan ba di han ṣugbọn eyi keyi to ba jẹ,bi oludije kan ba ti le ni ibo to pọju tẹni keji rẹ, oun ni yoo di aarẹ.
Ṣe aṣẹ ẹgbẹ APC yoo ṣẹ lọtẹ yi?
Awọn onwoye ni idanwo ni idibo aarẹ ile asofin yi yoo jẹ lati mọ boya awọn ọmọ ẹgbẹ APC yoo tẹle aṣẹ ẹgbẹ.
Aṣẹ ti a n sọ yi ni eleyi ti o wa lati ọdọ awọn adari ẹgbẹ to fi mọ aarẹ Buhari pe ki awọn ọmọ gbẹ dibo fun sẹnẹtọ Lawan ati Omo Agege gẹgẹ bi aarẹ ati igbakeji aarẹ.

Oríṣun àwòrán, SPNigeria
Bi a ko ba gbagbe, lasiko ti idibo ile asofin agba waye ni saa to kọja ẹnu ẹgbẹ ko ṣebi ẹni papọ soju kan eleyi to mu ki Sẹnẹtọ Bukola Saraki ati Sẹnẹtọ Ike Ekweremadu gbegba oroke.
Ninu iwoye tirẹ, amofin kan to fi ilu Ibadan ṣe ibujoko, Saliu Adebayo, ni APC ti kọgbọn latara ohun to ṣẹlẹ ni saa to kọja.
''Gbogbo wahala ti aarẹ koju pẹlu ile aṣofin ni saa to kọja ko ṣẹyin pe ẹnu ẹgbẹ ko ko. O da mi loju pe wọn ko ni fi ina sori orule sun lọtẹ yi''
Amofin Adebayo tẹsiwaju pe esi abajade ibo yi yoo tubọ fi rinlẹ boya APC ṣetan lati di agbara mu ni gbogbo ẹka ijọba lalai fi ọkan jafara.















