State Assembly: Adebo, Oluomo di adarí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo, Ogun

Awọn adari tuntun ile aṣofin Oyo ati Ogun

Oríṣun àwòrán, @Adebo_ogund, Olakunle Taiwo Oluomo

Àkọlé àwòrán, Họnọrebu Adebo Edward Ogundoyin ati Họnọrebu Olakunle Taiwo Oluomo

Awọn Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ati Ogun ti kede awọn to jawe olubori gẹgẹ bii adari ile.

Ni ipinlẹ Oyo, Họnọrebu Adebo Edward Ogundoyin ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party to n ṣoju ẹkun idibo Ila Oorun Ibarapa nipinlẹ Oyo lo bori.

Bakan naa ni wọn yan Họnọrebu Abiodun Muhammed Fadeyi to n ṣoju ẹkun idibo Ona Ara ni igbakeji adari ile aṣofin ipinlẹ Oyo.

Àkọlé fídíò, Iba Gani Adams: Bẹ́ẹ gbé màláíkà kan lọ sí Aso Rock, kò lè ṣàṣeyọrí

Ẹwẹ, bo ṣe n waye nipinlẹ Oyo naa lo n ri bakan naa ni Oke-Mosan, Abeokuta ipinlẹ Ogun nibi ti Họnọrebu Olakunle Taiwo Oluomo jawe olubori gẹgẹ bii adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun.

Olakunle n ṣoju ẹkun idibo Ifo 1 nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogunti wọn si yan an lai ni alatako kankan.

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Bẹẹ si ni wọn yan Họnọrebu Abiodun Muhammed Fadeyi to n ṣoju ẹkun idibo Ijebu North II gẹgẹ bii igbakeji adari ni ipinlẹ Ogun.

Idibo awọn mejeji si igbimọ aṣofin ikẹsan waye lai si alatako kankan.