Awuyewuye bí ọmọ Atiku Abubakar ṣe darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, kéde àtìlẹyìn fún Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Facebook/Getty Images
Ọmọ igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Atiku Abubakar, Abba Atiku Abubakar ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP sílẹ̀ bọ́ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC.
Abba Atiku Abubakar tún ṣèlérí láti ṣe àtìlẹyìn fún ìtúnyànsípò Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027.
Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kìíní ni igbákejì ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Barau Jibrin àti igbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC lẹ́kùn ìlà oòrùn àríwá Mallam Mustapha Saliu gba Abba Atiku Abubakar sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìlú Abuja.
Nígbà tó ń kéde ìpinnu rẹ̀ láti fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ àti dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Abba Atiku Abubakar ní ìgbésẹ̀ náà jẹ́ ìpinnu òun, tó sì ní ààmì fún òun.
Bákan náà ló kéde yíyí orúkọ ìgbìmọ̀ tó ń bá a ṣiṣẹ́, tó dá sílẹ̀ lọ́dùn 2022 padà láti Atiku Haske Organization sí Haske Bola Tinubu Organization.
Ó wá darí àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ náà àtàwọn tó ń ṣe àkóso rẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lẹ́yẹ ò sọkà, kí wọ́n sì ṣe àtìlẹyìn fún Tinubu.
Ó sọ pé ìgbésẹ̀ òun ń wáyé látàrí ipa rere tí Sẹ́nétọ̀ Barau Jibrin fi lélẹ̀ àtàwọn iṣẹ́ ribiribi tí Ààrẹ Tinubu ń gbé ṣe ní Nàìjíríà.
Ó ṣàlàyé pé òun máa ṣiṣẹ́ takuntakun pẹ̀lú Barau Jibrin láti ri dájú pé Ààrẹ Tinubu rí sáà kejì lásìkò ìbò.
Ṣé Atiku Abubakar máa díje dupò ààrẹ lọ́dún 2027?
Ìgbésẹ̀ Abba Atiku Abubakar ti wá ń fa awuyewuye bí àwọn ṣe ń wòye pé kí ló dé tó fi ń gbé ìgbésẹ̀ láti tako bàbá rẹ̀ níbi ètò ìdìbò ọdún 2027.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Atiku Abubakar tó jẹ́ bàbá Abba Atiku Abubakar kò ì tíì kéde ìpinnu rẹ̀ láti dupò ààrẹ Nàìjíríà níbi ètò ìdìbò ọdún 2027, ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti du ipò náà sẹ́yìn, tó sì máa ń fi èròńgbà rẹ̀ hàn pé òun fẹ́ ṣe ààrẹ Nàìjíríà.
Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó máa ń ṣe àtakò ìjọba tó wà lóde, tó sì máa ń fẹ̀sùn kàn pé ìṣèjọba Ààrẹ Tinubu ń mú ìṣẹ́ àti òṣì bá àwọn ọmọ Nàìjíríà jú bí ó ṣe yẹ lọ.
Ní ọdún 2025 ni Atiku Abubakar fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress, ADC tí ọ̀pọ̀ sì ní ìgbàgbọ́ pé ó ṣe bẹ́ẹ̀ láti tún dupò ààrẹ ni.
Mi ò kí ń dá sí ìpinnu àwọn ọmọ mi lórí òṣèlú - Atiku Abubakar
Ẹ̀wẹ̀, Atiku Abubakar ti wá sọ̀rọ̀ lórí ìgbésẹ̀ ọmọ rẹ̀, tó sì ní ìgbésẹ̀ náà jẹ́ ìpinnu ọmọ òun tí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú òun.
Atiku Abubakar wòye pé ìgbésẹ̀ táwọn ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ bá gbé lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú jẹ́ ohun tó tọ̀nà lábẹ́ ètò òṣèlú ìṣèjọba àwaarawa.
Ó tẹmpẹlẹmọ pé òun kìí gbìyànjú láti yí ọkàn àwọn ọmọ òun tàbí àwọn èèyàn òun padà lórí ìgbésẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ gbé.
Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sójú òpó X rẹ̀ lọ́jọ́bọ̀ ní ìgbésẹ̀ náà kò mú ewu kankan lọ́wọ́ fún òun àti òṣèlú òun.
Bákan náà ló bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba tó wà lóde pé ohu tó jẹ òun lógún ni ṣíṣe ètò ìjọba rere fáwọn ọmọ Nàìjíríà.
"Ohun tó ń kọmílóminú ni ìṣèjọba ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí kò dára àti ọrọ̀ ajé Nàìjíríà tó ti dénu kọlẹ̀ tó sọ ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn wa sínú ìdààmú.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC sọ̀rọ̀
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Eko lásìkò tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìgbésẹ̀ ọmọ Atiku ní ìgbésẹ̀ náà ti ṣàfihàn pé Atiku Abubakar kìí ṣe ẹni tó ṣe é fi ọkàn tán lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà, Seye Oladejo fi léde sọ pé bí Abba Atiku Abubakar ṣe kọ̀ láti tẹ̀lé bàbá rẹ̀ lọ sí ẹgbẹ́ òṣèlú ADC túmọ̀ sí pé ẹgbẹ́ náà kò kájú òṣùwọ̀n láti ṣèjọba Nàìjíríà.
Ó ní kò sí ẹni tó yẹ láti fi ọkàn tán Atiku tó yẹ kó ju ọmọ rẹ̀ lọ àti pé ìgbésẹ̀ ọmọ náà ti ṣàfihàn pé Atiku Abubakar kò ní gbòǹgbò nípa òṣèlú.














