Ìjọba àpapọ àti ASUU tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn tuntun tí yóò dènà ìyanṣẹ́lódì

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ijọba apapọ Naijiria ati ẹgbẹ awọn olukọ Yunifasiti, Academic Staff Union of Universities (ASUU) ti tọwọ bọ iwe adehun tuntun ti yoo ṣatunṣe si idakureku eto ẹkọ, iyanṣẹlodi, airowo gba deede awọn olukọ pẹlu awọn iṣoro miran to n koju awọn ile ẹkọ giga lorilẹede yii.
Ọjọru ana ni wọn tọwọ bọwe adehun tuntun naa ni gbọngan TETFund, niluu Abuja.
Àwọn kókó inú àdéhùn náà
Nibi ipade adehun naa ti Minisita eto ẹkọ, Tunji Alausa atawọn alẹnulọrọ lẹka ẹkọ Naijiria peju si ni wọn ti fẹnu ko pe afikun yoo ba owo oṣu awọn olukọ naa pẹlu ida ogoji (40%) ki ori wọn le maa ya si iṣẹ.
Gẹgẹ bi Alausa ṣe wi, ilana owo oṣu tuntun yii yoo kan CONRAISS (Consolidated Research and Allied Institutions Salary Structure) bẹẹ ni yoo kan owo awọn nnkan elo ẹkọ naa.
Bakan naa lo ni ajẹmọnu owo kan naa wa fun awọn ọjọgbọn "Professorial cadre allowances".
Gẹgẹ bi Minisita eto ẹkọ ṣe wi:
"Fun igba akọkọ, ijọba apapọ ti fọwọ si ajẹmọnu tuntun fun awọn ọjọgbọn ti wọn n lo gbogbo akoko wọn fun iṣẹ fasiti (Full time professors and readers).
O fi kun un pe ajẹmọnu yii ko si fun awọn ọjọgbọn to ni nnkan mi-in ti wọn n fi akoko wọn ṣe (part time professors and readers.)
O ni eto naa wa fun mimọ riri ọpọ iṣẹ ti wọn n ṣe, bẹrẹ lati iṣakoso de kikọ awọn eeyan ati ṣiṣẹ iṣẹ iwadii.
Ọmọwe Alausa sọ pe adehun ti yoo mu ayipada gidi wa laarin ijọba apapọ ati ASUU ree.
O ni adehun naa waye ni ibamu pẹlu iduroṣinṣin Aarẹ Tinubu.
Minisita fi kun un pe igbesẹ ti yoo dẹkun akude fun saa igbẹkọ leyi, o si jẹ imuṣẹ ileri ọtun Aarẹ Tinubu.
'A nireti pe yoo ri bẹẹ'
Ninu ọrọ Aarẹ ASUU, Ọjọgbọn Chris Piwuna, o ni bo tilẹ jẹ pe kaluku naa lo mọ itan ijọba apapọ ati ASUU to wa nilẹ, awọn fẹẹ gbagbọ lọtẹ yii pe nnkan yoo yatọ bayii.
Aarẹ ASUU ni ireti oun ni pe ẹgbẹ awọn ko ni I nilo lati tun kede idunkooko iyanṣẹlodi fun ijọba apapọ mọ.
"A gbagbọ pe ijọba apapọ yoo tẹle adehun yii delẹdelẹ, ṣugbọn a ṣi n ṣiyemeji nitori ohun to ti wa nilẹ tẹlẹ.
"Igbagbọ wa ni pe Ọmọwe Alausa yoo yatọ ni tiẹ, ati pe ẹgbẹ wa ko ni I nilo lati kede iyanṣẹlodi ikilọ ki ẹ too mu adehun yii ṣẹ."
Bẹẹ ni Aarẹ ASUU wi.














