Ilé aṣòfin àgbà Nàìjíríà dàbí ọjà bí Saraki ṣe pa Akpabio lẹ́nu mọ́

Senate bin adjourn sitting to Wednesday to honour di death of one member from Kwara.

Niṣe ni ile aṣofin agba Naijiria ri bi ọja Oyingbo l'Ọjọru lẹyin ti Aarẹ ile aṣofin naa, Sẹnetọ Bukọla Saraki, ko gba ki Sẹnetọ Godswill Akpabio o joko si aaye to tọ si i.

Ile aṣofin naa daru lẹyin ti Sẹnetọ Bassey Akpan to n ṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP, lati ipinlẹ Akwa Ibom, tọka si awọn kudiẹ-kudiẹ kan to waye nibi eto idibo abẹle ẹgbẹ APC to waye ni ipinlẹ Akwa Ibom.

Akpan wa kesi ile aṣofin pe ko gbe igbesẹ nitori pe 'eto idibo naa dunkooko mọ alaafia ipinlẹ Akwa Ibom’.

Ki lo sọ eyi si, ni Sẹnetọ Akpabio, to ti fi igba kan jẹ olori ọmọ ẹgbẹ oṣelu to kere julọ nile aṣofin naa, ba na ọwọ lati fesi lori ọrọ ọhun, ṣugbọn Bukọla Saraki ni ko gbọdọ sọrọ, ayafi to ba pada si ibi aaye ijoko rẹ.

Akpabio

Oríṣun àwòrán, @NGRSenate

Àkọlé àwòrán, Laipẹ yii ni Godswill Akpabio kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, to si lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.

Ki leyii waye si, a fi bi olori ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọju lọ, Sẹnetọ Ahmad Lawan ati awọn sẹnetọ mi i to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, ṣe sọ pe ko si nkan to jọ bẹ, pe ko si ibi ti Akpabio joko si ti ko ti le sọrọ ninu ile aṣofin naa.

Ṣugbọn awọn iroyin kan tun sọ pe, ẹrọ gbohungbohun ti Akpabio n lo lati sọrọ ko ṣiṣẹ daada lo mu ki Saraki sọ fun un pe ko lo omiran - ti Sẹnetọ Alli Ndume.

Lootọ ni Akpabio pada si ibi aaye ijoko rẹ, ṣugbọn o sọ pe, Saraki gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ oun fun iwa ifini se ẹlẹya to hu si oun. Amọ, Saraki sọ pe rara, ọ̀rọ̀ ko ri bẹ.

Ile asofin
Àkọlé àwòrán, Awọn kan sọ pe nitori pe Akpabio ti fi ẹgbẹ PDP silẹ Saraki ṣe huwa bẹ si

Laipẹ yii ni Godswill Akpabio kuro ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, to si lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.