8th Assembly: Saraki pín owó ìyọ̀nda rẹ̀ fún ẹbí Leah Sharibu àtàwọn míì

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, Twitter/Dr Abubakar Bukola Saraki

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Adari ile igbimọ aṣofin agba ikẹjọ to ṣeṣẹ kogba sile, Sẹnẹtọ Bukola Saraki ti fi owo iyọnda rẹ ranṣẹ si awọn ẹbi akẹkọọbinrin Leah Sharibu to wa lakata Boko Haram atawọn oṣiṣẹ oluranlọwọ ti Boko Haram sẹkupa.

Saraki sọrọ di mimọ ninu atẹjade ti oluranwọ rẹ lori ọrọ iroyin, Yusuph Olaniyonu fi sita.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Saraki tun sọ pe ki awọn alaṣẹ ile tun pin owo naa kan awọn ọmọ ṣẹnẹtọ to ku nigba to jẹ adari ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja.

Àkọlé fídíò, Ladoja: Àwọn èèyàn Oyo fì ìbò sọ̀rọ̀ pé ìjọba Ajimobi kò dára

Sẹnẹtọ Saraki ni oun gbe igbesẹ yii nitori pe ko si igba ti ile ba ṣe apero lori ọṣẹ tawọn agbsumọmi n ṣe papaajulọ lagbegbe ila-oorun ariwa, ti kii ba oun lọkan jẹ.

O rọ ile igbimọ aṣofin kẹsan an to sẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ lati ya owo kan s'ọtọ gẹgẹ owo iranwọ fawọn ti ko rọwọ họri.

Àkọlé fídíò, Ondo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú
Àkọlé fídíò, Barister lo bi gbogbo oníṣẹ́ fújì -Oṣupa

Ida ogun ninu ida ọgọrun owo iyọnda rẹ lo ṣo pe ki wọn fun ẹbi Leah, iye kan naa lo ni ki wọn fun idile Hauwa Liman ati Hussaini Ahmed Khoisan, awọn oṣiṣẹ oluranlọwọ ti Boko Haram pa.

Saraki ni ki ile lo ida ogoji lati ṣeranwọn feto ẹkọ awọn ọmọ sẹnẹtọ to ku nigba to jẹ adari ile lati ọdun 2015 si 2019.