Kí làwọn àtúntò tí ìjọba Nàìjíríà mú bá ètò ìdánwò WAEC àti NECO láti dènà àwọn aṣemáṣe?

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń kọ ìdánwò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ìjọba Nàìjíríà ti kéde àwọn àyípadà kan sí ètò ìdánwò àṣekágbá nílé ẹ̀kọ́ girama ìyẹn West African Certificate Examination, WAEC àti National Examination Council, NECO bẹ̀rẹ̀ láti ìdánwò ọdún 2026.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé, gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ ní Nàìjíríà ṣe sọ, láti kojú àwọn aṣemáṣe kan tó máa ń wáyé lásìkò àwọn ìdánwò náà.

Ètò ìdánwò WAEC àti NECO ló wà fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama tí wọ́n wà ní ipele àṣekágbá, tí wọ́n sì ń múra láti lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga.

Níbi ètò ìdánwò WAEC tọdún 2025, kò dín ní ìdá mẹ́wàá èsì ìdánwò tí ìjọba kọ̀ láti fi síta nítorí àwọn aṣemáṣe tó wáyé lásìkò ìdánwò náà.

Láti kojú àwọn ìṣòro yìí, iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ sọ pé àwọn gbé àwọn ìlànà tuntun yìí kalẹ̀ láti lè ri pé ìgboyà wà nínú ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́, Boriowo Folasade nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lójú òpó X sọ pé àwọn máa pọnkún akitiyan wọn láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn ètò ìdánwò àpapọ̀ gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwọ bọ̀.

Èyí ni àwọn àyípadà tí wọ́n ṣe sáwọn ìdánwò WAEC àti NECO:

Dída àwọn ìbéèrè rú

Àtẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ fi léde náà sọ pé àwọn máa bẹ̀rẹ̀ sí ní da àwọn ìbéèrè rú tó jẹ́ pé ìbéèrè akẹ́kọ̀ọ́ méjì tó bá jókòó ti ara wọn kò ní jọra.

Wọ́n ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbéèrè kan náà ni gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ máa dáhùn àmọ́ bí wọ́n ṣe máa tò àwọn ìbéèrè máa yàtọ̀ síra fún akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan.

Títo àwọn ìbéèrè lọ́nà tó yàtọ̀ kìí ṣe ohun tuntun níb ètò ìdánwò ní Nàìjíríà nítorí àjọ tó ń ṣe ètò ìdánwò sí ìgbani sílé ẹ̀kọ́ gíga, Jamb máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìdánwò wọn.

Fífòfin de àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ipele àṣekágbá

Boriowo Folasade sọ nínú àtẹ̀jáde náà sọ pé àwọn bẹ̀rẹ̀ fífi òfin de àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá wà ní ipele àṣekágbá ní ilé ẹ̀kọ́ girama láti máa lọ kà á ní ilé ẹ̀kọ́ míì yàtọ̀ sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n bá ti ń bá bọ̀ tẹ́lẹ̀.

Ẹ ó rántí pé nínú oṣù Kejìlá ọdún 2025 ni ìjọba ti kéde fífi òfin de àwọn ilé ẹ̀kọ́ girama láti máa gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí SS3.

Ó ní lọ́pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ọgbọ́n láti ṣe aṣemáṣe níbi ètò ìdánwò ni wọ́n fi máa ń gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí ètò ẹ̀kọ́ ní ipele ìkẹyìn.

Ṣíṣe ètò ìdánwò kéékèèkèé ṣáájú ìdánwò ńlá

Àtẹ̀jáde náà sọ pé iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé àwọn ìlànà kan jáde tí gbogbo àwọn àjọ tó ń ṣe ìdánwò gbọdọ̀ tẹ̀lé ní gbogbo sáà ètò ẹ̀kọ́.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, àwọn àsìkò ti wà tí àwọn ìdánwò náà gbọdọ̀ jẹ́ gbígbékalẹ̀.

Ó gbọdọ̀ wáyé ní oṣù Kìíní fún sáà ètò ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́, oṣù Kẹrin fún sáà kejì nígbà tí sáà kẹta gbọdọ̀ wáyé nínú oṣù Kẹjọ.

Wọ́n ní àwọn àsìkò yìí gbọdọ̀ jẹ́ títẹ̀lé ní gbogbo ìgbà láti lè ri pé wọ́n tẹ̀le bó ṣe yẹ.

Nọ́mbà ìdánimọ̀ tuntun

Ní àfikún, iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ní àwọn ti ṣàgbékalẹ̀ nọ́mbà ìdánimọ̀ tuntun fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan tí yóò jókòó fún ìdánwò ọdún 2026 àtàwọn ọdún tó ń bọ̀.

Àtẹ̀jáde náà ní nọ́mbà ìdánimọ̀ yìí yóò jẹ́ kí wọ́n le ṣàmójútó akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan àti láti lè ṣe àkóso ètò ìdánwò náà bó ṣe yẹ.

Láti bíi ọdún márùn-ún sẹ́yìn báyìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń kópa nínú ètò ìdánwò WAEC àti NECO ló ń ṣe dáadáa tó fi mọ́ gbígba máàkì tó lọ sókè nínú ìmọ̀ ìṣirò àti Gẹ̀ẹ́sì.

Ṣùgbọ́n èyí já wálẹ̀ lọ́dún 2025 báwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó gba máàkì tó dára kò ṣe ju ìdá méjìdínlógójì lọ nínú gbogbo àwọn èèyàn tó jókòó fún ìdánwò náà.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 1,969,313 ló kópa níbi ètò ìdánwò WAEC lọ́dún 2025 ṣùgbọ́n àwọn 754,545 péré ló gba máàkì tó dára nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ márùn-ún tó fi mọ́ ìmọ̀ ìṣirò àti èdè Gẹ̀ẹ́sì.