Man City vs Chelsea: Wọn ṣe ìyà fún Chelsea pẹ̀lú àmì ayo 6-0

Man city

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Manchester City ló ń se ipò kíní lórí tábìlì Premier League pẹ̀lú àmì ayò 65 lórí àtẹ.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester city ti fi agba han ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lẹyin ti wọn na wọn pẹlu ami ayo mẹfa si odo.

Sergio Aguero lo pegede julọ ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye ni alẹ Ọjọ Àìkú.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ọhun lo n leke tabili pẹlu ami ayo marunlelọgọta (65) lori atẹ tabili Premier League.

Àkọlé fídíò, Ọkọ àti ìyàwó sọ àsọtẹ́lẹ̀ tani yóò wọlé nínú PDP tàbí APC

Liverpool naa pẹlu na Bournemouth, eleyii to ti mu ki ẹgbẹ agbabọọlu naa si wa ni ipo keji ni ori tabili.