Ijamba Italy: Awọn arinrinajo fori sọta ni Macerata

Oríṣun àwòrán, EPA
Jennifer Otioto, ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn sọrọ lati ile iwosan rẹ wipe "Mo ṣẹṣẹ de si orilẹede Italy ni"
Ni owurọ ọjọ kẹta osu keji, Otioto duro ni ibudokọ akero ni ilu Macerata.
Ọkunrin Italy kan ti o jẹ ọmọ ọdun mejidinlọgbọn, Luca Traini, lọ si ọdọ rẹ ni Alfa Romeo o si yin in nibọn.
Otioto, ti o jẹ onidiri ti wa ninu irora ijamba ibọn lọwọlọwọ bayi. O wa ninu ibanujẹ latari isẹlẹ yi pẹlu.
"Iru wahala bayi ko ye mi rara," o sọ.
Luca Traini yinbọn si eniyan marun lọjọ yẹn. Ko si ẹni ti o ku ninu wọn, gbogbo wọn ye.

Oríṣun àwòrán, AFP
O farahan pe o se afojusun ẹnikẹni ti o dabi pe wọn wa lati ilẹ Afirika.
Kofi Wilson, ti o jẹ ọmọ ogun ọdun lati orilẹ̀ede Ghanan jade l lati lọọ ge irun ori rẹ nigbati o kagbako. O gba ọta ibọn ni aya rẹ.
"A gbọ ti awọn iro ibọn ndun ni akọkọ," Wilson rántí. "Lẹhin awọn iro ibọn akọkọ yi, a ko gbọ nnkan kan mọ", o sọrọ.

"Kii ṣe ipinnu mi lati jẹ dudu [eniyan]," o tẹsiwaju. "O jẹ aṣiṣe buburu lati [gbiyanju lati] pa eniyan dudu."
Kofi Wilson ti wa ni Itali fun ọdun mẹta. Ibon yiyan fun un yi ko mu ki o yi okan rẹ pada nipa ọjọ iwaju rẹ. Ko ni ipinnu lati pada si Ghana.
"Emi yoo fẹ lati duro ni Italy, ko da fun igba iyoku aye mi."
Ṣugbọn otitọ ni wipe ọpọlọpọ awọn ọmọ Italy yoo fẹ lati ri pe ki awọn eniyan lọ kuro nilu wọn.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ọkẹ mẹrin eniyan ngbe ilu yii. Olori Macerata, (Mayor) Romano Carancini sọ wipe ida mẹsan ninu ọgọrun ninu awọn olugbe ilu naa jẹ awọn aṣikiri tabi arinrinajo.












