NFF: Olóògbé Taiwo Ogunjobi gbá bọ́ọ̀lù fún Nàìjírìa nígbà ayé rẹ̀

Taiwo Ogunjobi

Oríṣun àwòrán, NFF

Àkọlé àwòrán, Taiwo Ogunjobi papoda
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọpọ lo n ṣedaro akọwe ajọ to n ri si ere bọọlu lorilẹede Nàìjíríà, NFF tẹ́lẹ̀rí, Taiwo Ogunjobi.

Ogunjọbi papoda lowurọ ọjọ Aje, ọjọ kọkanla oṣu keji odun 2019 niluu Ibadan lapa iwọ oorun gusu Naijiria.

Ajọ NFF lo kede iku rẹ loju opo Twitter wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ogunjọbi ṣe akọwe ajọ NFF laarin ọdun 2002 si ọdun 2005, bẹẹ o jẹ ọmọ igbimọ alaṣẹ ajọ NFF laari ọdun 2006 ati 2010.

Ogunjọbi jade laye lẹni ọdun marun le lọgọta nigba ti o pe ọdun marunlelọgbọn ti o ṣoju orilẹede Naijiria fun igba akọkọ ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Morocco lọdun 1984.

Ọgbẹni Tunde Shamsudeen to jẹ amugbalẹgbẹ rẹ ṣalaye pe oloogbe Ogunjobi lọ si ile iwosan lọjọ Abamẹta ki awọn dokita to ni ko lọ sinmi.

Taiwo Ogunjobi

Oríṣun àwòrán, @Emiearth

Àkọlé àwòrán, Taiwo Ogunjobi

Lẹyin igba naa ni Ogunjobi di oloogbe laarọ ọjọ Aje, ile iwosan ko sọ iru aisan kan gbogi to pa oloogbe naa.

Ogunjobu gba bọọlu fun gbajugbaja ẹgbẹ agbabọọlu un ni Shooting Stars ti ilu Ibadan.

Oun ni balogun ikọ agbabọọlu Shooting Stars to kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije Ife Ẹyẹ ilẹ Afirika lọdun 1984 ti o ti di African Champions League bayii.

Taiwo Ogunjobi
Àkọlé àwòrán, Taiwo Ogunjobi di oloogbe

Wọn fẹsun wi pe o wa lara awọn mẹrin ti o mọ nipa bi miliọnu mẹjọ owo dọla ti poora lasiko ti idije ife ẹyẹ agbaye n lọ lọwọ lọdun 2010.

Ṣugbọn ile ẹjọ dajọ are fun un ko jẹbi ẹsun ti wọn kan an lẹyin iwadi ti wọn ṣe.

Ogunjọbi dije lẹẹmeji fun ipo aarẹ ajọ NFF, ṣugbọn o fidi rẹmi lẹyin ti Amaju Pinnick wọle lẹẹmejeeji.

Oloogbe Ogunjọbi jẹ alaga ajọ ere bọọlu nipinlẹ Oṣun ki ọlọjọ to de.