Osun State: Gómìnà Oyetola wọ́gilé ìrìnàjò àwọn alága sí UAE

Gomina Adegboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adegboyega Oyetola

Àkọlé àwòrán, Ọrọ lori inrinajo awọn alaga ijọba ibilẹ nipinlẹ Osun

Gomina Ipinlẹ Oṣun, Adegboyega Oyetola ti wọgile irinajo si ilu okere tawọn alaga mejidinlaadọrin ipinlẹ naa n gbero lati lọ fun ijiroro.

Gomina Oyetola sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Adeniyi Adesina fi lede.

Awọn alaga naa ti kọkọ fi atẹjade kan sita pe awọn yoo lọ si ilu Dubai loṣu kẹfa yii.

Àkọlé fídíò, Iba Gani Adams: Bẹ́ẹ gbé màláíkà kan lọ sí Aso Rock, kò lè ṣàṣeyọrí
Àkọlé fídíò, Ondo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Wọn ni idi abajọ irinajo naa ni lati jẹ ki awọn alaga ipinlẹ naa ni iriri iṣejọba ibilẹ, gẹgẹ bi o ti rii kaakiri agbaye.

Ẹwẹ, gomina Oyetola sọ pe asiko ko tii to fun iru irinajo yii bo tilẹ je pe ohun ti wọn fẹ ṣe lorilẹede UAE ṣe pataki.

Àkọlé fídíò, BBC Africa Eye: Akọroyin fẹ ìdí àwọn oníṣẹ́ ibi ọmọ ogun síta

Gomina ipinlẹ Oṣun ṣalaye pe ijọba oun yoo tẹsiwaju lati maa fun awọn oṣiṣẹ ọba lanfaani lati maa lọ fun idanilẹkọọ loorekoore bi agbara rẹ ba ti mọ.

Awọn alaga ọhun fi sinu atẹjade pe ijọba ipinlẹ Oṣun ni yoo san owo fisa, owo baalu ati ile itura ti wọn yoo de si lorilẹede UAE.