Child Trafficking: Àwọn ọmọ ọdun mẹ́fà sí mẹ́wàá pọ̀ tí a ti tú sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Tẹlẹ ipinlẹ Edo lo n ṣaaju, ninu awọn ipinlẹ Naijiria to n fini s'owo ẹru. Ṣaadede ni ipinlẹ Oyo toun na jẹ ọkan lara ibi to ti n waye gba a mọ ipinlẹ Edo lọwọ.
Nibi ibi iwe kika kan to waye nilu Ibadan ni aṣoju ajọ to n ri si iwọle wọde lorilẹede Naijiria ti fi ọrọ lede.
Pe bi iye awọn ti wọn n tu silẹ nilu Ibadan atawọn agbegbe rẹ ṣe n pọ sii, o ti n sọ ọ di aarin gbungbun fun ifini ṣ'owo ẹru.
Lọdun 2019, ile iṣẹ iroyin NAN fabọ jẹni pe ipinlẹ Edo lo ni iye awọn ti wọn fi n ṣ'owo ẹru ju ati irinajo lọna aitọ.
Iroyin naa sọ pe ipinlẹ Edo ti gba to arinrinajo to din diẹ ni ẹgbẹrun mẹrin wọle laarin oṣu ikọkanla ọdun 2017 si ikeje ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹwẹ, alabojuto ẹka to n gbogun ti fifini ṣ'owo ẹru ni ajọ to n ri si iwọle wọde lorilẹede Naijiria, Foluso Akintola ni orilẹede Naijiria nikan n ṣe iṣẹ gẹgẹ bii orisun, ọna ati ebute abode ifini ṣ'owo ẹru.
Akintola ni ajọ to n ri si iwọle wọde Naijiria ni ipinlẹ Oyo sọ pe laarin ọmọde mẹfa si mẹwaa lawọn ti gba silẹ, "ọjẹ wẹwẹ si lawọn wọnyi o; awọn mii t'ọjọ ori wọn ko tii to mejidinlogun naa la tun ti gba silẹ lagbegbe yii.
Ọpọlọpọ wọn ni wn maa n lo gẹgẹ bi ọmọ ọdọ, olutaja tabi ki wọn maa kiri ọja loju popo ati laarin igboro.
Lọdun 2016, "awọn mẹrindinlogoje la gba silẹ ti a si mu awọn afini ṣ'owo ẹrun mejidinlogoji, awọn to n lo wọn meje le ọgọrun pẹlu eniyan mọkanla ti wọn ti gba. Ninu eyi afiniṣ'owo ru mọkanla ni wọn fi jofin. lọdun naa.
Akintola jẹ ko di mimọ pe ipenija yii ti di eyi to de gongon awọn ọmọ Naijiria to si n mu ẹmi ọpọ lọ sii laarin agbami okun Mediterranean fun awọn to n sa gba ibẹ.
Lonii, irọ ipese iṣẹ ni Arab world, Saudi Arabia, Qatar, Oman, Libya, lawọn afini s'owo ẹru maa n pa fun awọn ti wọn ba fẹ lo. Wọn a gba wọn bi ẹni gba ni ṣiṣẹ́, wọn a si ko wọn lọ maa ṣe iṣẹ nọbi.















