Walter Onnoghen kọ̀wé ìfẹ́yìntì ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ àgbà Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Muhammadu Buhari ti tẹ́wọ́ gba iwe ifẹyinti eyi ti adajọ agba, Walter Onnoghen kọ funra rẹ.
Ṣaaju wọn ti jawe lọ sinmi nile fun Onnoghen latari ọrọ to ni ṣe pẹlu aikede dukia rẹ laipẹ rẹ si ni iroyin kan n ja rayin rain pe Ṣé lòótọ́ ní pé adájọ àgbà Nàìjíríà Walter Onnoghen tí kọwe fiṣe sílẹ?
Gẹgẹ bi akọsilẹ inu iwe naa, ifẹyinti Onnnoghen gẹgẹ bi adajọ Naijiria yoo bẹrẹ ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu karun un.
Ninu ọrọ̀ ti oluranlọwọ agba fun aarẹ, Garba Shehu fi sita, o ni aarẹ Buhari dupẹ lọwọ rẹ fun iṣẹ isin rẹ si orilẹede o si gbadura ifẹyinti ayọ fun un.
Ninu oṣu kinni ọdun 2019 ni aarẹ Buhari jawe lọ rọọkun nile fun Onnoghen gẹgẹ bi alakalẹ ofin ile ẹjọ to n gbọ ẹsun awọn to du ipo nla mu lawujọ.
Ni oṣu kẹrin, ile ẹjọ dajọ pe Walter Onnoghen jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an ti wọn si ni ko lọ rọọkun nile.
Bakan naa, oluranlọwọ agba fun aarẹ sọ pe aarẹ Buhari ti kọwe si adele adajọ agba Tanko Muhammed lati yan adajọ marun un mii si ile ẹjọ giga ju lọ ti orilẹede Naijiria.
Eyi jẹ lati fi kun iye awọn adajọ to wa ki wọn le pe mọkanlelogun gẹgẹ bi o ṣe wa ninu ofin.













