Mọ̀lẹ́bí Omije oju mi fagilé ètò ìsìnkú tí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ kéde

Oríṣun àwòrán, Bunmi Akinnanu/Facebook
Awọn ẹbi gbajumọ akọroyin ẹmi to di oloogbe lọsẹ to kọja, Bunmi Akinnanu tawọn eeyan mọ si Omije Oju mi, ti fagile eto isinku to gbode ṣaaju, eyi ti awọn ẹlẹgbẹ rẹ kede.
Ninu fidio kan to gun ori ayelujara lọjọ Aiku ni ẹnikan to pe ara rẹ ni Lanre Alewilese, toun naa jẹ akẹgbẹ Omije Oju mi, ti kede pe ẹbi Oloogbe naa ti fagile ikede iṣaaju, fun idi kan tabi ikeji.
Tẹ o ba gbagbe, olorin ẹmi miran, Alayo Melody Singer lo kọkọ kede ilana eto isinku naa pe yoo bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun, ogunjọ oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii.
Nibu ikede naa ni won ti ni ninu ọgba tẹlifiṣan ipinlẹ Eko ni wọn yoo ti ṣeto isin orin onigbagbọ fun Omije Oju mi.
Wọn tun ni awon yoo ṣeto titan abẹla fun un pẹlu.
Ikede ọhun tun sọ pe wọn yoo sin akọrin ẹmi to ku lọjọ kejila oṣu yii naa, ati pe wọn yoo sinku rẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu kin-in-ni ọdun 2026.
Wọn fi kun un pe mọlẹbi atawọn to ba sunmọ Oloogbe timọ timọ nikan ni yoo wa ni itẹ oku naa.
Ṣugbọn ni bayii, awọn ẹbi Akinnanu ti fagile eto iṣaaju naa.
"Ẹbi yoo maa kede isinku to ba ya"
Ninu fidio naa ni Lanre Alewilese ti sọ pe igbimọ isinku naa sọ pe idile Akinnanu gbe igbesẹ yii lati yanju awọn nnkan kan.
Gẹgẹ bi Alewilese ṣe wi ninu fidio naa:
"Ki i ṣe adaṣe, lati ọdọ gbogbo igbimọ isinku Bunmi Akinnanu, Omije Oju mi ati gbogbo famili ni fidio yii ti jade.
"Nnkan ti wọn ni ki n sọ fun gbogbo ọmọ Naijiria ni pe isinku Bunmi Akinnanu ti a ni o maa waye lọjọ Iṣẹgun ati Ọjọru ni LTV ko ni i le waye mọ.
"Nitori pe fun idi kan tabi ikeji, wọn ti sun un siwaju. Bo ba ṣe maa jẹ, awọn omo Naijiria maa pada gbọ, ọjọ to maa jẹ awon ẹbi maa kede rẹ, gbogbo eeyan maa gbọ."
Ẹ o ranti pe lojiji ni iroyin iku Omije Ojumi gbode lọsẹ to kọja, ti ọpọ eeyan si n daro obinrin ti wọn ni ibi ẹsẹ to n dun un ni iku rẹ ti wa naa.
Ohun ti awọn kan n sọ nipa ikede ẹbi yii ni pe awọn nnkan kan to jẹ mọ ede aiyede lo n ṣẹlẹ lori ikede akọkọ.
Wọn ni eyi lo mu ẹbi pinnu pe awọn yoo kedẹ funra awọn to ba ya.
Ṣaaju ni Omije Oju Mi ti kọkọ n ṣaisan to si n lọ si awọn ile ijọsin fun iṣẹ adura lati bori aisan naa.
Lọdun to kọja ni fidio kan jade, nibi ti olorin ẹmi ọhun ti jokoo sori aga kan ti ẹsẹ rẹ mejeji si wu, ti wolii kan si n gbadura fun iwosan rẹ.
Lẹyin naa ni awọn ololufẹ rẹ ko gbọ nnkankan mọ titi di asiko ti iroyin iku rẹ gba igboro kan yii.














