Walter Onnoghen: Ṣé lòótọ́ ní pé adájọ àgbà Nàìjíríà tí wọ́n ní kó lọ rọ́ọ́kún nílé tí kọwe fiṣẹ sílẹ?

Walter Onnoghen

Oríṣun àwòrán, Nigeria Bar Association

Àkọlé àwòrán, Wọn fi awọn ẹsun to jọ mọ ajẹbanu ati awọn ẹsun miran kan Adajo agba naa

Iroyin to n tẹwa lọwọ sọ pe adajọ agba Naijiria ti wọn pasẹ lọ rọọkun nile ti wa papa kọwe fi ipo silẹ.

Gẹgẹ bi ohun ti a ri ka ninu iwe iroyin Naijiria kan,The Cable, adajọ agba Onnoghen ''fi iwe ikọwefiposilẹ rẹ sọwọ si aarẹ Buhari ni ọjọbọ lẹyin ọjọ kan ti igbimọ to n risi ọrọ eto idajọ NJC fi abajade iwaadi wọn ranṣẹ si aarẹ Buhari.''

Lara ohun ti igbimọ da laba ni pe ki wọn paṣẹ ifẹyinti lẹnu iṣẹ adajọ naa lẹyin ti wọn ṣe agbeyẹwo gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an.

Onnoghne ni ohun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan.

A ṣi n ṣe akojọpọ iroyin naa ṣugbọn ni kete ti a ba ri aridaju bi nnkan ti ṣe ri, a o fi to yin leti.