Walter Onnoghen: UNO bẹnu àtẹ́ lu ìdàdúró adájọ́ àgbà

Walter Onnoghen

Oríṣun àwòrán, NJC

Àkọlé àwòrán, Ọrọ lori idaduro Onnoghen

Ajọ iṣokan agbaye iyẹn UNO ti bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe ni ki adajọ agba lorilẹede Naijiria Wallter Onnoghen lọ rọkun nle.

Ajọ UNO sọ pe igbesẹ yii tako ẹtọ ọmọniyan lagbaaye.

Agbẹnusọ fun ajọ agbaye ṣalaye pe

ile ẹjọ to dawa nikan lo laṣẹ lati yọ awọn adajọ nipo.

Àkọlé fídíò, Ọkọ àti ìyàwó sọ àsọtẹ́lẹ̀ tani yóò wọlé nínú PDP tàbí APC

Ẹwẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe o gbe igbesẹ lati rọpo adajọ Onnoghen lẹyin ti ile ẹjọ to n ri si igbẹjọ iwa ibajẹ awọn oṣiṣẹ ọba paṣẹ bẹẹ.

Ṣugbọn ajọ agbaye sọ pe ile ẹjọ mẹrin ọtọtọ lo ti dajọ pe ki wọn da igbẹjọ Onnoghen duro.

Nibi osẹ meji sẹyin ni aarẹ Buhari fi adajọ Ibrahim Tanko Muhammad rọpo Onnoghen.

Bẹẹ lawọn ẹgbẹ oṣelu alako bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ọhun, wọn ni oṣelu ni ijọba Aarẹ Buhari fi ọrọ naa ṣe.

Ilẹ Gẹẹsẹ, Amẹrika ati Ilẹ Alawọfunfun(EU) naa kuro oju si asiko ti ijọba ni ki adajọ Onnoghen lọ rọkun nle.

Adajọ agba lorilẹede Naijiria lagbara lati yanju awuyewuye lori esi idibo.